Àwọn aráàlú Babanla, ní Kwara ti ń fi ìlú sílẹ̀ lẹ́yìn ìkọlù agbébọn

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Awọn olugbe ilu Babanla, ni ijọba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ Kwara ni a gbọ pe wọn ti n fi ilu naa silẹ lọọ gbe ni awọn ilu miran bayii.
Eyi waye latari ikọlu ti awọn agbebọn ṣe si ilu ọhun, ti ọpọlọpọ ẹmi si ba isẹlẹ naa lọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii ni awọn agbebọn ti wọn ni wọn le ni igba (200), ya bo ilu Babanla.
O kere tan, iroyin sọ pe wọn pa eeyan marun-un, to fi mọ ọlọpaa kan, awọn ọmọ ikọ Miyetti Allah meji ati araalu meji.
Iwadii BBC Yoruba fi han pe awọn to kọlu ilu Babanla tun ya bo ọja, wọn si ji oriṣiiriṣii ounjẹ lapolapo lọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ikọ alaabo koju wọn, ti wọn si pa ninu awọn agbebọn naa, ko sẹni to le sọ pato iye awọn agbebọn to ku.
Eyi ri bẹẹ nitori bi ọta ibọn ṣe n ba wọn loju ija ni wọn n sare gbe oku ara wọn gun ọkada, ti wọn wa a lọ.
Ikọlu to ko awọn araalu Babanla laya soke naa ni wọn lo fa a ti ọpọ wọn fi ti sa kuro nibẹ bayii, ti wọn lọọ n gbe agbegbe miran.
Yatọ si ounjẹ ti wọn ko lọ rẹpẹtẹ, awọn olugbe Babanla sọ pe awọn agbebọn naa tun gbe alùpùpù tó lé ní ọgbọ́n sa lọ.
''Ìjayà ló mú wa sá kúrò nílùú''

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Obinrin opo kan, Medinat Agboola to jẹ olugbe Babanla ṣaaju ikọlu naa, ṣalaye fun BBC pe Ilorin loun wa bayii, lọdọ ọmọ oun toun sa lọ latari iṣẹlẹ naa.
Medinat ṣalaye pe awọn ọkunrin diẹ ṣi wa ni Babanla, ti wọn n fi ọkan Akin dile mu, ki awọn ajinigbe ma baa gba ilu mọ awọn lọwọ patapata.
Ọkan lara awọn ọkunrin ilu naa to ba BBC sọrọ, Muraina Agboola, sọ pe awọn obinrin nikan kọ lo n sa kuro ni Babanla.
O ni awọn ọkunrin gan-an n japa kuro niluu lati daabo bo ẹmi wọn.
"Loootọ ni pe Ilorin ni isẹlẹ naa ka mi mọ, nitori isẹ ti mo wa ṣe nigba naa, ṣugbọn mi o le pada sile latigba to ti waye, tori o lewu fun mi gidi gan-an.
"Ko too di pe awọn agbebọn yẹn wa gan-an ni mi o ti sun ile mi mọ, ile miran ninu ilu wa ni mo n sun. Idi ni pe bi wọn ṣe n ji wọn gbe ni awọn agbegbe to sun mọ wa ni ara ti n fu mi.
"Mo wa lara awọn to n gbogun ti awọn ajinigbe yii, mo maa n fi owo ati nnkan mi-in ti mo ni ṣatilẹyin fun awọn agbofinro, mo si mọ pe awọn ajinigbe yii mọ mi nipasẹ ipa ti mo n ko nilu.
"Atọkunrin, atobinrin, tọmọde-tagba lo n fi ilu silẹ bayii.
Àwọn sọ́jà ní wọn ń dá àwọn olùgbé ìlú Babanla tí wọ́n ń sá lọ padà, wọ́n ní kò séwu mọ́."
Arakunrin Muraina Agboola fi kun-un pe, awọn sọja ti ijọba ko wọlu lati maa daabo bo ẹmi ati dukia awọn eniyan ni wọn o jẹ ki awọn olugbe ti lọ tan.
O ni bi awọn eeyan ṣe n ko lọ, lawọn sọja n dawọn pada.
O ni ohun ti awọn soja naa n sọ ni pe ti awọn eeyan ba sa lọ tan, ta wa ni kawọn maa daabo bo.
O rọ ijọba ki wọn wa gba awọn lọwọ awọn ajinigbe, nipa gige igbo nla nla ni ilu Babanla lulẹ.
Ọmọ ìlú kò sá lọ, àwọn àlejò ló n fìlú sílẹ̀ - Kabiyesi Ìlú Babanla

