'Lẹ́yìn tí mo bímọ tán ni mo ní ààrùn vitiligo'

Aworan WINIFRED AGHANWA

Oríṣun àwòrán, WINIFRED AGHANWA

Lẹyin ti Arabinrin Winifred Aghanwa bi ọmọ rẹ keji tan lọdun 2021, lo bẹrẹ si ni ṣe akiyesi pe iyatọ n ba awọ ara rẹ eleyii to ro pe ifo ni.

Bayii ni Aghanwa bẹrẹ si ni lo oogun ifo tori o ro pe iyatọ to maa n de ba awọn obinrin to ba ṣẹṣẹ bimọ lo n ṣẹlẹ si oun.

Ko tiẹ lero rara pe aarun vitiligo ni.

Ọmọkunrin meji ni Winifred bi, akọkọ jẹ ọmọ ọdun mẹfa nigba ti aburo rẹ jẹ ọmọ ọdun meji.

Winifred ni iyatọ to ba awọ ara oun jẹ iyalẹnu, eyi to mu ki oun lọ ri dokita onimọ nipa awọ ara ẹni to sọ fun oun pe vitiligo ni oun ni.

Dokita fun un ni itọju to le mu ki aarun naa lọ, amọ ko lọ.

Winifred sọ fun BBC pe oun ko ni ohun kankan to fara jọ aarun vitiligo ki oun to bi ọmọ keji ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2021.

Aworan Winifred Aghanwa

''Bayii kọ ni mo ṣe ro pe aye mi yoo ri''

Bi Winifred ṣe n sọ nipa irinajo rẹ lori bi o ṣe ni aarun vitiligo lẹyin to bimọ tan pẹlu omi loju rẹ, ni o sọ pe bi oun ṣe pinnu lati gbe igbe aye oun kọ ni o ṣe ri lẹyin ayọ ọmọ tuntun ti oun bi.

''Inu mi bajẹ tori mi o lero pe awọ ara mi tiẹ le ri bayii.

Bawo ni mo ṣe maa bimọ tan ti awọ ara mi yoo wa ri bayii?

Mo ti loogun, amọ ko ṣiṣẹ, o maa n dabi ẹni pe o maa lọ nigba mii.

Ki a to wi ki a to fọ, o tun ti bẹrẹ,'' Winifred ṣalaye.

Winifred ni vitiligo ti mu iyipada ba igbe aye oun to fi mọ iru aṣọ ti oun n wọ bayii.

O ni oun ko le wọ aṣọ alapa penpe mọ.

Bakan naa ni o sọ pe oorun ko gbọdọ pa oun ju mọ, koda oun ma n nilo lati wọ gilaasi oju.

Winifred sọ pe ''ko rọrun fun mi rara, mi o le duro si inu oorun fun igba pipẹ.''

O ni ẹbi ati awọn ọrẹ oun n gbaraku ti oun bo tilẹ jẹ pe oun ṣadeedee larun vitiligo.

Winifred funra rẹ wa rọ awọn iya ọmọ ikoko ti wọn ba ni iru arun vitiligo yii lati tọju ara wọn.

Aworan Winifred Aghanwa

Iru arun wo ni vitiligo?

Aarun vitiligo gẹgẹ bi ajọ to n ri si eto ilera lorilẹede UK ṣe ṣe apejuwe rẹ jẹ aarun to ti maa n pẹ lara ti o si maa n pa awọ ara da si funfun.

Ajọ naa ni aisi eroja ara kan to n jẹ melanin lo maa n fa arun vitiligo.

Ko si ibi ti vitiligo ko ti le jẹyọ ninu ara, amọ, o maa n saba jẹyọ ni oju, ọrun ati ọwọ eeyan.

Amọ, aarun vitiligo kii ṣe ohun to maa n ran lati ara ẹnikan si ara ẹlomiran.

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa aarun naa sọ pe, vitiligo le jẹ ki ọkan ẹni to ba mu poruuru, o si tun le jẹ ki eeyan naa maa ba inu jẹ. Koda,e o le jẹ ki o maa gbero ati pa ara rẹ.

Kínni awọn akọṣẹmọṣẹ sọ nipa aarun vitiligo ati ipo iloyun?

Ọpọ awọn dokita onimọ nipa ilera awọn obinrin ti wọn ba BBC sọrọ lo sọ pe kii ṣe oyun nikan lo n fa aarun vitiligo.

Oluwarotimi Ireti sọ pe vitiligo maa n gbogun ti awọn sọja to maa n gbogun ti aarun ninu ara.

Amọ, o ni kii ṣe idi lati sọ pe oyun lo maa n fa a.

O ni vitiligo yatọ si awọn awọn asarun mii ti oyun nini le ṣe okunfa rẹ.

Osas Edokpolor naa kin ọrọ Ireti lẹyin nigba to sọ pe ko wọ pọ ki awọn oloyun ni aarun vitiligo.

Koda, o sọ pe oun ko tii ri oloyun to ni aarun vitiligo ri.

Edokpolor fikun ọrọ rẹ pe oyun nikan kọ ni o n fa aarun vitiligo.

O ni o ṣeeṣe ki aarun yii ti wa lara tẹlẹ ki ẹni ti o ba mu to loyun.

Dokita naa sọ pe oyun nini maa n fa ila to maa n wa lara awọ oloyun amọ kii ṣe aarun vitiligo.