‘Àwọn ajínigbé gba owó lọ́wọ́ wa kí wọ́n tó tú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀’

Oríṣun àwòrán, BBC/Others
Olori ile ẹkọ Apostolic Faith Apostolic Montessori School Emure Ekiti, Adesanya Gabriel ni otitọ nipe awọn ajinigbe gba owo itusilẹ lọwọ mọlẹbi ati ile ẹkọ ki wọn to tu awọn akẹkọọ ati olukọ silẹ.
Bee ba gbagbe, ọjọ Aiku, ọjọ kẹrin oṣu keji ọdun 2024 ni iroyin tẹwa lọwọ pe ọmọ ileẹkọ naa moribọ kuro ni akata awọn ajinigbe ni deede ago meji oru.
Ọkan lara awọn molebi ọmọ ti wọn jigbe ati osise ọgba ile iwe naa fidi rẹ mulẹ fun akoroyin wa.
Awọn ti wọn jigbe yii, akẹkọọ marun un, olukọ obinrin meji ati awakọ ni wọn ko si ọwọ awọn ajinigbe nigba ti wọn n dari si ile ẹkọ pada nirọlẹ ọjọ Aje to kọja.
Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ, Adesanya salaye pe ko si ẹnikẹni to fẹ ki awọn akẹkọọ ati olukọ ku si akata awọn ajinigbe lo fa ti wọn fi san owo itusilẹ naa
“Ohun se ni laanu ni pe dirẹba wa padanu ẹmi rẹ si ibugbe awọn ajinigbe yii.
“Bawo ni ko ba se buru to ka ni awọn ọmọ ile ẹkọ ati awọn olukọ naa ni awọn ajinigbe yii sekupa.
“Gbogbo awọn olufẹ ohun rere lo parapọ lati ri pe wọn gba itusilẹ awọn ọmọ ile ẹkọ lọdọ awọn ajinigbe.”
Adesanya ni oun ko le sọ iye owo ti ilu, awọn obi ati ile ẹkọ san lasiko ti isẹlẹ naa waye nitori oun ko tẹlẹ wọn lasiko ti wọn gbe owo itusilẹ lọ.
“Adupẹ lọwọ gbogbo ilu, adupẹ lọwọ gbogbo afẹnifẹre ni wọn parapọ lati gba itusilẹ fun awọn ile ẹkọ wa.”
Nǹkan to wa nilẹ ni a ko fun awọn ajinigbe- Oba Adebowale Adebayo
Bakan naa, Elemure ti ilu Emure Ekiti, Ọba Adebowale Adebayo fidi ọrọ naa mulẹ pe ilu ati ile ẹkọ lo parapọ lati gbe owo silẹ lati gba itusilẹ awọn akẹkọọ naa.
Ọba Adebayo dupẹ lọwọ awọn agbofinro fun igbyanju wọn lati ri pe awọn ri pe awọn ile ẹkọ yii gba itusilẹ lọwọ ajinigbe.
“Nnkan to wa ni ilẹ ni a gbe fun wọn sugbọn gbogbo ohun ti gbogbo wa ni lapapọ gbe fun wọn nitori pe ọkan ajinigbe yii le pupọ.
“Ijọba ni a yoo rọ lati wa nnkan se si bi eto abo se mẹyẹ.
“Ko ki n ṣe pe o jẹ nnkan to ju gbara ijọba lọ, ati pe a mọ pe ijọba o dakẹ lori ọrọ eto abo ati ijinigbe to wọ pọ.”
Ọba Adebayo wa tun rọ awọn araalu lati kun ijọba lọwọ ninu igbiyanju lati gbe ogun ti eto abo ati ijinigbe to wọ pọ kaakiri.
Bakan naa ni Ọba tun fi ọkan awọn araalu balẹ pe ilu Emure ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati ri pe irufẹ isẹlẹ yii ko waye mọ.















