Wo àwọn tó fẹ̀sùn olè kan Lizzy Anjorin, àti ohun tí ọlọ́pàá ń ṣe fún wọn lọ́wọ́lọ́wọ́

Aworan Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin/Instagram

Ko din ni afurasi mẹfa ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko wọ lọ si ileẹjọ Majisireeti to wa ni Lagos Island, ipinlẹ naa l’Ọjọbọ, ọsẹ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ.

Awọn mẹfa yii ti wọn n ta ọja ninu Ọja Ọba Akintoye to wa ni Lagos Island la gbọ pe wọn doju ija kọ gbajugbaja oṣerebinrin Yoruba naa iyẹn, Elizabeth Anjọrin-Lawal, ẹni tọpọ mọ si Liz Anjọrin.

Qudus Jokogbọla, Suru Ọlawale, Edu Shakirat, Fausat Mohammed, Kafayat Ahmẹd, ati Ọpẹrẹ Simiat Morẹnikẹ lorukọ mẹfẹẹfa ti wọn kawọ pọyin rojọ niwaju Onidajọ A.A. Paul.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni fọnran kan jade sori ikanni ayelujara kaakiri, nibi ti awọn kan ti n fi ẹsun jibiti kan Liz Anjọrin.

Ninu fọnran ọhun, wọn sọ pe Liz Anjọrin ra ọja to to ẹgbẹrun lọna aadọrun-un (N90,000) naira, ṣugbọn kaka ko san owo fun wọn, ayederu owo lo fi ranṣẹ lati ori foonu ẹ si wọn, to si salọ.

Aworan Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, Lizzy Anjorin

Eyi ni wọn lo bi Liz Anjọrin ninu, to fi gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi ẹjọ sun, ti awọn ọlọpaa si pada lọ ko gbogbo wọn.

Ṣaaju asiko yii ni Liz funra ti kọkọ gba ori ikanni ayelujara ti Instagram rẹ lọ, nibi to ti lọ ṣalaye pe irọ ni wọn pa mọ oun, ati pe wọn kan fẹẹ ba oun lorukọ jẹ lasan ni.

Agbefọba Ṣọla Samuel to fẹsun kan awọn eeyan naa niwaju ile-ẹjọ jẹ ko di mimọ pe mẹjọ ni gbogbo awọn to wa ninu iwe ẹsun, ṣugbọn to sọ pe awọn meji yooku ti na papa bora.

Samuel ni nnkan bi aago kan aabọ ọsan ni wọn purọ mọ Liz Anjọrin, ti wọn si yẹyẹ rẹ, pẹlu bi wọn tun ṣe lu lalubami, nibi to ti farapa gidi gan an.

O sọ siwaju pe iwa ti awọn eeyan naa hu tako iwe ofin ọdaran ni dida alaafia ilu laamu ni abala 411 ati 413; pẹlu abala 168(d) ati 170(b) ti ipinlẹ Eko lọdun 2015.

Loju ẹsẹ ni awọn mẹfẹẹfa naa ti sọ pe awọn ko jẹbi ti wọn fi kan awọn.

Agbẹjọro awọn olujẹjọ yii, Ade Oshodi wa rọ ile-ẹjọ lati foju aanu wo wọn nipa gbigba beeli wọn, nitori pe ontaja ni wọn.

Nigba to n paṣẹ, Onidajọ A.A. Paul ni ki ẹnikọọkan wọn lọ san ẹgbẹrun lọna igba naira pẹlu oniduro kọọkan ki wọn too gba beeli wọn.

Bakan naa lo ni ki wọn ṣi wa ni ọgba ẹwọn titi digba ti wọn yoo fi ri awọn amuyẹ naa pe, ati pe awọn oniduro wọn gbọdọ jẹ awọn to n san owo ori wọn deedee nipinlẹ Eko.

Onidajọ Paul wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2024.

Ki lo ṣẹlẹ gangan?

Aworan Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, lizzyanjorin_original/screenshot

Ni ọjọ Iṣẹgun ni iroyin kan bọ si ori ayelujara eyi to so rọ mọ gbajumọ oṣere sinima, Lizzy Anjọrin.

