Bí ẹ kò bá san owó ìtúsílẹ̀, a kò ní tú àwọn obìnrin 53 tó wà ní àhámọ́ wa sílẹ̀ - ajínigbé ní Katsina

Oríṣun àwòrán, others
Awọn ajinigbe to ji awọn obinrin mẹtalelaadọta to sin iyawo lọ sile ọkọ ni ipinlẹ Katsina ti fi fọnran fidio sita to ṣafihan awọn ti wọn ji gbe
Ọsẹ kini oṣu keji ọdun ni awọn obinrin yi kagbako lọwọ awọn ajinigbe yi nilu Damari ni ijọba ibilẹ Sabuwa ni Katsina .
Inu ọkọ ti wọn fi gbe wọn lalẹ ni wọn wa ti awọn ajinigbepawo ti ji wọn gbe.
Awọn fijilante mẹta kan togbiyanju lati doola awọn obinrin yi lo padanu ẹmi wọn.
Lati igba naa titi di akoko yi, awọn agbofinro ko mọ pato ibi ti wọn wa titi ti wọn fi wa gbe fọnran fidio to safihan awọn obinrin naa sita
Ki lo wa ninu fidio naa?
Iṣẹju meji ati iṣẹju aaya ogun ni wọn fi ṣe fidio taa n wi yi.
Ninu rẹ, a ri agbebọn kan to wọ aṣọ to jọ tawn ologun to si gbe ibọn dani.
Wọn ṣafihan awọn obinrin to wa lẹyin wọn ti wọn wọ hijaabu ninu igbo ti wọn wa.
Ninu awọn obinrin wọnyii awọn meji kan wa ti wọn gbe ọmọ lọwọ.
Bẹẹ naa ni a ri iyawo ti wọn jigbe naa to wọ aṣọ to jọ tologun ti wọn si gbe ibọn kọ lọrun ti arakunrin kan si duro sẹgbẹ rẹ.
Ninu alaye tawọn ajinigbe yi ṣe ninu fidio naa, wọn sọ pe awakọ ọkọ ti wn wa ninu rẹ ati iyawo ni awọn gbe ibọn kọ lọrun ninu fidio naa.
''Ti eeyan kankan ba n gbọ wa ki o yaju silẹ wo wa daada''
Gbolohun akọkọ ree ti eeyan kọkọ gbọ lẹnu awọn ajinigbe yi ninu fidio naa ti wọn gbe jade lọjọ Iṣẹgun.
Ọrọ yi fi han pe awọn ajinigbe yi ko bẹru ẹnikẹni to ba gboya lati wa doola awọn obinrin naa lọwọ wọn.
Ọkan ninu awọn agbebọn yi n sọ ede Fulfude ninu fidio naa ti eeyan kan si n tu si ede Hausa.
Wọn sọ ninu fidio naa pe awọn ji obinrin mẹtalelọgọta gbe dipo mẹtalelaadọta ti ijọba kede pe wọn jigbe.
Amọ ṣa ẹni to kọkọ sọrọ ninu fidio naa sọ pe eeyan mẹtalelaadọta lawọn ji gbe ki ẹlomiran ninu wọn to pe akiyesi rẹ pe mẹtalelọgọta ni.
Wọn leri pe awọn yoo ṣeku pa iyawo naa ti wọn ko ba san owo idoola ẹmi yi.
Lẹyin igba ti wọn sọr tan , a ri ti awọn obinrin naa bẹrẹ si sunkun ti wọn si n bẹ awọn alaṣẹ lati ran awọn lọwọ.
''Ẹ ṣaanu wa, ẹ dakun ẹ san owo naa ki wọn ma baa ṣe wa baṣubaṣu''
Wọn tẹnu mọ pe wọn ko ṣe nkankan fun awọn bayii amọ ''ẹ ṣaanu wa,ẹbẹ laa n bẹ ki ẹ ṣaanu wa''
Nigba to ya ni awọn ajinigbe naa kesi dirẹba ọkọ na lati bọ siwaju wa ṣalaye tẹnu rẹ.
Oun naa sọ pe ki awọn eeyan ṣaanu awọn tori ijọba ko le gba awọn kalẹ.
O ya wa lẹnu nigba taa ri fidio yi-araalu
Awọn eeyan kan ni abule Damari ti wọn ti ji awọn obinrin yi gbe sọ fun BBC pe iyalẹnu lo jẹ fawọn lati ri fọnran fidio yi.
Iroyin to desi eti igbọ wa fihan pe niṣe lawọn eeyan joko sita niwaju ile ati ṣọọbu ti wọn si n kẹdun awọn obinrin ti wọn ri ninu fidio yi.
Amọ ṣa wọn lawọn ko le ba akọroyin wa sọrọ tori awọn alaṣẹ sọ pe awọn n gbe igbesẹ lati doola awọn obinrin wnyii lọwọ awọn ajinigbe.
Adura lawọn mọlẹbi awọn obinrin yi ti BBC kan si sọ pe awọn n mura si ki Ọlọrun gba akoso da awọn eeyan wọn pada laaafia.
Ọrọ aabo to mẹhẹ ni Naijiria ti jẹ ki ijinigbepawo gbalẹ kaakiri tibu toro Naijiria.
Nibẹrẹ ọdun yi ni iroyin gbode pe awọn ajinigbe ji awọn ọmọ obinrin mẹfa gbe ni agbegbe Bwari lolu ilu Naijiria, Abuja.
Lẹyin ti wọn lo aimọye ọjọ lakata wọn, wọn ṣeku pa ọkan ninu awọn ọmọbinrin yi ti wọn si tun gba owo itanran tawọn ọmọ Naijiria dajọ lati fi doola wọn.
Amọ ṣa ijọba sọ pe awọn n tẹsiwaju nipa ipese aabo to peye ṣugbọn awọn onimọ sọ pe igbiyanju yi ku diẹ kaato.
Ki ni ijọba sọ lori fidio naa?
Amọṣa ijọba ipinlẹ Katsina ti fesi si fidio naa, paapaajulọ ipe awọn ajinigbe naa.
Kọmiṣọna fun ọrọ abo ati abẹle ni ipinlẹ Katsina, Nasier Mu’azu ni ijọba yoo tubọ jawe sobi lori ipese abo, nipatakijulọ riri daju pe awọn obinrin to wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa gba itusilẹ.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ara ọna lati fi han ijọba pe bi o ti wu ki wọn gbogun ti awọn to, awọn ṣi ni agbara pupọ.
O ni tẹlẹ awọn agbebọn naa a maa lọ si awọn ilu nla lati kogun jawọn ti wọn a si tun ja wọn lole, ṣugbọn eyi ti rọlẹ, gẹgẹ bi o ṣe sọ.
O ni ijọba ko ni fi aye gba eyi mọ, gbogbo igbesẹ ni yoo si tubọ gbe ju ti atẹyinwa lọ lati maa da awọn agbebọn naa lẹkun.












