Èèyàn mẹ́rin kú, ọ̀pọ̀ farapa níbi ìjà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn l’Abẹ́òkúta

Ko din ni eeyan mẹrin ti wọn ti jade laye nibi ikọlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan to waye kaakiri ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla lo fidi rẹ mulẹ, o ni ọwọ si ti tẹ awọn mọkanla lori ija ẹgbẹ okunkun naa.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, Odutọla ni awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun Aye, Ẹiyẹ ati Buccaneer ni wọn doju ija kọ ara wọn, nibi ti awọn mẹrin ti jade laye.
Odutọla ninu ọrọ sọ pe sọ pe ọkan lara awọno ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ti Ẹiyẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni Dare ni wọn kọkọ pa danu siwaju ita ile rẹ to wa ladugbo Ijẹja, Abẹokuta l’Ọjọbọ, Tọside to kọja.
O ni awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun Buccaneer ni wọn yinbọn pa Dare ti ọpọ awọn eeyan mọ si Alọba lalẹ ọjọ naa.
Bakan naa lo tun sọ pe lẹyin ni wọn tun pa ẹnikan toun naa n jẹ Ṣeun Elewode toun jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye.
- Àwọn ajínigbé palẹ̀mọ́ àwọn èrò ọkọ̀ GIG & ABC tó ń gba Kogi lọ Abuja
- Ṣé lóòtọ́ ni gbajúmọ̀ òṣèré, Lizzy Anjorin lu ìyálọ́jà ní jìbìtì pẹ̀lú àyédèrú ‘transfer’?
- 'Ńṣe ni ẹ̀jẹ̀ bo Pásítọ̀ Adegboyega lẹ́yìn tí àwọn darandaran náà gún un ní ọ̀bẹ'
- Wo àwọn oúnjẹ mẹ́rin tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kanra jẹ báyìí nítorí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun/Facebook
Agbegbe Adeun to wa nitosi Lafenwa ni Ṣeun ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra lasiko ti awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun doju ibọn kọ ara wọn.
Ibi faaji ayẹyẹ ọjọ ibi ni Odutọla sọ pe wọn ti pa Ṣeun, ẹni to ṣẹṣẹ jade kuro lẹwọn.
O ni ọmọ ẹgbẹ okunkun Buccaneer ni wọn ti kọkọ pa lagbegbe Akinolugbade, Abẹokuta.
Lasiko to n darukọ awọn ti ọwọ ti tẹ, Odutọla ni ọwọ ti tẹ Oluga Abiọla, Ọlamilekan Abiọdun, Ọlarenwaju Michael, Jimọh Okewọle, ati Wasu Tolulọpẹ.
Awọn yooku ni Abiọdun Adeyẹmi, Muiz Adeyẹmi, Adebọwale Saheed, Adebọwale Ayọọla, David Oviem ati Adebọwale Ọlayọri.















