Wo àwọn nnkan tí o le ṣe bí ọkọ rẹ bá fẹ́ ẹ́ fẹ́ ìyàwó lé ọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Aisha Babangida
- Reporting from, BBC News, Abuja
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Ko si alakara to n fẹ ki ẹnikeji din laye yii, Oriṣa jẹ n pe meji obinrin ko si le denu laye, wọn n rọju ni bi ọkọ ba gbe iṣe rẹ de, to fẹ iyawo tuntun le eyi to wa nile tẹlẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ẹsin Islam ni tiẹ fi ara mọ ki ọkunrin fẹ iyawo de ori mẹrin to ba wu u, to si le ṣe deede laaarin wọn, apa Ariwa Naijiria ni fifẹ iyawo to ju ẹyọkan lọ pọ si ju lorilẹede yii.
Eyi ri bẹẹ nitori ẹsin Islam ni ọpọ eeyan nilẹ Hausa n ṣe.
Igba mi-in wa ti ọkọ atiyawo yoo jọ sọ asọye lori iyawo tuntun ti ọkọ n gbero lati fẹ, wọn yoo jọ pinnu rẹ bi yoo ṣe ri, iyaale yoo loun ti gba, ki ọkọ too mu oloju arede tuntun naa wale.
Ṣugbọn ọpọ igba lo jẹ pe ogun abẹle to gbona girigiri lo maa n ti ibi ibagbepọ iyawo pupọ wa, ile olorogun maa n pada di ogun mọ wọn lọwọ ni.
Fifẹ iyawo le iyale wa lara awọn ohun ti a gbọ pe o n fa iku tọkọ-taya lapa Ariwa, ẹnikan yoo pa ikeji nigba ti ọrọ ko ba wọ̀ mọ.
O le jẹ laaarin iyawo to ṣẹṣẹ de pẹlu iyale ni wahala yoo ti bẹrẹ, tabi laaarin ọkọ wọn gan-an pẹlu awọn obinrin to fẹ.
BBC ba awọn iyawo ile kan sọrọ ni Ariwa Naijiria, nipa iriri wọn lori ọrọ yii
'Ìdààmú ọkan bá mi nígbà tí ọkọ mi fẹ́ẹ́ fẹ́yàwó lé mi'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkan lara awọn obinrin to ti foju wina ọrọ iyawo mi-in yii ni Hajia Fatima.
O ṣalaye pe ọkan oun poruru, ibanujẹ ati idaamu ọkan si ba oun lalejo nigba ti ọkọ oun fẹẹ mu iyawo keji wale.
"Nigba to kọkọ sọ fun mi pe oun fẹẹ fẹyawo le mi, owu jijẹ gbe mi wọ, ọkan mi daru.
"Mo jẹ ko mọ pe mi o fẹ ko fẹyawo le mi, mo tiẹ tun bẹrẹ si i ba a sọrọ fun ọpọlọpọ ọjọ lorii rẹ boya yoo yi ipinnu naa pada, ṣugbọn ko gba si mi lẹnu.
"Nigba ti mo ri i pe ko ṣetan lati da mi lohun, mo gba kamu, mo pada sile mi, mo si sọ fun un pe ko jẹ ka jọ maa gbe ile kan naa, o si gba.
"Ọdun keje ree to ti fẹ iyawo naa, o tun ti n mura lati fẹ ẹlẹẹkẹta bayii."
Hajia Fatima to ti di iyale agba lo ṣalaye bẹẹ.
'Ọkọ tèmi kò tiẹ̀ sọ fún mi pé òun fẹ́ẹ́ fẹ́yàwó lé mi, ìta ni mo ti gbọ́ ọ'
Obinrin kan lara awọn ti BBC ba sọrọ sọ pe, ṣebi ọkọ awọn kan tiẹ pe wọn jokoo sọ fun wọn pe oun fẹẹ fẹyawo le wọn, ọkọ toun ko tiẹ ba oun sọ nnkan kan lori igbesẹ naa to fi ṣe e.
"Mo kan gbọ ọrọ yẹn lati ọdọ ọrẹ mi kan ni, o sọ fun mi pe ọkọ mi ti fẹẹ gbeyawo tuntun.
'Ọrẹ mi yẹn gbọ ọ lati ọdọ ọkọ tiẹ, o ni ọkọ naa si gbọ ọ lakoko ipade kan ni."
Obinrin yii sọ pe o dun oun o, owu jijẹ si gba ọkan oun gẹgẹ bo ṣe yẹ.
O ni ṣugbọn latigba to ti fẹ iyawo naa, oun ko huwa aburu kan si i ri, tabi si iyawo rẹ to fẹ.