Ohun ti iroyin naa sọ ni pe awọn kan fi ẹsun kan an pe o ṣe ayederu ifoworanṣẹ ti oyinbo n pe ni ‘transfer’fun onibara rẹ kan to ra ẹṣọ obinrin lọwọ rẹ.

Ko si ṣẹyin fọnran fidio kan to lu sita nibi tawọn kan ti sọ pe awọn ọlọja to n ta goolu lọja kan n ṣe fakinfa pẹlu Lizzy pe o ra goolu ko fẹ san owo.

Fọnran fidio yi taa ri loju opo ayelujara ṣafihan eeyan kan to jọ Lizzy Anjorin to si fi ibomu nose mask ṣẹnu.

A ko gbọ nkan ti wọn n sọ ninu fidio yi tori pe ohun orin ti wọn fi sabẹ fidio naa nikan lo jade sita taa n gbọ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Amọ akọle ti o ba fidio naa n ṣalaye pe Lizzy Anjorin ni awọn ontaja n ba fa surutu lori ẹsun pe o fi ayederu alati san owo ọja goolu to ra.

Ninu fidio mii ti a ti gbọ ohun awọn eeyan to n sọrọ nibẹ, awọn eeyan n darukọ Lizzy Anjorin gẹgẹ bi ẹni to wa ninu fidio naa.

Ohun eeyan kan n beere pe ''elo ni?'' ti ẹlomiran si dahun pe ''90k''

Loore koore ninu fidio naa ni a n gbọ ti eeyan kan n sọ pe ''Lizzy Anjorin ni.Ohun ni''

A tun ri ninu akọle ti eeyan kan kọ sabẹ fidio yi wi pe ọja Akinyosoye International Market ni ilu Eko ni iṣẹlẹ yi ti waye.

Ati fido kini ati ẹlẹẹkeji la ko le fidi ọrọ mulẹ lori wọn amọ Lizzy Anjorin naa ti jade sita lati sọrọ nipa ohun to waye

Ki ni esi ti Lizzy Anjọrin fi sita si iroyin naa nigba naa?

Aworan fidio naa

Oríṣun àwòrán, screenshot

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbolohun to gbẹnu Lizzy Anjorin ree ninu fidio to gbe si oju opo rẹ nipa iṣẹlẹ to waye yi.

Ninu fidio naa to gbe sita ni ọjọ Aje, a ri oju Lizzy Anjorin kedere to si n tẹnumọ pe ẹnikan ''Ṣẹpẹtẹri'' lo gbiyanju lati ka ẹsun si oun lọrun.

O ni ''Ṣe o ri nkan to ṣẹlẹ lonii? O wa jẹ ki n ranti bo ṣe palẹmọ Egbegbe,ọgbọn kan naa lo lo''

Ẹgbẹgbẹ ti Lizzy Anjorin n darukọ yi ni Seun Egbegbe to jẹ gbajugbaja oludari sinima ti wọn fẹsun kan ninu fidio kan pe o fẹ fi ọgbọn gbajuẹ ji foonu Iphone mẹsan ni Computer Village nigba naa lọhun.

Lizzy Anjorin sọ pe ọgbọn yi kole ṣiṣẹ nitori pe wọn sọ pe foonu ni Seun Egbegbe lọ ra ti wọn fi mu ti oun ko si lọ ra foonu.

O ni ni toun, nkan elo aṣọ riran loun lọ ra lọja nigba ti iṣẹlẹ yi fi waye.

Lizzy fi kun pe ọja ẹgbẹrun mọkanlelaadọrun Naira loun ra ti ọkọ oun si fi owo ranṣẹ si akanti ẹni to taja fun.

O sọ pe ''mo beere lọwọ arakunrin naa pe ṣe o ri owo ti wọn fi ranṣẹ o si sọ pe rara.Ni mo ba fi kuro nibẹ. Mo lọ fun nnkan bi wakati meji ki n to pada sibẹ. Mo tun beere pe ṣe o ti ri owo naa to si sọ pe oun ti rii. Lẹyin igba naa ni mo kuro nibẹ.”