Gbajúmọ̀ òṣèré, Olaiya Igwe tọrọ àforíjìn fún bí ó ṣe gbàdúrà ní Ìhòhò

Oríṣun àwòrán, Instagram/Olaiyaigwefilms
Gbajugbaja oṣere tiata, Ebun Oloyede ti ọpọ mọ si Olaiya Igwe ti tọrọ aforijin lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria fun bi o se lọ si eti okun lati lọ gbadura fun aṣeyọri Aarẹ Bola Tinubu ninu eto idibo Aarẹ ọdun 2023.
Ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara, eyi to ti yọ kuro bayii, Agba oṣere naa salaye pe igbesẹ ohun ko sẹyin iran ti oun tẹwọ gba lori ọrọ Tinubu.
Olaiya ni ọtitọ ni pe Tinubu se iranlọwọ fun oun paapa nipa ilera rẹ, to si jẹ idi to fi to sẹyin rẹ lasiko idibo.
“Nitori nnkan to ti se fun mi, nipa ilera mi, mo gba iran lati lọ gba adura fun ni eti okun, eyi ti mo se.
“Ọpọ lo bu mi, sepe fun mi lẹyin nnkan ti mo ṣe sugbọn ko kan mo. N ko binu si Tinubu tabi mo hu iwa ti ko da si.
“Mo mọ pe abuku yii ma waye nitori mo jẹ oṣere ti ọpọ nifẹ si pupọ nipasẹ ere ti mo n se.
“Fun awọn eeyan ti wọn lero pe mo le ṣe nnkan ti mo ṣe, to ba wọn ni jiji, ti wọn bere ki ni idi ti mo fi ṣe.
“Mo mọ pe epe ati ebu yii ma wa lati ọdọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako Tinubu nidi oṣelu.”
Ki lo sẹlẹ saaju?
Ọdun to kọja ni Olaiya Igwe fi fidio kan sori ayelujara, eyi to ṣafihan bo ṣe n gbadura fun oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Tinubu,ẹni to ti di Aarẹ Naijiria bayii ni eti okun lai wọ aṣọ.
Ninu fidio naa to pada fa awuyewuye lori ayelujara, ni Olaiya ti n kawọ adura soke pe Tinubu ni yoo jawe olubori gẹgẹ bi aarẹ Naijiria lọdun 2023.
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo si n bu u pe iwa itiju ati ẹlẹya ni Ọgbẹni Ebun Oloyede hu, nitori bo ṣe gbe fidio ara rẹ jade nitori oloṣelu.
Ṣaaju ni Oloyede ti pada ṣalaye pe oun gbe igbesẹ lati gbadura fun Tinubu, nitori pe oloore oun lo jẹ.
O ni iyawo rẹ, Oluremi Tinubu, doola ẹmi oun nigba kan ti oun dubulẹ aisan, to si sanwo itju oun nile iwosan.
Sugbọn ninu ifọrọwanilẹnu wo kan to ṣe lori amohunmaworan TVC lowurọ ọjọ Aje, Ebun Oloyede sọ pe oun gbọ́ ohùn kan ninu ẹmi, pe ki oun ṣe eto adura naa.















