'Ńṣe ni ẹ̀jẹ̀ bo Pásítọ̀ Adegboyega lẹ́yìn tí àwọn darandaran náà gún un ní ọ̀bẹ'

Oríṣun àwòrán, others
Pasitọ ijọ aladani kan, ni ilu Ogbomoṣọ ni Adegboyega ki awọn afurasi darandaran kan to ṣekupa a.
Awọn afurasi darandaran naa ni a gbọ pe wọn da jẹ ẹran jẹ oko Pasitọ Adegboye lọjọ Ajẹ ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kinni ọdun yii ti oloogbe naa si kọju wọn lati ko ẹran wọn kuro ninu oko rẹ.
Iroyin fìdi rẹ mulẹ wi pe niṣe lawọn darandaran fulani naa kọju ija si pasitọ yii ti wọn si gun un lọbẹ titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

Lẹyin isẹlẹ naa lawọn araalu mu awọn afurasi darandaran mẹta ti wọn sọ pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ ọhun.
Lẹsẹkẹsẹ ni wọn si gbe wọn lọ si aafin Soun ilu Ogbomoso, Oba Ghandi Olaoye Orumogege kẹta ki Kabiyesi to ni ki wọn gbe wọn lo si ahamo ọgba awon olopaa to wa ni agbegbe Owode niluu Ogbomoso.
“Lásìkò tí Pásítọ̀ ń kìlọ̀ fáwọn darandaran tó d'ẹran jẹ oko rẹ̀ l'Ogbomoso ni wọ́n gún un lọ́bẹ pa”

Oríṣun àwòrán, bbc/other
Taiwo Jacob to jẹ ẹgbọn pasitọ Segun Adegboyega tawọn afurasi Fulani darandaran ṣeku pa loko rẹ ni agbegbe Gege to wa ni opopona Ogbomoso si ilu Iseyin ti sọ pe lasiko ti o n kilọ fawọn darandaran to da ẹran jẹ oko rẹ ni wọn gun un lọbẹ pa.
Ẹ̀gbọ́n oloogbe naa sọ fun BBC Yoruba pe "ile ẹkọ ni pasito Segun wa nigba ti Leyin ariyanjiyan to waye laarin oloogbe naa ati awọn Fulani darandaran, ọkan ninu awọn Fulani ọhun gun Pasito Adegboyega lọbẹ latẹyin kí wọn to salọ.
Okada ni a fi gbe oloogbe lọ sílè ìwòsàn kò tó gbẹmi mi.''
Lara awọn ọdọ agbegbe Gege nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ṣalaye wi pe,"Pasitọ Adegboyega ti ṣaaju akoko yii ni ariyanjiyan ranpẹ pẹlu awọn Fulani ọhun, nitori gaa wọn kò jinna si ile pasitọ Adegboyega.
“Lọjọ ti pasitọ Adegboyega ku, iyawo mi pe mi ki n maa bọ wa si ile nitori wọn ti gun pasitọ lọbẹ.
Loju ọna ni mo ti pade awọn to n gbe wọn lọ si ile iwosan, koda ọkada la lo láti gbe wọn.

O ku diẹ ka de ile iwosan ni wọn padanu ẹmi wọn, oju ẹsẹ ti a de ile iwosan awọn dokita tiraka lati doola ẹmi wọn ṣugbọn epa ko boro mọ.
Lẹsẹkẹsẹ ni a ko ara wa jọ lati wa awọn Fulani naa, wakati diẹ lẹyin ti a n wa wọn kaakiri inu igbo là bawọn pade ṣugbọn a o rí ẹni ti o ṣiṣẹ ibi naa.
rẹ pe e lati wa ba awọn darandaran to da ẹran wọn gba inu oko iṣu rẹ.
Igba akọkọ ko niyi ti pasito ti n pe akiyesi awọn darandaran naa lati mu awọn ẹran wọn gba ibomiran ti wọn ko si da pasitọ Adegboyega lohun.
Ọgbẹni Jacob ni gbogbo oko oloogbe ọhun ko ju ebe iṣu diẹ lọ yatọ si ibi ti o gbin ẹ̀fọ́ ati ewedu si lọ.



