Adájọ́ ta ẹjọ́ karùn-ún tí wọ́n pe Tani-Ọlọhun nù, ó ní kí wọ́n gbé e lọ ilé ẹjọ́ míì

Ile ẹjọ Majisireeti kan ti o kalẹ si ilu Ilọrin, olu ilu ipinlẹ Kwara ti ta ẹjọ ti wọn sẹsẹ fi kan gbajugbaja onisẹse, Abdulazeez Adegbọla ti wọn pe ni Tani Ọlọhun nu.
Bẹẹ ba gbagbe, agbẹjọro awọn ti o ti saaju pe Tani-Ọlọhun lẹjọ si ile ẹjọ mẹrin ọtọọtọ, iyẹn US Imam ati Ahmad Alfulani ni wọn pe onisẹse naa lẹjọ lọtẹ yi.
Ẹjọ onibeji ni ẹjọ naa nitori Tani-Olohun ati arabinrin kan ti o fi orilẹ ede Italy ṣe ibugbe, Osatola Abimbola, ni wọn papọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ.
Pẹlu eleyi, oti wa di ile ẹjọ marun-un ti Tani-Olohun ti yọju si fun igbẹjọ lati igba ti ẹjọ rẹ ti bẹrẹ ni Ilorin.
Adajọ ile ẹjọ ọhun, Magistrate Hafusat Alege sọ wi pe idi ti ohun ko fi lee gbọ ẹjọ naa imosinu mosikun ara oun, ko si ni nkankan se pẹlu ofin.
Adajọ naa ni ohun ti ka iwe ẹjọ naa fini fini lati ọsẹ meji ti o ti wa lori tabili ohun.
O da iwe ẹjọ naa pada si rẹjisiri nibi ti wọn ti n seto ẹjọ wi pe ki wọn gbe e lọ ile ẹjọ mii.
Olujẹjọ kini, arabinrin Osatola Abimbola ko yọju sile ẹjọ bẹẹ sini Olupẹjọ kini, Ahmad Alfulani ko yọju sile ẹjọ bakan naa.
Saaju, agbẹjọro US Imam ti o duro fun ara rẹ, fi to ile ẹjọ leti pe, lotitọ ni olujẹjọ kinni n gbe ni ilẹ okere, sugbọn wọn yoo gbe e wa ile ẹjọ ni awọn igbẹjọ yoku.
Tani-Oloun sọ fun BBC Yoruba pe oun naa ko mọ idi ti adajọ o fi fẹ gbọ ẹjọ naa sugbon ohun mọ pe nkan to n se yee.















