Ìjọba Nàìjíríà kò lérò láti tọwọ́ bọ owó dọ́là táwọn ọmọ Nàìjíríà fi pamọ́ - Cardoso, Gómìnà báǹkì àpapọ̀, CBN

Aworan Gomina banki apapọ

Oríṣun àwòrán, cenbankng

Ko si ootọ ninu ọrọ to gbode pe banki apapọ fẹ tọwọbọ oṣunwọn owo dọla awọn ọmọ Naijiria.

Ọrọ ree ti Gomina banki apapọ Naijiria Olayemi Cardoso fọ lesi nigba to n dahun ibeere lori eto ileeṣẹ amohunmaworan Naijiria kan Arise Daily.

Cardoso sọ pe iru iwa bayi tako gbogbo iyipada daaa tawọn n gbero lati mu ba ẹka ifowopamọ.

O ni ''Mo fẹ fi daa yin loju pe eleyi ko si ni ibamu pẹlu afojusun awa adari banki apapọ Naijiria''

Igba akọkọ ree ninu ifọrọwerọ ti Olayemi Cardoso yoo mu alaye bẹnu lori bi owo Nairia ti ṣe dẹnukọlẹ lẹgbẹ dọla ti nkan ko silọ deede lagbo eto ọrọ aje Naijiria.

Lori ọna ati ro owo Naira lagbara lẹgbẹ akẹgbẹ rẹ dọla, Cardoso sọ pe awọn ile ifowopamọ ni lati ṣe agbejade owo dọla to wa ni akasọ wọn.

Cardoso sọ pe awọn banki kan ti wawọ mọ owo ilẹ okere to wa ni akaunti wọn fọjọ pipẹ tawn si ti ni ki wọn gbe owo yi sita fawọn to nilo rẹ.

O sọ pe bi wọn ba ṣe eleyi, yoo jẹ ki Naijiria le koju ipenija ipese owo ilẹ okere fawọn to fẹ si ṣe idokoowo kan tabi omiran.

Cardoso sọ pe afojusun oun ni pe asiko kan yoo pade waye ti eeyan ko ni mọ ẹnikankan ni banki apapọ tabi awn ile ifowopamọ si ko to le ri owo dọla gba fun nkan to ba fẹ fi ṣe.

''Ti a ba ni eto ti ko lẹja n bakan ninu, ko ni faaye silẹ fun awọn kudiẹkudiẹ to n waye ni ẹka ifowopamọ Naijiria''

Iyatọ diẹ lo wa laarin paṣiparọ owo banki ati awọn bureau d change

Cardoso mẹnu ba ọrọ paṣiparọ owo Naira si dọla eleyi to ṣọ pe awọn kudiẹkudiẹ kan latẹyinwa lo ṣokunfa bi wọn ṣe jina si ara wọn.

O ni awọn n gbero gẹgẹ bi banki apapọ lati ri pe gbogbo awọn to n ṣe owo fifi owo ranṣẹ taa mọ si International Money Transfer Operators bẹrẹ si ni ṣe bẹẹ ni ibamu pẹlu alakalẹ banki apapọ.

O ni aisi eto to n dari fifi owo ranṣẹ yi lo mu ki iyatọ maa wa laarin iye owo ti banki apapọ ni ki wọn maa ta awọn owo yi ati iye tawọn n gba lori rẹ.

O ṣalaye pe bayii iyatọ diẹ lo wa laarin owo Naira ni piparọ lọdọ awọn ti ile ifowopamọ ati awọn ti bureau d change.

O ni awọn ti gbe awọn ilana tuntun jade ti awọn si lero pe eleyi yoo mu adinku ba bi segesege ṣe n waye nibi paṣiparọ owo Naira si dọla.

$2.4bn ninu $7bn owo taa jẹ awọn to fẹ gba owo ilẹ okere la ri pe ko yẹ ni sisan

Nipa awọn gbese to wa nilẹ lori owo ilẹ okere ti banki apapọ jẹ awọn to nilo owo yi, Cardoso sọ pe kii ṣe gbogbo awọn to kọwe lati gba owo naa lo lẹtọ si.

O ni lẹyin agbeyẹwo finifin awọn rii wi pe biliọnu meji le diẹ $2.4bn ninu awọn owo yi ni o ni kọnunkọhọ ninu.

O ṣalaye pe ninu gbesẹ biliọnu meje tawọn jogun lọwọ awọn to ṣakoso banki naa kọja, awọn ti san $2.3bn ti o si ku $2.2bn nilẹ gẹgẹ bi gbesẹ.

O ni awọn gbe iṣẹ ayẹwo yi fun ileeṣẹ Deloitte lati m owo to yẹ ni sisan ati eleyi ti ko yẹ.

Lara nkan to ni o tu asiri ni pe awọn ri pe awọn to n beere owo yi ko ni nkankan ṣe tabi wn ko lẹtọ lati gba owo ilẹ okere yi .

Ninu awọn ti wn san owo fun to darukọ lawọn to wa ni ẹka ileeṣẹ ofurufu ati awọn mii .

O ni laipẹ lawọn yoo san owo to ku tan.