"Ìjọba àpapọ̀ ní gbèdéke ọjọ́ 14 láti yanjú àdéhùn tó wà láàrin wa, áìjẹ́ bẹ́ẹ̀..."

Aworan NLC ati TLC

Oríṣun àwòrán, Others

Adari ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorilẹ ede Naijiria, NLC ati TUC ti fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati yanju adehun to wa laarin wọn bẹrẹ lati ọla, ìyẹn ọjọ kẹsan an osu Keji ti a wa yii.

Awọn ẹgbẹ osisẹ mejeejin ni ti ijọba ba kuna lati se ohun to tọ laarin gbedeke yii, awọn yoo gunle iyansẹlodi alailọjọ.

Ninu atẹjade kan ti aarẹ ẹgbẹ mejeejì naa gbe jade, Comrade Joe Ajaero(NLC) ati Comrade Festus Osifo(TUC) salaye pe ijọba kọ lati mu adehun mẹrindinlogun to ba awọn ẹgbẹ osisẹ naa se ní ọjọ kejí oṣu kẹwaa, ọdun 2023.

Ẹgbẹ osìsẹ NLC ati TUC tun tẹsiwaju pe, pẹlu gbogbo ìgbìyanju adari ẹgbẹ awọn oṣìṣẹ lati jẹ ki ifọwọsowọpọ ati alaafía wa laarin ijọba ati oṣìṣẹ níle iṣẹ, sibẹ se ni ìjọba apapọ fi aake kọri lati túbọ maa fi ara ni awọn oṣìṣẹ ati araalu.

“Ebi n pa awon oṣiṣẹ ati araalu, owo ti awọn oṣìṣẹ n gba ko ka nkankan mọ lọja, owo epo n fi ojoojumọ gbowo lorí, eto alaafia ti di afisẹyìn ti eegun n fi aṣọ.

Ibẹru-bojo wa gbode kan, bẹẹni ìjọba kọ lati se awọn ohun ti yoo mu inira yii kuro, ọrọ wa ti di kaka ko san lara ìya ajẹ, se lo n fi gbogbo ọmọ rẹ bí obìnrín.

Lara awọn adehun ti ìjọba bawọn ẹgbẹ osìsẹ se ni:

Lati maa fun awọn oṣìṣẹ ni ẹgbẹrunmẹẹdọgbọn(Thirty five thousand naira) fún oṣìṣẹ kọọkan, gẹgẹ bí alekun owo oṣu fun oṣu mẹfa.

Lati se adinku sí awọn owo ti awọn araalu n san lorí ohun amayedẹrun.

Lati yanju wahala to wa laarin ẹgbẹ awọn oṣìṣẹ awakọ ti ìpínlẹ Eko ati ìjọba ìpínlẹ Eko.