Kò tọ̀ọ́ kí ẹgbẹ́ APC máa dà aráàlú lẹ́bi ikùnà rẹ, kedere ló han- PDP àti LP fèsì

Aworan Atiku Abubakar ati Peter Obi

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/ATIKU ABUBAKAR/PETER OBI

Ẹgbẹ alatako mejeeji to lewaju lorileede Naijiria,Peoples Democratic Party,PDP ati Labour Party,LP, ti fesi pada lori ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress to wa lori oye fi kan wọn pe wọn n ru ọkan araalu lati tako ijọba Aarẹ Bola Tinubu.

Ẹgbẹ APC fẹsun yi kan wọn lẹyin tawọn araalu kan dide iwde ifẹhonuhan ni ipinlẹ Kano, Niger ati Eko lori ọwọngogo nkan lorileede Naijiria.

Felix Morka to jẹ akọwe ipolongo APC lo fi atẹjade sita nibi to ti ni awọn ẹgbẹ alatako lo wa nidi iwde naa.

Ko darukọ eyi tii ṣe ninu awọn ẹgbẹ alatako to fẹsun kan.

Amọ awọn ẹgbẹ alatako yi ti sọ pe ẹgbẹ APC lo wa lori aleefa tori naa awọn lo lẹbi bi nkan ṣe n doju ru lorileede naa kii ṣe araalu.

Awọn ẹgbẹ alatako mejeeji ọhun sọ pe iwọde naa jẹ ifẹhonu han araalu si awọn ilana eto ọrọ aje ijọba APC Tinubu to n mu inira ba araalu.

Ninu atẹjade lati ọwọ akọwe ipolongo PDP, Debo Ologunagba,ẹgbẹ PDP sọ pe iwa ihalẹ mọ araalu ti APC n hu lori fifi ẹtọ wn rinlẹ lati fẹhonu han lori ijọba ti ko bikita ipaniyan, ebi,ati awọn inira mii ṣafihan ailaanu ijọba to nifẹ si lati maa dakun iṣoro araalu.

O fikun pe : “Ilana ijọba yi dipo ki wọn tẹti gbọ araalu jẹ ohun abuku to si tun sunmọ pe wọn fẹ ti araalu kan ogiri''

Bakan naa igbakeji akọwe ipolongo PDP to ba BBC sọrọ, Malam Ibrahim Abdullai sọ pe ''awọn talaka Naijiria wa ni ipo aabo to mẹhẹ, osi ohun iṣẹ ti wọn ko si nibi ti wọn le salọ. Ti wọn o ba tun wa le sọ ẹdun ọkan wọn bi igba pe eeyan to n fi iya jẹni lo tun n s pe ki eeyan ma sunkun sita''

Gẹgẹ bo ṣe wi, gbogbo eeyan lo ri nkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria. Ẹgbẹ APC ti kuna

LP naa sọ tiẹ

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu LP, Tanko Aliyu sọ pe ''awọn ni wọn sun awọn araalu kan ogiri tori wọn ja wọn lole ti wọn si febi pa wọn. E ko jẹ ki wọn ri ile ẹkọ lọ,ẹ ni ki wọn ma lọ si oko tori aṣemaṣe tẹ ṣe si awọn araalu.''

O fi kun pe to ba ṣe pe ijọba ṣe ohun to yẹ ko ṣe ni, ko ba ma koju iru wahala to wa nilẹ yi.

''Bayii owo naira si dọla ti wọ ẹgbẹrun kan abọ, ṣe awa la ṣe eleyi fun wọn?Awọn ọmọ Naijiria si loye, ṣe o tunmọ si pe wọn ko mọ ẹtọ wọn ni?Wọn ti fi han pe awọn kuna tori ijọba Tinubu ko yatọ si ti Buhari,Igba diẹ lo ku''

Ki lawọn onwoye sọ nipa iṣẹlẹ yii?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn onwoye ọrọ oṣelu Naijiria ti BBC kan si ṣalaye pe iru ifigagbagba yi laarin awọn ẹgbẹ oloṣelu ko jẹ tuntun ni Naijiria.

Dokita Abubakar Kari to jẹ olukọni agba ni ẹka imọ oṣelu fasiti Abuja sọ pe ''aṣa to fẹsẹ rinlẹ ni pe wọn kii fẹhonu si iṣejọba awọn to ba wa lori oye ni Naijiria to si ti bẹrẹ lati igba awọn ologun.''

O fi kun pe ''Ti atako kankan ba si waye, ohun ti wọn yoo sọ ni pe awọn alatako ijọba lo wa nidi rẹ. Kii ṣe gbogbo igba lo maa n ri bẹ bo ti lẹ jẹ wi pe awọn alatako nigba mii a maa runa si wahala labẹlẹ''

Dokita Kari sọ ọpọ awọn eeyan kan n fi itara wọn han pẹlu awọn nkan to n ṣẹlẹ ni orileede yi ni.

''O yẹ ki wọn mọ wi pe wahala yi n peleke si ni.Ohun to si ku fun ijọba ni pe ki wọn wa ojutu si ọr to wa nilẹ tori diẹ diẹ ni iru rẹ maa n di wahala to pọ ti ipa ko ni ka mọ''

Lorileede Naijiria lonii, ọwọngogo nkan n mu ikunsinu wa lọdọ ọpọ araalu.

Tohun ti pe ijọba lawọn n gbiyanju lati dẹkun rẹ, awọn onimọ s pe bi wọn ko ba tete wa wọrọkọ fi ṣada, ipa ko ni ka wahala yi to ba di ranto.