$3.7 million kìṣì ni a ti ná lórí ìgbéyàwó alárédè- Davido

Davido ati Chioma

Oríṣun àwòrán, Davido Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Olowo ṣe ohun gbogbo tan.

Gbajugbaja olorin taka-sufee, David Adeleke tawọn eeyan mọ si Davido, ti sọ pe owo to din diẹ ni miliọnu mẹrin dọla, iyẹn $3.7 million ni oun naa kiṣi fun imurasilẹ igbeyawo alarede laaarin oun ati Chioma Roland, ni Miami, Florida lorilẹede America.

Eyi jẹ owo to le diẹ ni biliọnu marun abọ NAira (N5,667,922,552.00) lonii.

Ninu fidio kan ti Teni, olorin taka-sufee bii Davido fi sori ẹka Instagram ni Davido ti kede eyi.

" A ti na $3.7 kiṣi. Fun idi eyi, o yẹ kẹ ẹ mọ ohun ti a n ṣe. O maa lagbara gan-an"

Igbeyawo naa to waye lopin ọsẹ yii ni inawo rẹ ṣi n tẹsiwaju ju iye ti Davido kede yii lọ.

Davido ati Chioma

Oríṣun àwòrán, Davido Instagram

Ibeere ọsẹ to kọja ni tọkọ-taya ti de si Miami, ninu ọkọ ofurufu aladaani wọn ti wọn ṣe lọṣọọ, ti wọn si kọ akọle "MRS",, iyẹn Abilẹkọ si.

Fidio oriṣiiriṣii to ti n jade lati ibi eto inawo naa n fi ami ọla han, pẹlu bi tọkọ-tiyawo naa ṣe n fi imura olowo nla oriṣiiriṣii han.

Igbeyawo Miammi yii ni ẹlẹkẹẹta ti tọkọ-taya Adeleke yoo ṣe, ṣaaju ni wọn ti ṣe ti kootu loṣu Kẹta ọdun 2023.

Oṣu Kẹfa ọdun 2024 ni wọn ṣe igbeyawo nilana ibilẹ niluu Eko, nibi ti awọn gbajugbaja kaakiri orilẹede yii peju si.

Lara awọn olorin to peju si ti eyi ti wọn pe ni Chivido 2025 yii ni:Zlatan Ibile, Teniola Apata, Adekunle Gold, Tunde Ednut, Poco Lee ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa ni Gomina Ademola Adeleke to da bii baba fun Davido naa wa nibẹ, gẹgẹ bi Akọwe iroyin rẹ, Olawale Rasheed, ṣe sọ.

Ìrìnàjò ìfẹ Davido àti Chioma

Chioma ati Davido

Oríṣun àwòrán, Davido Instagram

Davido ti awọn eeyan tun mọ si Ọmọ Baba Olowo, (OBO) kọkọ pade Chioma to pada fẹ yii ni Yunifasiti Babcock, nibi ti ọmọbinrin ẹya Igbo naa ti jẹ akẹkọọ.

Bo tilẹ jẹ pe o ti ju ọdun mẹwaa lọ ti wọn ti bẹrẹ ajọṣepọ, ọdun 2018 ni ifẹ wọn han saye.

Awo orin kan ti Davido pe ni 'Assurance' lo gbe jade nigba naa lati fi da Chioma loju, pe oun yoo fẹ ẹ bii iyawo.

Lẹyin naa lo tun ṣe awo mi-in to fi ni oun le san miliọnu lorii rẹ gẹgẹ bi owo ori.

Nigba to si di 2023, wọn ṣe igbeyawo labẹ ofin.

Davido ati Chioma

Oríṣun àwòrán, Davido Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọmọkunrin kan ti wọn sọ ni Ifeanyi Adeleke ni Chioma kọkọ bi fun Davido, ṣugbọn iku pa ọmọ naa nigba to ri sinu omi ile wọn l'Ekoo ni 2022.

Lẹyin iku Ifeanyi ni Davido ati Chioma bi ibeji ni America, iyẹn ni 2023.

Bo tilẹ jẹ pe Davido ni ọmọbinrin kan, Imade Adeleke, ti obinrin to kọkọ fẹ, Sophia Momodu, bi fun un, sibẹ, ko fi bo rara pe Chioma ni aayo oun.

Ọpọ igba lo maa n fi awẹlẹwa rẹ naa yangan lawujọ.

Alásè ni awọn eeyan mọ Chioma si, wọn a maa pe e ni Chef Chioma.

Bo si tilẹ jẹ pe igbeyawo wọn ti koju awọn awuyewuye pẹlu awọn obinrin mi-in ri, ohun to daju ni pe Chioma ki i gbe e soju.

Eyi jẹ ki ọpọ eeyan fẹran rẹ lori ayelujara, wọn a si maa sọ pe ara rẹ balẹ pupọ.

Ọmọkunrin kan ti wọn sọ ni Ifeanyi Adeleke ni Chioma kọkọ bi fun Davido, ṣugbọn iku pa ọmọ naa nigba to ri sinu omi ile wọn l'Ekoo ni 2022.

Lẹyin iku Ifeanyi ni Davido ati Chioma bi ibeji ni America, iyẹn ni 2023.

Bo tilẹ jẹ pe Davido ni ọmọbinrin kan, Imade Adeleke, ti obinrin to kọkọ fẹ, Sophia Momodu, bi fun un, sibẹ, ko fi bo rara pe Chioma ni aayo oun.

Ọpọ igba lo maa n fi awẹlẹwa rẹ naa yangan lawujọ.