Ilééṣẹ́ Ọlọ́pàá sàfihan afurasí mẹ́tàlá lórí jíjí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti ikú àwọn ọbalayé ní Ekiti

Aworan

Ileesẹ ọlọpaa ipinle Ekiti ti ṣafihan awọn afurasi agbebọn mẹtala ti wọn sekupa pa ọbalaye meji ni agbegbe Oke-Ako nipinlẹ Ekiti nigba ti wọn n ti ipade kan bọ ati awọn afurasi to ji awọn ọmọ ile ẹkọ The Apostolic Faith Montessori School Emure Ekiti gbe pamo.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori aseyori naa, Ọga agba ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Ekiti, Dare Ogundare so pe gbogbo akitiyan awon eleto aabo ni ipinle Ekiti lati mu awọn agbebọn na.

Ogundare ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa ni igbo kan to wa laarin Ayedun ati Ayebode, to si jẹ ko di mimọ pe ọkan lara awọn afurasi naa ti jẹwọ pe oun mọ nipa isẹlẹ naa.

“Alhaji Babunga, ọkan lara awọn agbebọn to kopa ninu isekupani awọn Ọba meji ti jewo fun awọn pe oun lowo ninu iṣẹlẹ naa

AIG Ogundare ni awọn ko mu afurasi kankan lasiko ti wọn dola awọn akẹkọọ ati olukọ to ko sọwọ awọn ajinigbe sugbọn o sọ fun awọn akọroyin pe awọn mu awọn afurasi naa ni agbegbe Oke Osun ni Ikere Ekiti, Igbo Okah ati inu igbo Iju-Ikere

Nigba to n fesi si ibeere pe boya wọn san owo fun itusilẹ kankan fun awọn ajinigbe lati tu awọn akẹkọọ ati olukọ silẹ, Ogundare ni igbesẹ yii lo lodi si ofin, ti ijọba ko si ni rọ awọn eeyan lati ma se san owo itusilẹ fin awọn ajinigbe

Lẹyin naa ni Ọga ọlọpaa kẹdun pelu awọn mẹlẹbi dirẹba to padanu ẹmi rẹ ninu iṣẹlẹ naa.

Aworan
Aworan
Aworan