Àyẹ̀wò ti fihàn pé Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Charles ní àìsàn jẹjẹrẹ

Oríṣun àwòrán, PA Media
- Author, Sean Coughlan
- Role, Royal correspondent
Aafin Buckingham Palace ni ilẹ Gẹẹsi ti kede pe ayẹwo ti fihan pe Ọba Charles ti ni aarun jẹjẹrẹ ti oloyinbo n pe ni cancer.
Aarun jẹjẹrẹ yii kii ṣe jẹẹrẹ asetọ ti oyinbo n pe ni prostrate cancer, amọṣa ayẹwo ṣawari aisan yii lasiko to gba itọju laipẹ yii fun bi nnkan ọmọkunrin rẹ se tobi kọja bi o ṣe yẹ.
Wọn ko tii sọ irufẹ aarun jẹjẹrẹ to jẹ, amọṣa atẹjade kan ti aafin ilẹ Gẹẹsi fi sita sọ pe, Kabiyesi ti bẹrẹ si ni “gba itọju bi o ṣe yẹ” lati ọjọ Aje.
Ọba Charles, to ti pe ẹni ọdun marundinlọgọrin bayii, yoo yẹba fun fifara han ni ita gbangba fun asiko yii, Olori rẹ, Ọbabinrin Camilla ati Ọmọọba William yoo maa ṣoju fun un lasiko to fi n gba itọju.
Ko si afikun ọrọ kankan mọ nipa ipele ti aarun jẹjẹrẹ naa wa tabi ohun to ṣe okunfa rẹ.
Kabiyesi ni ‘afojusun rere nipa itọju ara rẹ’
Aafin Buckingham ni “ọkan Oba ilẹ Gẹẹsi naa balẹ pẹlu itọju to n gba lọwọ, bẹẹ lo si n reti ati pada si ẹnu iṣẹ ilu laipẹ.”
Ẹkunrẹrẹ atẹjade ti aafin fi sita

Bi o tilẹ jẹ wi pe yoo dawọ fifarahan ni awọn eto ita gbangba duro, amọṣa Kabiyesi yoo tẹsiwaju pẹlu awọn ojuṣe rẹ labẹ ofin gẹgẹ bi olori orilẹede naa.
O wa ni ile ijọsin ni Sandringham ni ọjọ Aiku nibi ti o ti juwọ si ọpọ ero to wa nibẹ.
O gba itọju lori isetọ rẹ ni ile iwosan aladani kan ni ilu London ni nnkan bii ọsẹ kan ati diẹ sẹyin.
Kii ṣe jẹjẹrẹ asetọ
Kabiyesi gba lati kede ipo ilera rẹ nipa itọju asetọ rẹ lati ṣe koriya fun awọn ọkunrin pa ki awọn pẹlu le maa lọ fun ayẹwo nnkan ọmọkunrin wọn.
Inu rẹ dun pupọ lati ṣe itaniji lori ọrọ naa, pẹlu bi ileeṣẹ ilera apapọ ni ilẹ Gẹẹsi, NHS ṣe fi si oju opo ayelujara rẹ pe ọrọ ipenija ailera nipa isetọ ọkunrin ti n gogo sii.
Aridaju wa pe kii ṣe jẹjẹrẹ asetọ, amọṣa lasiko itọju rẹ fun bi nnkan ọmọkunrin rẹ se tobi kọja bi o ṣe yẹ laipẹ yii ni ayẹwo fi han.
Yoo maa gba itọju amọṣa ireti wa pe wọn ti tete kẹfin jẹjẹrẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Yiyẹba diẹ
Kabiyesi yoo yẹba fun fifara han ni ita gbangba fun asiko yii, Olori rẹ, Ọbabinrin Camilla ati Ọmọọba William yoo maa ṣoju fun un lasiko to fi n gba itọju.
Ẹni ọdun marundinlọgọrin ni Ọba ilẹ Gẹẹsi, yoo ṣi maa tẹsiwaju pẹlu awọn iṣẹ ilu ti ofin gbe le lọwọ gẹgẹbi olori orilẹede.
O fara han nibi iṣẹ isin kan ni Sandringham ni ọjọ Aiku nibi ti o ti ju ọwọ si ọgọrọ eeyan nibẹ.
O gba itọju lori isetọ rẹ ni ile iwosan aladani kan ni ilu London ni nnkan bii ọsẹ kan ati diẹ sẹyin.

Kabiyesi gba lati kede ipo ilera rẹ nipa itọju asetọ rẹ lati ṣe koriya fun awọn ọkunrin pa ki awọn pẹlu le maa lọ fun ayẹwo nnkan ọmọkunrin wọn.
Inu rẹ dun pupọ lati ṣe itaniji lori ọrọ naa, pẹlu bi ileeṣẹ ilera apapọ ni ilẹ Gẹẹsi, NHS ṣe fi si oju opo ayelujara rẹ pe ọrọ ipenija ailera nipa isetọ ọkunrin ti n gogo sii.

Oríṣun àwòrán, PA Media
Itọju aisan jẹjẹrẹ yoo nilo ọna igbalode chemotherapy -eyi ti yoo nilo lilo ogun lati pa awọn sẹẹli aisan jẹjẹrẹ naa; ati nipa ilana radiotherapy – eyi ti wọn yoo ti lo imọlẹ Radiation fi pa awọn eroja sẹẹli aisan jẹjẹrẹ naa tabi awọn ogun to maa n pa eroja sẹẹli aisan jẹjẹrẹ ni agọ ara.















