Ìdí tí òògùn ìfètòsọ́mọbíbí fi má ń ní ìpalára fún àwọn obìnrin

Oríṣun àwòrán, Abere ifeto somo bibi/ GETTY IMAGES
Awọn oogun idena ọmọ bibi ti jẹ ohun pataki laarin tọkọ taya, paapaa laarin awọn obinrin ti wọn fẹẹ fi aaye silẹ fun ọmọ bibi ati lati ṣeto igbe aye mọlẹbi wọn.
Oriṣi oogun ifetosọmọbibi lo wa, to si bẹrẹ lati ori eyi ti wọn n fi si oju ara, eyi ti wọn n gba bi abẹrẹ ati rọba idaabobo, to fi mọ awọn eyi ti wọn n fi si ara obinrin, ati awọn miran.
Ọpọ awọn obinrin ni wọn maa n ri anfaani ninu lilo oogun to n dena oyun ati ọmọ bibi, ṣugbọn ti awọn miran maa n sọ pe awọn maa n koju ọpọlọpọ iṣoro lẹyin ti wọn ba lo awọn oogun naa tan.
Lara awọn iṣoro tabi adojukọ ti ọpọ awọn obinrin maa n koju lẹyin ti wọn ba lo awọn ogun to n dena oyun yii ni, bi wahala nnkan oṣu ati ki wọn maa sanra si i.
Awọn miran tilẹ maa n ni irora ninu ọyan, ori fifọ, aini ifẹ si ibalopọ, ki omi maa da loju ara wọn, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Àwọn ìṣòro ‘fertility drugs’
Iyawo ile kan, to tun jẹ ọlọmọ mẹta ati ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, Hajiya Maryam ṣalaye fun BBC pe o ti to ọdun mẹjọ bayii toun ti n lo ogun to n dena ọmọ bibi, ati pe ajọsọ laarin oun pẹlu ọkọ oun ni lati maa lo o.
“Ọdun marundinlọgbọn ni mo wa nigba ti mo wọ ile ọkọ, ki n to ṣegbeyawo, mi o sanra rara, igba ti mo de ile ọkọ mi lẹyin oṣu mẹrin ni mo to loyun.
“Lẹyin oṣu mẹjọ ti mo bimọ ni mo tun loyun miran, nigba ti a ko mura rẹ silẹ rara, mo si mọ pe inu ọkọ mi ko dun sii.
“Lẹyin naa ni ọkọ mi sọ pe ka lọ si ọsibitu lati lọ ri dokita, ki wọn le gbe wa sori eto ifeto sọmọ bibi.”
Ninu gbogbo oriṣiriṣi eto ti dokita ṣalaye fun tọkọ-taya yii, Maryam gba lati maa gba abẹrẹ oloṣu mẹta-mẹta.
Abẹrẹ akọkọ ti wọn kọkọ fun Maryam jẹ ko maa bi lera-lera, to si tun n koju iṣoro inu rirun, bo tilẹ jẹ pe lẹyin ọsẹ kan, lo sọ pe ara oun ṣẹṣẹ balẹ, to si pada bọ sipo.
“Lẹyin oṣu mẹta, mo pada lọ si ọsibitu lati gba abẹrẹ miran, abẹrẹ naa tun jẹ ki n maa bi, ki inu si tun maa run mi.”
Ipenija miran ti Maryam tun koju lẹyin to gba abẹrẹ ọhun, ni pe kii ri nnkan oṣu oun rẹ lasiko to ba yẹ.
“Ẹẹkan laarin oṣu mẹta ni mo maa n ri nnkan oṣu mi. Nigba ti mo ṣalaye fun dokita, o sọ pe iyẹn kii ṣe iṣoro rara. Mi o mọ pe o maa di bẹẹ rara.
“Lẹyin bi ọdun meji ataabọ ti mo ti bẹrẹ sii gba abẹrẹ to n dena ọmọ bibi yii, mo bẹrẹ sii ṣakiyesi pe mo n sanra sii, o si n ṣakoba fun mi.
“Mo ṣalaye fun ọkọ mi pe abẹrẹ idena oyun ti mo n gba ti n jẹ ki n maa sanra, ṣugbọn niṣe lo sọ fun mi pe rara, wi pe ounjẹ ti mo n jẹ ni.”
