Ìjọba Nàìjíríà gbé ìgbìmọ̀ kalẹ̀ lórí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ àti Ebi ọ̀pàgbà fọwọ́ mẹ́kẹ́ tó ń pa aráàlú

Aworan afihan agbalagba to n ke gbajare

Ariwo ebi n pa araalu, nnkan wọn lọja ti awọn eeyan kan kigbe nibi iwọde ifẹhonuhan to waye ni ilu Minna laipẹ yi jẹ nkan to kan ijọba lominu.

Wọnyii ni ọrọ to jade lẹnu Minisita feto iroyin ati idanilẹkọ ni Naijiria, Muhammed Idris nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Abuja.

O fi ọrọ yi lede lẹyin ipade igbimọ pataki kan to sọ pe aarẹ gbe kalẹ lati jiroro lori ọna abayọ ebi ati ọwọngogo ounjẹ to gbode.

Idris sọ fun awọn akọroyin pe awọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ipade yi ni (lọjọ Iṣẹgun)ti yoo si waye lỌjọru ati Ọjọbọ.

O ṣalaye pe ọrọ aisi ounjẹ fun ọpọ ọmọ Naijiria ati ọwọngogo ounjẹ lọja jẹ nkan to fọwọ kan ijọba to wa lori aleefa lẹmi.

''O mumu laya ijọba nkan tawọn ọmọ Naijiria n farada ni paapa iṣẹlẹ to waye ni Minna lana tori naa ijọba n wa ọna lati mu idẹkun ba awọn ọmọ Naijiria nipa ipese ounjẹ''

Aworan igbimọ ti aarẹ gbe kalẹ lori ọrọ ounjẹ

Oríṣun àwòrán, others

Awọn igbeṣẹ to ni igbimọ yoo gbe

Aworan ọja

Minisita iroyin,olori oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ to fi mọ Gomina banki apapọ Naijiria wa lara awọn ọmọ igbimọ yi.

Ninu alaye ọna ti igbimọ yoo ṣe gbe ọrọ yi gba Minisita Muhammed Idris sọ pe lara ohun tawọn yoo ṣe ni pinpin awọn ounjẹ ti ijọba ni ni ipamọ jakejado orileede Naijiria.

O ni ounjẹ wọnyi to wa labẹ akoso ileeṣẹ ọgbin lawọn yoo pese fun awọn araalu gẹgẹ bi ọna abayọ.

Ninu alaye rẹ bakan naa o sọ pe awọn yoo kan si awọn to n peloo ounjẹ ati awọn to n ta ounjẹ lọpọ lati mọ dedee nkan to wa ni ikawọ wọn.

O ni awọn yoo ṣe bi wọn yoo ṣe ṣi ounjẹ silẹ faraalu ti ijọba yoo si pese iranwọ lati le jẹ ki ounjẹ yi de arọwọto araalu.

O ni ohun tawọn woye ni pe ounjẹ ṣi wa ni Naijiria lọpọ yanturu amọ awọn araalu kọọkan lo n gbe owo lori iye wọn tori bi nkan ṣe wọn ati idẹnukọlẹ to ba owo Naira.

Ẹ ṣe suuru pẹlu ijọba-Minisita parọwa

Ọrọ aisi ounjẹ ati ọwọngogo ounjẹ jẹ nkan ti ọpọ ti n woye pe ijọba ko gbọdọ kawọ gbera lori rẹ mọ.

Ṣaṣa ni nkan ti iye owo rẹ ko lọ soke ni Naijiria nilẹ toni to mọ ṣugbọn ti ounjẹ to yẹ ko tun jẹ idẹkun faraalu kọja afẹnusọ.

Minisita ko sọ pato igba ti awọn ilana yi yoo bẹrẹ si ni di imuṣẹ fun awọn araalu amọ o sọ pe ijọba to wa lori aleefa nilo ifgarajin awọn araalu.

''Nigba taa ba fi pari awọn ipade wọnyii, a o lanfaani lati gbe ọrọ jade ni pato iru igbesẹ ti yoo kan lori ọrọ to wa nilẹ yii.Ohun ti mo kan le sọ ni pe ijiroro n tẹsiwaju ati pe laipẹ ọna abayọ ko ni pẹ mọ''