EFCC ti gbé Olùdásílẹ̀ ìjọ, wọ́n ní o lu ọmọ ìjọ ní jìbìtì

Aworan asia EFCC

Oríṣun àwòrán, Asia EFCC/Facebook

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ Pasitọ kan, Apostle Theophilus Oloche Ebonyi lori ẹsun lilu awọn ọmọ ijọ rẹ ni jibiti owo.

Owo ti ko din ni ogun biliọnu owo dọla la gbọ pe Ebonyi fi lu awọn ọmọ ijọ rẹ ni jibiti.

Ebonyi ni olori ati olusailẹ ijọ Faith On The Rock Ministry International.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ajọ kan ti wọn pe ni Ford Foundation ni wọn sọ pe Ebonyi fi gba owo lọwọ awọn ọmọ ijọ rẹ, pẹlu ẹtanjẹ wi pe oun fẹẹ fi ṣe iranwọ fawọn to ku diẹ kaato fun.

Apapọ owo ọhun lo le diẹ ni tiriliọnu mẹta naira, N1,319,040,274.31.

Ninu atẹjade ti ajọ EFCC gbe jade, wọn ni Ebonyi tan awọn ọmọ ijọ rẹ lati kopa ninu eto ti ajọ naa gbe kalẹ, lati le mu wọn kuro ninu iṣẹ ati oṣi.

EFCC ni miliọnu meji naira din diẹ, N1,800,000 ni ọmọ ijọ kọọkan san, ti ko si sẹni to ri abọ owo ti wọn san.

Wọn ni igba ti ko sẹni to gburo nipa owo wọn, lo jẹ ki wọn kọ iwe ẹsun si ajọ EFCC.

Ninu iwadii ti ajọ EFCC ṣe ni aṣiri ti tu pe Ebonyi ko ni ajọṣepọ kankan pẹlu ajọ Ford Foundation, o kan fẹẹ tabuku ba orikọ wọn ni.

EFCC sọ pe awọn ti ṣawari awọn ile nla marun-un ti fi owo jibiti naa ra kaakiri.

Ju gbogbo rẹ lọ, ajọ EFCC sọ pe awọn yoo foju Ebonyi ba ile-ẹjọ laipẹ, iyẹn lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.