Oríṣun àwòrán, Babanla Palace
Lodi si ọrọ awọn ọmọ ilu Babanla ti BBC ba sọrọ, Kabiyesi ilu naa, Ọba Aliyu Alabi Yusuf, sọ pe awọn to n filu naa silẹ ki i ṣe ọmọ bibi ilu Babanla, o ni awọn ajeji lo n sa lọ.
Ninu ọrọ ti Kabiyesi Yusuf ba BBC sọ lori aago lo ti ni oriṣiiriṣii ẹya lo wa ni ilu Babanla.
Ọba ni oun ko le sọ boya agbodegba fun awọn ajinigbe wa ninu wọn tabi ko si, ṣugbọn ohun to da oun loju ni pe ọmọ ilu kan ko le jẹ agbodegba.
Kabiyesi Babanla rọ gbogbo awọn to sa lọ lati pada sile, o ni nitori eto aabo ti wa.
O ni o ṣe diẹ ti ijinigbe ti bẹrẹ ni agbegbe Babanla, ati pe awọn agbebọn to wa yii pọ niye, wọn si ṣoro lati koju nitori ibọn ti wọn gbe lọwọ.
Ọba naa sọ pe gbogbo ile itaja ilu naa ni wọn fẹrẹ wọ tan, ti wọn ko ounjẹ loriṣiiriṣii lọ.
Kabiyesi Aliyu Alabi ṣalaye pe ọjọ naa jẹ ọjọ ọja, o ni gbogbo awọn olọja ti wọn ka owo mọ lọwọ ni wọn gba owo naa lọ lọwọ wọn.
Ọba ilu Babanla rọ ijọba lati fi awọn igbo nla nla to wa ni ilu naa kọ agọ awọn ṣọja, ileesẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Àwọn agbódegbà wà nínú ìlú - Amúgbálẹ́gbẹ̀ Kabiyesi
Ni tirẹ, Ọgbeni Suleiman Abdul Azeez to jẹ amugbalẹgbẹẹ fun Kabiyesi ilu Babanla, sọ pe awọn to n ṣe agbodegba fun awọn agbebọn naa wa laaarin ilu awọn.
O ni ẹya to wa ni Babanla ki i se Yoruba nìkan, Hausa, Ibo, Tiv Fulani, Kenberi ati awọn miran lo ni wọn wa nibẹ.
"Ko si si bi awọn agbebọn wọnyi ṣe le sisẹ lai ni agbodegba, ọkan lara awọn afurasi naa fidiẹ mulẹ pe agbodegba ni oun.
"Awọn agbebọn yii le ni igba pẹlu eeyan meji meji lori ọkada kan"
''Yato si ounjẹ bi irẹsi, ẹwa, epo pupa ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn ji ko lọ, nise ni wọn tun ko awọn ọkada awọn to n duna dura to le ni ọgbọn lọ."
O ni awọn ilu bii Patigi, Edu tawọn ti n ra ounjẹ tẹlẹ ni awọn o ri ounjẹ ra mọ bayii.
Ìgbésẹ̀ ìjọba Kwara àti ọlọ̀pàá

Oríṣun àwòrán, Kwara Government House
Lati koju iṣoro yii, Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazak, ti sepade pẹlu awọn ṣọja, ọlọpaa ati awọn ẹsọ alaabo mi-in.
Gẹgẹ bi oludamọran Gomina naa ni ẹka iroyin, Fafoluyi Olayinka, ṣe wi, ilu Omu-Aran ni ipade naa ti waye, o si da lori bi eto aabo yoo ṣe duro daadaa nipinlẹ Kwara.
Saaju ni ajọ olopaa ipinlẹ Kwara ti sabẹwo si ilu Babanla lati mọ bi isẹlẹ naa se waye.
Atẹjade ti Alukoro olopaa Kwara, SP Adetoun Ejire Adeyemi, fi sita, ṣalaye pe Komisanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Adekimi Ojo, lo dari awọn ikọ oloogun lọ sibẹ lati ṣeto bi eto aabo agbegbe naa yoo se nipọn si i.