"Mo fi Ọlọun bura, nigba ti mo gbọ ọrọ yẹn lati ita, ko dun mọ mi rara, niṣe lo da bii pe wọn yẹyẹ mi, wọn si fi oju mi gbole, nitori ọkọ mi ko pe mi jokoo ba mi sọ ọ.
" Mo mọ pe mo maa n jowu, ṣugbọn iyẹn ko ni ki n huwa aburu kankan si wọn, oun naa si mọ bẹẹ."
Iyawo to di iyale yii sọ pe ẹsin Islam to fi aaye gba iyawo pupọ lo mu oun gba kamu, ti ko si jẹ ki oun binu sọkọ oun lori ohun to ṣe.
'Bí mo ṣe sọ fún ìyàwó mi pé mo fẹ́ẹ́ fẹ́yàwó kejì'
Lati yanna-na ọrọ yii delẹ, BBC ba ọkunrin kan to fẹ iyawo keji sọrọ.
Bo si tilẹ jẹ pe o ni ka fi orukọ bo oun laṣiiri, eyi ni alaye to ṣe fun wa nipa bi iyale ṣe gba iroyin iyawo keji nigba to sọ fun un.
"Iyawo mi n ṣiṣẹ, ọpọ igba lo si maa n wa nibi iṣẹ ju bo ṣe maa n wa nile lọ, ile si ni emi ti n ṣiṣẹ ni temi, eyi n jẹ ki n lo akoko to pọ nile ju u lọ.
"Ọdun karun-un ree ti a ti ṣegbeyawo, ṣugbọn a o ti i bimọ kankan.
"Nigba ti mo sọ fun un pe mo ti ri ẹlomi-in ti mo fẹẹ fẹ ṣikeji, ko ba mi ja.
Koda, o tun gba mi niyanju pe ki n fẹ ẹ ni, o si tun yin mi fun bi oun ko ṣe ki n duro nile lọpọ igba, ti mo si n gba iru ẹ mọra, oun naa si mọ pe awọn kan n da mi laamu pe ki n fẹ iyawo mii.
"Lati igba ti mo ti sọ fun un, niṣe lo ni o daa bẹẹ. K'Ọlọun ba mi bu kun un, ko si ba mi san an lẹsan ire pẹlu iwa rere to ni."
Kí ló yẹ kí obìnrin ṣe bí ọkọ bá fẹ́ẹ́ fẹ́ ìyàwó tuntun lé e?
Bi eto ṣe wa fun ohun gbogbo laye naa lo wa fun ọrọ olobinrin meji tabi ju bẹẹ lọ ni fifẹ, awọn kan si wa to jẹ iṣẹ tiwọn ni lati gba awọn to ba ba ara wọn lagbo olorogun nimọran nipa ohun ti wọn le ṣe.
Ọkan lara awọn olugbani-nimọran bẹẹ ni Ọmọwe Hajia Zainab Abdullahi, onimọ nipa igbeyawo ati idile.
Iya naa ka awọn nnkan wọnyi bi ohun ti iyawo le ṣe bi ọkọ ba setan lati fẹ ẹlomi-in le e.
Gẹgẹ bii obinrin, o yẹ ki o maa ro o pe ohunkohun lo le ṣẹlẹ, ọkunrin le ji lọjọ kan ko loun fẹẹ fẹyawo keji tabi ju bẹẹ lọ.
- To ba ṣẹlẹ bẹẹ, farabalẹ: Ma jẹ ki ibinu tabi owu jijẹ dari ọkan rẹ.
- Fi ọgbọn ba ọkọ rẹ sọrọ.
- Beere imọran lọwọ awọn onimọ lori ọrọ yii, fun alaafia ọkan rẹ.
- Ma a ṣe adua ko o si nigbagbọ ninu Ọlọrun.
- Tunra ṣe, mojuto ilera rẹ, ero to n wa si ọ lọkan ati awọn ọmọ ti o bi.
- Bi o ba jẹ obinrin Musulumi, o yẹ ki o mọ pe ẹsin fi aaye gba ọkọ rẹ lati fẹ iyawo le ọ.
Ọmọwe Zainab ṣalaye lakootan, pe igbaradi pe o le ṣẹlẹ, ọkọ le fẹyawo nigba to ba wu u, suuru, adua ati ibaraeni sọ asọye, wa lara ohun to le mu ọkan obinrin papọ sọna kan to ba ṣẹlẹ.
O ni eyi yoo jẹ ki wọn mojuto aye wọn bii pe awọn nikan naa ni wọn ṣi jẹ iyawo lọọdẹ ọkọ wọn.
Ko ju bẹẹ lọ.














