Ẹ fi ìdájọ́ ikú lélẹ̀ fún àwọn ajínigbé - Wòlíì Ayodele rọ Ìjọba àpapọ̀

Aworan Primate Ayodele

Oríṣun àwòrán, Instagram/primateayodele

Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti rọ Aarẹ Bọla Tinubu lati fi idajọ iku lelẹ fun gbogbo awọn tọwọ ba tẹ lori iwa ijinigbe lorileede Naijiria.

Loni, ọjọ Aiku, Sannde ni Wolii Ayọdele sọrọ naa jade ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Oluwatosin Ọṣhọ gbe jade.

Wolii Ayọdele ni bi Aarẹ Tinubu ba kọ lati tete gbe igbesẹ akikanju lori idajọ to tọ sawọn ajinigbe, a jẹ pe ki ileeṣẹ aarẹ atawọn alẹnulọrọ nijọba maa gbaradi lati gbalejo awọn ajinigbe

Ninu atẹjade naa, Ayọdele tun sọ pe bi ijọba ba fẹẹ mu opin ba iwa ijinigbe to n ṣẹlẹ lojoojumọ, niṣe lo yẹ ki idajọ iku maa ba awọn ti ọwọ ba tẹ loju ẹsẹ ni.

O ni awọn ajinigbe, agbebọn ni lati maa gba idajọ oju ẹsẹ bi ijọba ba fẹ ki adinku ba iwa ọdaran lorileede yii.

“Bi ijọba ba fẹẹ ki opin de ba iwa ijinigbe ati aisi eto aabo ni tootọ, idajọ iku lo yẹ ko tọ si awọn ajinigbe ati agbebọn lorileede yii.

“O yẹ ki wọn maa pa awọn ti wọn ba ba nidi iwa buruku yii ni. Wọn nilo idajọ oju ẹsẹ bi a ba fẹ ko dinku.

“Bi ijọba ba ṣi n fi ọwọ ra wọn lori, eto aabo yoo tubọ maa mẹhẹ siwaju sii ni, mo si ni rii wi pe wọn ti fẹ maa ji awọn alẹnulọrọ ninu ijọba gbe bayii.

“Ko si eto aabo fun ileeṣẹ aarẹ mọ. Mo n rii wi pe awọn ajinigbe fẹẹ ya bo ileeṣẹ aarẹ lati ṣiṣẹ buruku wọn.

“Eto to mẹhẹ yoo tubọ maa buru sii lojoojumọ ni, ayafi bi ijọba ba gbe idajọ iku kalẹ fun iwa yii, ohun to si le jẹ dopin niyẹn.”