'Ọdún kejìlá rèé tí mo ti ṣe ìgbéyàwó láì rí ọmọ bí, àwọn dókítà kò sì mọ kókó nnkan tó fàá'
Ayọ tọkọtaya ati ẹbi wọn ni pe, lẹyin igbeyawo, ki iyawo fi inu ṣoyun, ko si fi ẹyin gbọmọ pọn.
Ṣugbọn nigba ti eyi ko ba ri bẹẹ, o ma n jẹ nnkan ibanujẹ fun iru tọkọtaya bẹẹ.
Ọpọ obinrin lo ti ẹ ma n koju idẹyẹsi, eebu, ọrọ ẹyin, ati awọn iwa ti ko tọ miran lati ọdọ awọn ẹbi, ọrẹ, koda, ọkọ rẹ nigba mii.
Ọdun kejila re e ti Arabinrin Aminat Sheriff-Owolabi ati ọkọ rẹ ti ṣe igbeyawo, ti wọn si ni ireti lati di obi lọjọ kan. Amọ eyi ko tii ri bẹẹ fun wọn.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC News Yoruba, Arabinrin Sheriff-Owolabi sọ awọn nnkan ti oju rẹ ti ri nitori airọmọbi.

Oríṣun àwòrán, MomentswithAminat/Instagram
O ni oun ti ni eeyan kan to sunmọ oun to ṣe igbeyawo lẹyin bi ọdun meji ti oun ṣe, amọ ẹni naa kọ lati fi iwe pe e sibi ayẹyẹ igbeyawo naa nitori "ko ma ba ko airọmọbi ran-an".
Arabinrin Sheriff-Owolabi ṣalaye pe gbogbo ayẹwo ti tọkọtaya ma n ṣe ṣaaju igbeyawo ni awọn ṣe.
"Ọdun kejila re e ti a ti ṣe igbeyawo, a ti ṣe ayẹwo, amọ eyi to buru ju nibẹ ni pe, wọn ko ri koko nnkan to n fa airọmọbi fun wa."
O ni koda, awọn ko ri oyun ni nigba ti awọn tun bọ si ilu oyinbo.
Mo ma n sunkun nigba miran
O ni airọmọbi yii ti mu ki oun da awọn irinajo kan duro ninu igbeaye oun ati ọkọ.
"Lẹyin ti mo pari ipele eto ẹkọ giga keji, mo ni anfaani ẹkọ ọfẹ, amọ nitori pe mi o fẹ fi ọkọ oun silẹ nitori mi o mọ asiko ti ọmọ le de, mo kọ lati lọ."
"Eyi wa lara nnkan ti ọkọ rẹ naa ṣe fi iṣẹ silẹ ni banki to ti n ṣiṣẹ, ki awọn mejeeji le jọ wa papọ niluu oyinbo.
Arabinrin Sheriff-Owolabi sọ pe oun pinnu lati ma a fi igbeaye oun tu awọn obinrin mii to le ma a koju airọmọbi bi tiẹ ninu.
Eyi lo mu ko ṣi ojuopo ayelujara instagram kan, nibi to ti ma n fi awọn ọrọ itunu ati iriri rẹ sita.



