Nǹkan méje tí o kò mọ̀ nípa ẹyẹ̀ idì ‘eagle’ tó jẹ́ àmì ìdánimọ̀ Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lootọ ni idije ife AFCON 2023 ti pari, ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles, ko si ri i gba.
Ipo keji ni super Eagles ṣe.
Amọ ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo awọn amuyẹ ti ẹyẹ idi, ti wọn n pe ni Eagle ni ede Gẹẹsi ni, gẹgẹ bi ami idanimọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, ati orukọ wọn.
Oju opo itakun agbaye fun igbeaye awọn ẹranko, ati irugbin, Britannica, sọ pe ẹyẹ to jẹ akinkanju ni idi jẹ, to si tun jẹ apẹẹrẹ agbara ogun jija nigba aye ijọba Babiloni atijọ.
O le ni aadọta ẹya ẹyẹ idi to wa l’agbaye. Diẹ lara wọn ni harpy eagles, harrier eagl, hawk eagles, martial eagle, sea eagle, snake eagle, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nnkan meje to yẹ ko o mọ nipa ẹyẹ idi
1. O le ni aadọta ẹya ẹyẹ idi to wa
Ẹyẹ idi jẹ ara awọn ẹyẹ to wa lati agboole ti wọn n pe ni Accipitridae. Ikọọkan wọn si yatọ ni bi wọn sẹ tobi si, ati bi ẹnu wọn ṣe ri.
Ilẹ Africa ati Asia ni ẹyẹ idi wọpọ si julọ, iwadii si fihan pe o le ni ida ogoji ẹya ẹyẹ na to wa ni ẹkun mejeeji.
Awọn ẹkun bi Australia ati America ni awọn ẹya yooku wa. Eyi to wọpọ ni America ni wọn n pe ni Bald Eagle.
2. Ẹyẹ idi ni ayajọ ti wọn l’agbaye
Gbogbo ọjọ kẹwaa, oṣu Kinni lọdọọdun ni ọjọ ti wọn ya sọtọ l’’agbaye, lati fi polongo didaabo bo ẹyẹ idi lọwọ ewu, ki wọn ma ba a parun.
3. Ẹyẹ idi ma n ri ọna jinjin ni ilpo mẹjọ ju eeyan lọ
Awọn onimọ ijinlẹ nipa ẹyẹ, sọ ninu iwadii kan pe ko si iyatọ ninu bi oju eniyan ati oju ẹyẹ idi ṣe tobi to. Ṣugbọn ṣa, nnkan to ya ẹyẹ naa sọtọ ni bo ṣe ma n rina kedere lati ọọkan ju eeyan lọ.
Wọn ni ẹyẹ idi le ri ẹran to fẹ ẹ pa jẹ lati bi kilomita mẹta, to si le ri awọ marun-un lẹẹkan naa.
4. Ẹyẹ to ni ẹmi gigun ni idi
Ẹyẹ idi kii tete ku, paapaa awọn ti wọn ba tọju pamọ yatọ si awọn to n gbe ninu igbo. Iwadii sọ pe awọn ẹyẹ idi ti wọn tọju pamọ le lo to ọdun mejidinlaadọrin, eyi to jẹ ilọpo meji awọn akẹẹgbẹ wọn to n fo kiri.
Ida aadọta awọn ẹyẹ idi to wa ninu igbo kii le lo ju ọgbọn ọdun lọ, nitori ebi tabi ijamba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
5. Ẹyẹ idi kii kọ awọn ọmọ wọn bi wọn ṣe le fo
Tako bi awọn ẹyẹ kan ṣe ma n kọ awọn ọmọ wọn bi ṣe n fo, ẹyẹ idi kii sẹ bẹẹ.
Oun ma n fẹ ki awọn ọmọ rẹ kọ bi wọn ṣe le fo funra wọn. Ọna to ma n gba ni pe, kii tete fun wọn ni ounjẹ, ki ebi le pa wọn daadaa.
Igbagbọ ni pe ti ebi ba pa ọmọ ẹyẹ idi, ko si ẹni ti yoo kọ ọ lati do lọ wa ounjẹ jẹ.
Awọn onimọ nipa ẹyẹ sọ pe ilana yii ma n ṣiṣẹ ni ọpọ igba, paapaa ti awọn ọmọ ẹyẹ naa ba duro pẹ titi fun iya wọn lati gbe ounjẹ wa, amọ ti wọn ko ri i.
6. Ololufẹ kan ṣoṣo ni ẹyẹ idi ma n ni lọjọ aye rẹ
Ko si bi ẹyẹ idi ṣe pẹ laye to, oju kan ṣoṣo ni ada rẹ n ni. Ẹyẹ idi meji to ba ti n ba ara wọn ni ibalopọ, kii paarọ ololufẹ. Ẹyọkan ṣoṣo naa ni wọn o ba ni ibalopọ titi di ọjọ iku eyikeyi ninu wọn.
Iku tabi ti ọkan ninu wọn ba fo lọ fun bi ọdun kan tabi to deedee di awati, lo le mu ki ẹyẹ idi fun ẹlomii ni anfaani.
7. Omuwẹ to da n tọ ni ẹyẹ idi
Pupọ ninu awọn ẹyẹ idi lo jẹ omuwẹ gidi, paapaa ẹyẹ idi to pa lori ti wọn n pe ni bald eagle.
Iyẹ apa wọn to gun ma n mu ki iwẹ inu odo rrun fun wọn pupọ. Wọn si tun ma n le pa ẹran fun ijẹ ninu odo.












