Lahanmi: Kí ló fa èlé owó orí ọjà, ipa rẹ̀ lórí ìdílé, ẹ̀bí ta ni àti ọ̀nà àbáyọ

Àkọlé fídíò, Laahanmi: Kí ló fa èlé owó orí ọjà, ipa rẹ̀ lórí ìdílé, ẹ̀bí ta ni àti ọ̀nà àbáyọ

Bi ebi ba ti kuro ninu isẹ, isẹ buse ni Yoruba n wi amọ ibeere ti ọpọ eeyan n beere ni pe igba wo ni isẹ yoo buse ni Naijiria nitori ebi ko dawọ duro.

Ebi ko si lee dawọ duro nitori awọn owo eroja to gbẹnu soke nilẹ wa, paapaa awọn eroja ounjẹ.

Eyi lo mu ki eto wa ọlọsọọsẹ, Laahanmi fi boju wo awọn ipo ti owo eroja wa nilẹ yii, ki lo se okunfa ọwọn gogo wọn ati ọna abayọ.

Bakan naa la tun wo ipa ti ọwọn gogo ọja ati ounj ti n ni lori awọn ọmọ Naijiria ati idagbasoke wa.

Ipo wo ni ọwọn gogo ọja wa ni Naijiria?

Eto Laahanmi se iwadi lati mọ odiwọn ipo ti ele ori ọja wa ni Naijiria, ggẹ bi awọn onimọ iwadi nipa ọrọ aje ti sọ.

A ri ka pe ida mọkandinlogun ati aabọ ni ele to ba owo eroja nilẹ Naijiria ta ba wo akọsilẹ ajọ to n ri si idiyele owo eroja ọja nil wa.

Bakan naa ni ajọ naa fikun pe o ti to ọdun mẹtadinlogun sẹyin ti ele ọja ti waye kẹyin bayiii lorilẹede Naijiria.

Ki lo sokunfa ele owo ounjẹ ati ọja ni Naijiria?

Gẹgẹ bi Laahanmi ti se iwadi rẹ, a ri pe aifararọ eto aabo to n ba wa finra lorilede yii wa lara ohun kan gboogi to n se okunfa ele owo ounjẹ lorilẹede yii.

Ko sibi ti nnkan ti fara rọ lẹka eto aabo lorilede yii, eyi to mu ki jinni jinni maa de bawọn agbẹ lati lọ sinu oko wọn nitori awọn agbebọn ati ajinigbe.

Bakan naa ni pasipaarọ owo naira il wa si ti ilẹ okeere ko rẹrin rara nitori agbara owo Naira ilẹ wa ti mẹhẹ ju.

Eyi lo si mu ki owo awn ọja ta n ko wle lati oke okun maa gbe owo gege sori.

Tunwẹ, ọpọ ọdọ ni ko setan lati kopa ninu isẹ ọgbin, ti ounjẹ yoo fi sun wa bọ, to si jẹ pe awọn agbẹwa to n pese ounj ni ọpọ wọn ti darugbo patapata.

Ipa wo ni ọwọn gogo eroja ati ounjẹ n ni lori idile:

Akaakatan ni awọn ipa ti ọwọn gogo ọja yii n ni lori idile wa, to si kọja sisọ.

Gẹgẹ bi Laahanmi ti wi, se ni iwa ikanra gba inu ẹbi kọọkan kan, nitori aisi owo lati ra ounjẹ, iwọnba owo ti wọn si ni ko le ra ọpọ ohun ti wn fẹ.

Koda, aimọye iroyin lo ti sọ nipa bi ọkọ se n pa aya rẹ nitori owo ounjẹ tasọrẹ, ti aya naa si n se ọkọ lese nitori aile pese ounjẹ oojọ sinu ile.

Iwa idigunjale, ijinigbe gba owo atawọn iw aibi miran wa n lekeeka si lawujọ wa nitori ọrọ aje to dẹnu kọl ati ọwọn gogo ounjẹ oojọ.

Ki ni ọna abayọ:

Ninu alaye Laahanmi, se lo y ki ijọba tete wa wọrọkọ fi sada lati pese aabo to peye si Naijiria eyi ti yoo se iwuri fun ọpọ ọmọ orilede yii lati pada soko.

Bakan naa lo yẹ ka wa ọna ti pasipaarọ owo naira ilẹ wa yoo fi lowura si, ti yoo si le ta kangbọn plu awn owo il okeere eyi ti yoo mu adinku ba owo awọn ọja to n wọle lati oke okun.

Tun wẹ, gbogbo wa lo yẹ ka maa gbin eroja ounjẹ, ka da oko, paapaa si agbala wa, ka le ri ọwọ mu lọ sẹnu.

Laahanmi tun daba pe o y ki ijọba se iwuri fun awọn ọdọ lati sisẹ ọgbin, ko si tun fi awn eeyan to nimọ nipa ọrọ aje si ẹka naa.

Lakotan, eto toni tun daba pe awọn ọjọgbọn ni ẹka ọrọ aje gbọdọ gunle awọn isẹ iwadiii, ti yoo mu ki ọrọ aje orilẹede yii tun gbe pẹẹli si.