A fẹ́ rí òkú bàbá wa, bó jẹ́ eérú ẹ̀ la rí kó, ká sáà rí nǹkan sin - Ọmọ dẹ́rẹ́bà tí àwọn ajínigbé pa l’Ekiti sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, BBC/Others
Awọn mọlẹbi Taye Olugbaye, dẹrẹba ile ẹkọ The Apostolic Faith Apostolic Montessori School Emure Ekiti ti ni ohun ibanujẹ lo jẹ fun idile pe wọn ko ni anfani lati foju ri oku oloogbe fun eto isinku.
Olutayo Oseni, ẹgbọn oloogbe salaye pe ipaya, ibanujẹ ati ọgbẹ kikoro ni iroyin nipa iku Olugbaye jẹ fun oun ati gbogbo idile.
O ni kete ti ohun gbọ pe wọn ti yu awọn akẹkọọ ati olukọ silẹ ni oun morile aafin Ọba sugbọn ibanujẹ lo jẹ fun oin pe ko si aburo oun nibẹ.
“Gẹgẹ bii wọn se sọ, to si jẹ ohun to ba wa lẹru, pe pẹlu gbogbo nnkan tom selẹ, to si jẹ pe o jẹ ọkunrin, to ti mọ gbogbo asiri wọn ni wọn ṣe ṣekupa, ti wọn si tun dana sun pẹlu.
“Ibanujẹ ni ọrọ jẹ fun gbogbo idile wa pe o ti ẹ ni gboro aburo mi mọ.”
Oseni wa gbogbo lọwọ Ọba, Aarẹ, Gomina, Alaga ibilẹ ati awọn ẹsọ alabo fun gbogbo igbiyanju wọn lati ri pe wọn dola ẹmi awọn eeyan.
“Adupẹ lọwọ gbogbo awọn ijọ Kristẹni sugbọn o ṣeni laanu.
“Gbogbp ti Baba wọn se lo ti di eeru enikan, to jẹ iya wọn.”
Bi o jẹ eeru oku baba wa la ri , ki a sa ti ri nnkan sin nipa wọn - Ọmọ oloogbe

Ọkan lara awọn ọmọ oloogbe naa, Rufiat Olugbaye rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ekiti pe ko dakun ba awọn wa ibi ti wọn gbe oku baba awọn si ki awọn le ṣe oori fun un.
“Bi o tilẹ jẹ eeru ni wọn ri nibẹ ki a sa a ko ki a le sin wọn...bo jẹ egungun lo ku, ki wọn sa ba wa ko o.”
Rufiat ni ohun to n mumu lọkan awọn bayii ni ki baba awọn ni orori ti awọn yoo le maa tọka si lọjọ iwaju pe ibi ti wọn sin baba awọn si niyi.
Oloogbe si ni Baba laye- Akọbi Oloogbe

Akọbi Oloogbe Tosin Olugbaye ni o ṣe ni laanu pe Baba oun, fi baba silẹ laye
O ni kayefi ni iroyin naa kọkọ jẹ fun oun nigba ti oun gbọ si isẹlẹ pe wọn ko ri baba oun sugbọn wọn ri bata ati aṣọ.
Tosin, ẹni to ni ilu Ado Ekiti ni oun wa nigba o gbọ nipa iroyin naa, to si wa si Emure pẹlu iya rẹ, to jẹ iyawo oloogbe.
“Nigba ti mo de Ile Baba oloogbe naa awọn naa ni awọn ti gbọ nipa isẹlẹ naa
“Ni dede meji ooru ni eeyan kan i mo ma fi orukọ bo ni asiri, to sọ fun pe wọn ti tu awọn eeyan silẹ sugbọn wọn ko ri baba mi.
“Ero ọkan ni pe boya ibo miiran ni Baba mo wa, ti mo si n sare bọ si ilu Emure.
















