Kí ni àìsàn jẹjẹrẹ, àti àwọn ohun tí a mọ̀ nípa ohun tó ń bá Ọba Charles fínra?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, King Charles Kẹta ti ní àìsàn jẹjẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ààfin Buckingham ṣe sọ.
Lásìkò tó lọ fún ìtọ́jú kan ni wọ́n fìdí èyí múlẹ̀. Ọba Charles ti bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú, tí wọ́n sì ti gbà á nímọ̀ràn láti yé ṣe iṣẹ́ tí yóò máa mu jáde lásìkò yìí.
Irú àìsàn jẹjẹrẹ wo ni Ọba Charles ní?
Wọn kò ì tíì fi irú àìsàn jẹjẹrẹ tí ọba Charles ní léde tàbí ilé ìwòsàn tó ti ń gba ìtọ́jú.
Ẹ̀wẹ̀, wọ́n ní kìí ṣe nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ jẹjẹrẹ ni jẹjẹrẹ ń dà láàmú.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Kí ni ọjọ́ orí ọba Charles àti pé ta ni àrẹ̀mọ rẹ̀?
Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin ni Ọba Charles Kẹta. Ní oṣù Kẹsàn-án ọdún 2022 ló jẹ Ọba United Kingdom lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀, Ọbabìnrin Elizabeth Kejì jáde láyé lẹ́yìn tó lo àádọ́rin lórí oyè.
William, ẹni ọdún mọ́kànlélógójì, tó tún jẹ́ ọmọ ọba Wales ní àkọ́bí Ọba Charles, tó sì lẹ́tọ̀ọ́ sí ipò náà bí bàbá rẹ̀ bá jáde láyé.
Ǹjẹ́ àìsàn jẹjẹrẹ yìí ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìtọ́jú "prostate enlargement" tó Oba Charles n gbà tẹ́lẹ̀?
Láìpẹ́ yìí ni Ọba Charles gba ìtọ́jú lórí àìsàn "prostate enlargement".
Lásìkò ìtọ́jú rẹ̀ yìí ni wọ́n ṣàwárí ohun mìíràn tí wọ́n sì ní àìsàn jẹjẹrẹ ni.
Yóò máa gba ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ yìí láì dùbúlẹ̀ sílé ìwòsàn.
Kí ni àìsàn jẹjẹrẹ?
Àìsàn jẹjẹrẹ máa ń wáyé nígbà tí àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀yà ara kan bá pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ sí àwọn ọ̀nà tí kò ṣe mójútó.
Àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí le tàn ká sí àwọn ẹ̀yà ara mìíràn tó sì lè gba ibẹ̀ di àìsàn jẹjẹrẹ.
Báwo ni wọ́n ṣe ń mọ àìsàn jẹjẹrẹ?
Àwọn dókítà máa ń bèrè ìbéèrè lórí àwọn ìpèníjà tí èèyàn bá ń dojú kọ ní ara. Bákan náà ni wọ́n máa ń ṣe àyẹ̀wò láti mọ ohun tó bá ń ṣe èèyàn.
Lára àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n máa ń ṣe ni àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀, X-ray àti àyẹ̀wò inú. Bákan náà ni wọ́n máa ń gba "tissue" ara láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀ nílé àyẹ̀wò.
Nígbà, gẹ́gẹ́ bí i ti Ọba Charles, àsìkò tí àwọn èèyàn bá lọ fún àyẹ̀wò ara wọn ni wọ́n máa ń ṣàwárí jẹjẹrẹ.
Àwọn àmì ni àyẹ̀wò àìsàn jẹjẹrẹ máa ń ṣàwárí lára ẹni tí àmì rẹ̀ kò bá ì tíì ma jáde lára rẹ̀.
Èèyàn mélòó ló ní jẹjẹrẹ ní àgbáyé?
Oríṣìí àìsàn jẹjẹrẹ tó wà lé ní igba.