O ni ipo ti oun ba ara oun ti wa n jẹ ki oju maa ti oun, ati pe niṣe lo tun n da wahala silẹ laarin oun ati ọkọ oun.
O ni oun tun ti wa n ri bi ẹni pe ọkọ oun ko fẹẹ sunmọ oun, ko si fẹ ki wọn jọ maa wa papọ.
“Ọkọ mi kii ba mi sọrọ, ṣugbọn lẹẹkan, o sọ fun mi pe mo ti padanu itara ti mo ni, bi mo si ṣe maa dunnu si nnkan ti dinku.
“Gbogbo nnkan lo ti yi pada, ko dabi igba to maa n fẹ wa pẹlu mi tẹlẹ mọ.”
O ni lẹyin ọdun toun ti n gba abẹrẹ naa, o loun loyun miran, toun si fi oyun naa bi ibeji.
Maryam tẹsiwaju pe inu oun ko dun si oogun idena oyun toun n lo, nitori pe niṣe lo n mu ki oju ti oun lati jade, paapaa pẹlu ọkọ rẹ, nitori pe ko si ni ipo to wa tẹlẹ mọ.
Bakan naa, Faiza, ẹni ọdun mejidinlọgbọn sọ fun BBC pe lati igba ti oun ti n lo oogun ifeto sọmọ bibi yii, oun kii ri nnkan oṣu oun daadaa bii ti tẹlẹ mọ.
O ni ẹẹkan laarin oṣu mẹfa ni oun maa n ri nnkan oṣu oun.
“Nigba ti mo rii pe awọn iṣoro ti n dojukọ ti n pọ, mo pada lọ si ọsibitu lati sọ fun dọkita pe mi o fẹ eto ti wọn ṣe fun mi.
“Lakọkọ, mi o ni imọlara kankan, mi o bi, mi o ja wa silẹ, ṣugbọn lẹyin bi oṣu meloo kan, mo bẹrẹ sii ni ifẹ fun nnkan.
“Mo ṣakiyesi pe igbe aye mi n yi pada daadaa, maa kan maa rii pe inu mi kii dun, mi o fẹ maa sunmọ ibi ti ọkọ mi ba wa, koda, to ba wa ba mi, maa kan sun nilẹ lati tẹ ẹ lọrun lasan ni, eyi ti kii tẹ oun funra rẹ lọrun.
“Loṣu kan, ifẹ lati ni ibalopọ maa kere, to ba tun ya, yoo tun lọ soke.”
Faiza sọ pe ipo naa ko tẹ oun lọrun rara, ṣugbọn to ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ohun gbogbo lo ye ọkọ oun.
Ọpọ awọn obinrin ni wọn n koju oriṣiriṣi iṣoro nipa lilo oogun tabi gba abẹrẹ ifetosọmọbibi, ati pe nigba miran, awọn miran kii koju iṣoro kankan, tabi ki iṣoro ti wọn n koju ma to nnkan.
Kí ni dokita sọ?

Oríṣun àwòrán, Oogun ifeto somo bibi/GETTY IMAGES
Dokita Kabir Dara, to jẹ dokita agba nipa eto ilera awọn obinrin, ti awọn oloyinbo n pe ni Gynecologist ni ile iwosan Dara Specialist Hospital, ipinlẹ Katsina sọ fun BBC pe iṣoro wa ninu awọn oogun ifeto sọmọ bibi, ṣugbọn lara awọn nnkan ti awọn eeyan wọnyi sọ ko ni nnkan ṣe pẹlu awọn ogun naa.
O ni kẹmika ni pupọ awọn oogun to n dena oyun, eyi to ni pupọ awọn obinrin to ba lo o yoo ri ayipada ninu ara wọn.
O ni, o tun nii ṣe pẹlu iru obinrin to ba lo awọn oogun wọnyi.
Dokita Dara ṣalaye pe nitori naa ni awọn eleto ilera fi maa n gba awọn eniyan ni imọran lati kọkọ wa ri awọn akọṣẹmọṣẹ, ki wọn le mọ eyi ti yoo ba wọn lara mu lati lo.
