Ṣé lóòtọ́ ni gbajúmọ̀ òṣèré, Lizzy Anjorin lu ìyálọ́jà ní jìbìtì pẹ̀lú àyédèrú ‘transfer’?

Aworan Lizzy Anjorin

Oríṣun àwòrán, lizzyanjorin_original/screenshot

Oju opo Ayelujara n sọkutu-wọwọ lowurọ ọjọ Iṣẹgun lori ọrọ to ni ṣe pẹlu gbajugbaja oṣere tiata Yoruba nii, Lizzy Anjorin

Ko si ṣẹyin fọnran fidio kan to lu sita nibi tawọn kan ti sọ pe awọn ọlọja to n ta goolu lọja kan n ṣe fakinfa pẹlu Lizzy pe o ra goolu ko fẹ san owo.

Fọnran fidio yi taa ri loju opo ayelujara ṣafihan eeyan kan to jọ Lizzy Anjorin to si fi ibomu nose mask ṣẹnu.

A ko gbọ nkan ti wọn n sọ ninu fidio yi tori pe ohun orin ti wọn fi sabẹ fidio naa nikan lo jade sita taa n gbọ.

Amọ akọle ti o ba fidio naa n ṣalaye pe Lizzy Anjorin ni awọn ontaja n ba fa surutu lori ẹsun pe o fi ayederu alati san owo ọja goolu to ra.

Ninu fidio mii ti a ti gbọ ohun awọn eeyan to n sọrọ nibẹ, awọn eeyan n darukọ Lizzy Anjorin gẹgẹ bi ẹni to wa ninu fidio naa.

Ohun eeyan kan n beere pe ''elo ni?'' ti ẹlomiran si dahun pe ''90k''

Loore koore ninu fidio naa ni a n gbọ ti eeyan kan n sọ pe ''Lizzy Anjorin ni.Ohun ni''

A tun ri ninu akọle ti eeyan kan kọ sabẹ fidio yi wi pe ọja Akinyosoye International Market ni ilu Eko ni iṣẹlẹ yi ti waye.

Ati fido kini ati ẹlẹẹkeji la ko le fidi ọrọ mulẹ lori wọn amọ Lizzy Anjorin naa ti jade sita lati sọrọ nipa ohun to waye

Wọn fẹ we ọrọ mọ mi lẹsẹ bi ti Egbegbe - Lizzy Anjorin

Aworan fidio naa

Oríṣun àwòrán, screenshot

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iya yin ti lọ ji goolu o!

Gbolohun to gbẹnu Lizzy Anjorin ree ninu fidio to gbe si oju opo rẹ nipa iṣẹlẹ to waye yi.

Ninu fidio naa to gbe siat ni ọjọ Aje, a ri oju Lizzy Anjorin kedere to si n tẹnumọ pe ẹnikan ''Ṣẹpẹtẹri'' lo gbiyanju lati ka ẹsun si oun lọrun.

O ni ''Ṣe o ri nkan to ṣẹlẹ lonii? O wa jẹ ki n ranti bo ṣe palẹmọ Egbegbe,ọgbọn kan naa lo lo''

Ẹgbẹgbẹ ti Lizzy Anjorin n darukọ yi ni Seun Egbegbe to jẹ gbajugbaja oludari sinima ti wọn fẹsun kan ninu fidio kan pe o fẹ fi ọgbọn gbajuẹ ji foonu Iphone mẹsan ni Computer Village nigba naa lọhun.

Lizzy Anjorin sọ pe ọgbọn yi kole ṣiṣẹ nitori pe wọn sọ pe foonu ni Seun Egbegbe lọ ra ti wọn fi mu ti oun ko si lọ ra foonu.

O ni ni toun, nkan elo aṣọ riran loun lọ ra lọja nigba ti iṣẹlẹ yi fi waye.

Lizzy fi kun pe ọja ẹgbẹrun mọkanlelaadọrun Naira loun ra ti ọkọ oun si fi owo ranṣẹ si akanti ẹni to taja fun.

O sọ pe ''mo beere lọwọ arakunrin naa pe ṣe o ri owo ti wọn fi ranṣẹ o si sọ pe rara.Ni mo ba fi kuro nibẹ.Mo lọ fun nkan bi wakati meji ki n to pada sibẹ. Mo tun beere pe ṣe o ti ri owo naa to si sọ pe oun ti rii'

Lẹyin igba naa ni mo kuro nibẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ki lo fa ọrọ goolu?

Ohun taa ri gbọ ninu fidio yi ni pe ọjọ ti Lizzy ra ọja to loun san owo yat si jọ ti awọn ero pe jọ le lori pe o fẹ lu ọlọja ni jibiti.

Lizzy Anjorin sọ pe oun tun pada lọ ra awọn nkan elo iranṣọ ni ṣọọbu to wa lẹgbẹ ibi toun ti ra ọja lọjọsi ni nigba ti oun pade arakunrin toun ti fi owo ranṣẹ si akanti rẹ ṣaaju.

O ni arakunrin to ta ọja fun oun tipẹ pade oun to si ni oun ko ti san owo ọja toun ra.

Ọja to n sọ yi ni nkan elo iransọ toun ti ra lati ọdun to kọja.

Ọrọ yi ni wọn jijọ n fa to fi di pe ero pejọ si Lizzy lori ninu ṣọọbu arakunrin naa lọjọ Aje yi.

Lizzy ko darukọ oun to jọ mọ ọrọ goolu.

Alaye to ṣe ni pe awọn ẹni to ko ara wọn jọ n wa ọna lati ṣeku pa oun ni lori ẹsun ti oun ko mọ ọwọ mọsẹ rẹ.

Lizzy Anjoirin sọ pe ọkọ oun pada wa si ọja lati wa yanju ọrọ naa ṣugbọn awọn alaburu ti ṣe fidio lọpọ wakati ti wọn si n sọ pe awọn yoo doju ti Lizzy to ji ọkọ ọlọkọ.

Ohun taa ri gbọ ninu fidio naa ni pe Lizzy Anjorin n tẹnumọ pe ''Ṣẹpẹtẹri '' ati awọn eeyan rẹ lo wa nidi ọrọ ti wọn fẹ fi doju ti oun.