Kò sí ajínigbé tàbí agbébọn tó lè dá mi lọ́nà tàbí jí mi gbé - Oluwo

Oríṣun àwòrán, oluwo
Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti sọ pe ko si agbebọn tabi ajinigbe kankan to le pa oun danu, tabi ji oun gbe lorileede Naijiria.
Kabiyesi naa sọ pe awọn agbebọn ati ajinigbe ti bẹrẹ si doju kọ awọn ọba alaye nitori pe wọn gbojule awọn agbara ti wọn ni.
Ọba Akanbi ni Ọlọrun nikan toun gbojule lo ti n jẹ alaabo fun oun latilẹ.
Oluwo lo sọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni aafin rẹ to wa niluu Iwo, ipinlẹ Ọṣun laipẹ yii.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe ko le si aabo to pe ye fun awọn ọba alaye ti wọn n gbojule awọn oriṣa ati irunmalẹ, ati pe yoo baa tabuku ba ibujoko wọn lasan ni.
“Mo n sọ fun un yin bayii pe ko si ẹni naa to le gboju-gboya lati gbiyanju pe oun fẹẹ ji mi gbe tabi pinnu lati pa mi danu
“Aabo Ọlọrun wa lori mi, kii ṣe nipa oriṣa tabi irunmalẹ kankan.
“Mo n fi asiko yii rọ awọn ọba alaye ẹgbẹ mii lati dẹkun gbigbe ireti wọn lori awọn irunmalẹ, bi ko ṣe pe ki wọn pada si ọdọ Ọlọrun ti wọn n ṣoju.”

Oríṣun àwòrán, oluwo
Siwaju sii lo sọ pe asiko yii ni awọn araalu n kọminu lori awọn ọba alaye mẹta ti wọn padanu ẹmi wọn sọwọ awọn agbebọn nipinlẹ Ekiti ati Kwara laarin ọsẹ meloo kan sẹyin.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn ajinigbe ji awọn alaye meji gbe nipinlẹ Ekiti, ti wọn si pa wọn.
Elesun tiluu Esun-Ekiti, Ọba David Ogunṣakin; ati Ọba Ọlatunde Oluṣọla, to jẹ Onimojo tiluu Omojola-Ekiti ni awón ọba mejeeji ti wọn pa.
Ko ju bi ọjọ meloo kan si asiko naa ni awọn ajinigbe tun yawọ Aafin Onikoro tiluu Koro-Ekiti nijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara, nibi ti wọn ti pa Ọba Peter Arẹmu.