“Oriṣiriṣi ọna ni awọn oogun yii pin si. Awọn kan to jẹ pe bi obinrin ba ṣe, o le paarọ rẹ, o si le bimọ.
"Awọn miran si wa to jẹ pe titi lai ni, to jẹ pe bi obinrin ba ṣe e, ko tun le bimọ mọ.
“Awọn oogun to n dena oyun ti wọn n lo yii dabi oogun oni horo ni, o si ni awọn eyi to jẹ pe inu ile ọmọ lo maa wa.
Awọn miran si wa to jẹ pe abẹ ara lo maa wa, ati pe gbogbo wọn lo ni ọjọ ati oṣu ti wọn le lo, bẹẹ lo tun nii ṣe pẹlu ọjọ ori
Awọn oogun wọnyi lo ni oriṣiriṣi awọ, awọn kan wa ti obinrin le gba lasiko to ba n fun ọmọ lọyan lọwọ.
Awọn eyi si dara fun awọn obinrin nitori pe o ni awọn eroja ninu to ba ara obinrin mu.
“Awọn eyi maa n dena ẹyin to n di ọmọ lati dide, bi awọn ẹyin wọnyi ko ba si gbera, ko si ọna ti obinrin le gba lati fi loyun. O dara lara, ojoojumọ si ni wọn maa n lo.”
Ṣugbọn dokita yii sọ pe iṣoro to wa ninu eyi ni pe o le ni ipalara bii ori fifọ, ko maa rẹ eeyan, tabi eeyan maa tobi tabi tiirin.

Oríṣun àwòrán, Abere to n dena oyun/THINKSTOCK
Dokita yii sọ pe ayipada to n waye ninu nnkan oṣu le jẹ eyi to waye lati ara awọn abẹrẹ tabi eyi ti wọn n fi si abẹ ara.
O ni eto gbigba abẹrẹ tabi lilo eyi ti wọn n fi si oju ara lẹ dena ki obinrin pada loyun, ati pe lati dena ẹyin ti yoo doyun ni.
Bẹẹ lo sọ pe o maa n gba asiko, ati pe ilana ti awọn eyi maa n tẹle maa n jẹ ki oju ara jona, to ba si ti jona, o ṣee ṣe ki obinrin ma ri nnkan oṣu rẹ fun ọpọ oṣu.
“Bi obinrin ko ṣe nnkan oṣu fun ọpọ oṣu, o maa ṣakiyesi pe to ba pada wa, niṣe lo maa sare wa gbuurugbu.
“O maa n gba asiko ko to ṣiṣẹ. O nii ṣe pẹlu iru ẹjẹ to wa lara eeyan ko to di pe o bẹrẹ sii ṣiṣẹ.
“Ati pe eyi ti wọn n fi sinu ile ọmọ, kii dena ẹyin to n dọmọ lati wa. Nigba ti awọn ẹyin yẹn ba wa, o maa nilo lati kọja, eyi ni yoo si dena ki nnkan oṣu lọ bo ṣe yẹ, to si le fa ki inu maa run obinrin.
Nipa wahala to n ṣẹlẹ laarin ọkọ ati iyawo ẹ, dokita naa sọ pe kii ṣe oogun yii lo n fa a, o ni o kan maa n jẹ ki ifẹ si ibalopọ dinku ni.
Dokita Kabir gba awọn eeyan niyanju pe ọrọ tọkọ-taya gbọdọ ye ara wọn daadaa ko to di pe wọn pinnu lati lo oogun tabi gba abẹrẹ to n dena oyun.
“Nigba miran, o le jẹ ọkunrin lo maa kan an nipa fun obinrin lati lọ lo oogun yii, ko si jẹ pe ko wu obinrin inaa lati ṣe e, nibẹ yẹn, ẹ maa rii pe ko si ifẹ laarin wọn.
“Niwọn igba to ba wu lati loyun, ti ọkọ ko si fẹ, ti wọn ko si sọ asọyepọ lati wa ọna abayọ, iṣoro le waye, ko si ma gba ifẹ laaye ninu ẹbi wọn.”