Àjọ tó ń mójútó ètò ìlera ní àgbáyé, WHO ní àwọn àìsàn jẹjẹrẹ tó gbajúmọ̀ ni jẹjẹrẹ ọyàn, ọ̀nà ọ̀fun, ojú ara, colon and rectum àti prostate.
WHO ní jẹjẹrẹ ló ń ṣokùnfà ikú èèyàn kan nínú èèyàn mẹ́fà tó ń jáde láyé.
Bí èèyàn bá ṣe ń dàgbà si ní ó ṣeéṣe kó ní àìsàn jẹjẹrẹ sí àti pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ṣàwárí àìsàn jẹjẹrẹ lára wọn ló jẹ́ pé wọ́n ti lé ní àádọ́ta ọdún.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde àjọ BMC Public Health, ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta èèyàn tó ní àìsàn jẹjẹrẹ láyé ni wọ́n ti lé ní márùndínlọ́gọ́rin lọ́jọ́ orí.
Àìsàn jẹjẹrẹ wọ́pọ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà gẹ́gẹ́ bí Cancer Atlas ṣe ní àwọn orílẹ̀ èdè Yúróòpù, China, Northern America ló ní Ìṣẹ̀lẹ̀ àìsàn jẹjẹrẹ tó pọ̀ jù ní àgbáyé.
Kí ni àwọn ìtọ́jú tó wà fún àìsàn jẹjẹrẹ?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtọ́jú ló wà láti tọ́jú tàbí ṣe àmójútó àìsàn jẹjẹrẹ. Irú jẹjẹrẹ tó bá jẹ́ ní yóò sọ irú ìtọ́jú tí wọn yóò ṣe fun.
Iṣẹ́ abẹ ni wọ́n fi máa ń yọ jẹjẹrẹ mìíràn, tó sì jẹ́ pé oògùn nípasẹ̀ fífi sínú iṣan ara tí wọ́n ń pè ní "chemotherapy" ni wọ́n fi máa ń wo òmíràn.
"Radiotherapy" náà jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí wọ́n fi máa ń wo àìsàn jẹjẹrẹ.
Àmọ́ ṣá, kìí ṣe gbogbo àwọn ìtọ́jú yìí ló máa ń wo jẹjẹrẹ sàn.

Èèyàn mélòó ló máa ń móríbọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ?
Láti bí àádọ́ta ọdún ni àlékún ti ń bá iye èèyàn tó ń rí ìwòsàn lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìròyìn ètò ìlera, the Lancet ṣe sọ, bí àlékún ṣe bá ìwòsàn fún jẹjẹrẹ ọyàn, lékún dada ní North America, Australia, Japan àti ìwọ oòrùn Yúróòpù.
Wọ́n ní ó kéré ní Algeria, Brazil àti ìlà oòrùn Yúróòpù.
Ó máa ń rọrùn láti móríbọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ fún ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá ì tíì pé ogójì ọdún tí wọ́n fi mọ̀.
Kí ni àwọn nǹkan tó yẹ kí o ṣe tí o bá rò wí pé o ní jẹjẹrẹ?
Tí o bá rí àwọn nǹkan àjòjì ni ara rẹ, kàn sí dókítà rẹ.
Lára àwọn nǹkan tí o lè rí ni:
- kí ẹ̀jẹ̀ máa yọ lára rẹ láì nídìí
- kí ibì kan máa wú lára rẹ
- kí ó máa rẹ èèyàn láì nídìí tàbí kí èèyàn máa rù púpọ̀
- kí èèyàn máa wúkọ́
Àwọn àmì tí ò ń rí lè má jẹ ti àìsàn jẹjẹrẹ àmọ́ ó dára láti ṣàyẹ̀wò.
Ṣíṣe àwárí àìsàn jẹjẹrẹ lásìkò máa ń jẹ́ kó rọrùn láti tọ́jú.















