Wo ìdí tí orí fífọ́ àbaadì fi má n yọ àwọn obìnrin lẹ́nu ju ọkùnrin lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ori fifọ abaadi ti Yoruba tun n pe ni ori tuulu, eyi ti wọn n pe ni Migraine ni ede Gẹẹsi jẹ irufẹ ori fifọ to kọja eyi ti ẹnu le sọ, to si ma n mu ki awọn eroja inu ọpọlọ ko wa ninu ewu.
Ẹnikẹni ti ẹfọri migraine ba n yọ lẹnu ma n fojuwina ori fifọ ti yoo dabi pe ori naa fẹ jabọ silẹ, paapaa julọ ni apa kan ori.
Irora yii kii rin lasan, o ma n mu aarẹ dani, pẹlu eebi. Bakan naa ni ẹni to ba n yọ lẹnu yoo ni irora lasiko to ba wo ina tabi imọlẹ tabi gbọ ariwo.
Ẹfọri Migraine le wa fun ọpọlọpọ wakati tabi ọjọ.
Awọn onimọ sọ pe eeyan bi miliọnu lọna ẹgbẹrin lo ni iru ẹfọri yii l’agbaye. Nilẹ America nikan, o to miliọnu mọkandinlogoji eeyan to ni ẹfọri naa ni gbogbo igba.
Fun awọn obinrin ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejidinlogun si mọkandinlaadọta, ẹfọri migraine lo n sọ wọn di alaabọ ara julọ ni agbaye.
Iwadii fihan pe ẹfọri naa ma n pẹ lara awọn obinrin ju ọkunrin lọ.
Bakan naa ni awọn onimọ sọ pe awọn obinrin to ba ni migraine le ni aisan ọpọlọ, to fi mọ ipaya ati irẹwẹsi ọkan.
Ki wa ni idi ti eyi fi ri bẹẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oriṣiriṣi nnkan iyalẹnu lo n mu ki awọn obinrin ni ẹfọri migraine ju awọn ọkunrin lọ.
Ẹ jẹ ka wo diẹ lara wọn.
Migraine ati Omoonu
Lara awọn nnkan to mu ki iyatọ wa ninu bi ọkunrin ati obinrin ṣe n foju wina ẹfọri migraine ni ‘hormones’wa. Bakan naa ni awọn idi kan jẹ ajogun ba, ati bi awọn eroja ara kan ‘gene’ ṣe n ṣiṣẹ si ninu ara.
Awọn idi wọn yii lo ma n ko ipa ninu bi ọpọlọ yoo ṣe ṣiṣẹ si ti eeyan ba ni ori fifọ yii.
Awọn omoonu bi oestrogen ati progesterone to wa lara awọn obinrin ma n gba oriṣiriṣi ọna lati sọ bi igbe aye obinrin yoo ṣe ri.
Awọn eroja yii ma n nipa lara oriṣiriṣi kẹmika to wa ninu ọpọlọ, to si le kopa ninu ayipada to n waye ni awọn abala kan ninu ọpọlọ to ma n lọwọ ninu ọfọri.
Yatọ si eyi, omoonu to nii ṣe pẹlu ibalopọ le mu ayipada ba awọn ọpa to n gbe ẹjọ ninu ara, to si le fa ori fifọ abaadi.
Fun awọn ọmọde, tọkunrin-tobinrin wọn lo le ni ẹfọri yii.
Akọsilẹ sọ pe ida mẹwaa ninu awọn ọmọde ni yoo ni ẹfọri migraine.
Ṣugbọn ti awọn ọmọbinrin ba ti balaga, naa ni bi migraine ṣe le mu wọn n pọ si.
Idi ni pe eroja omoonu to n ṣiṣẹ fun ibalopọ, ko duro si oju kan.
Awọn ọmọbinrin kan ma n ni ẹfọri migraine fun igba akọkọ lasiko ti wọn ba kọkọ ri nnkan oṣu wọn.
Ṣugbọn ẹfọri yii ma n waye leralera, to si ma n lagbara si i lasiko nnkan oṣu obinrin, ati fun gbogbo ọdun ti wọn ba fi n bimọ.
Awọn onimọ kan tun sọ pe ida aadọta si ọgọta obinrin lo ma n ni ẹfọri lasiko nnkan oṣu wọn nikan.
Eyi ma n waye nitori adinku to le ba eroja oestrogen.
Ori fifọ lasiko nnkan oṣu ma n l’agbara pupọ, to si tun ma n pẹ ju ti awọn asiko yooku lọ
Ki ni ọna abayọ?
Fun awọn obirnin to ba n la iru nnkan bayii kọja, awọn onimọ iṣegun oyinbo sọ pe ki wọn o yago patapata fun awọn ilana ifetosọmọbibi to ba ni eroja oestrogen ninu.
Eroja yii ninu ilana ifetosọmọbibi le fa aisan rọpa-rọsẹ nitori pe oestrogen to n pọ si le mu ki ẹjẹ didi pọ.
Ilana ifetosọmọbibi to dara fun awọn obirnin to ba ni migraine ni eyi to ni progesterone nikan.
Ori fifọ ninu oyun ati ti nnkan oṣu ko ba wa mọ
Fun awọn obinrin to ba loyun, ori fifọ le mu ko rẹ wọn ni oṣu mẹta akọkọ, to si le mu ko nira lati jẹun, sun tabi mu omi.
Bakan lo jẹ pe ori fifọ naa ma n pọ si ti wọn ko ba ṣe eyikeyi ninu awọn nnkan mẹta naa.
Amọ ti oyun ba ṣe n pẹ si i, ni ẹfọri naa ma n dinku lara awọn kan. Ṣugbọn fun awọn alaboyun mii, eyi ko ri bẹẹ.
Nitori naa, ori fifọ fun awọn obinrin to ba ni ẹfọri ni gbogbo asiko ti wọn loyun, tun le pọ si i lẹyin ti wọn ba bimọ tan.
O le jẹ nitori awọn omoonu kan to dinku ninu ara, tabi airoorun sun, aimu omi to bo ṣe yẹ, ati awọn nnkan miran to niiṣe pẹlu itọju ọmọ tuntun.
Yatọ si awọn alaboyun, ori fifọ abaadi le pọ si i ti obinrin ba ti n sunmọ asiko ti nnkan oṣu rẹ yoo dopin lati ma a wa.
Amọ bi obinrin ba ṣe n dagba si i ni ipele ti nnkan oṣu ti dawọ duro patapata, menopause, ni ori fifọ naa yoo ma a dinku. O ti lẹ ma n lọ patapata lara awọn kan.
Eyikeyi to ba wu ko jẹ, o sẹ koko ki obinrin fi to awọn dokita rẹ leti lati mọ ọna abayọ ati fun imọran lori igbeaye.














