Igbákejì akọ̀wé KWASU ṣubú lulẹ̀ lásìkò tó ń wo bọ́ọ̀lù Super Eagles, ó sì gbabẹ̀ dèrò ọ̀run

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Lalẹ ana ni igbakeji Alakoso ẹka eto ipawo wọle ni ile ẹkọ giga fasti ijọba ipinlẹ Kwara ọgbẹni Abdullahi Ayuba sa dede subululẹ to si ku.

Iṣẹlẹ yii lo waye lalẹ ana lagbegbe Sango ni ijọba ibilẹ ila orun ilọrin, ni ilu ilọrin olu ilu ipinlẹ Kwara.

Akọroyin ile isẹ BBC Yoruba ri gbọ pe ọgbẹni Abdullahi Ayuba n wo bọọlu to waye lalẹ ana larin ikọ agbabọlu Super eagle ati Bafana Bafana ti ilẹ south African ni ọlọjọ de.

Ologbe na lagbọ wipe o sọ fawọn ti wọn jọ wo bọọlu pe oru n mu oun lati inu wa, oun fẹ pada lọ si ile lati lọ sinmi lai mọ pe ifunpa rẹ ti ga.

Akọroyin wa fi idi ẹ mu lẹ pe bo se dele lo ṣubu lulẹ ti wọn si gbe lọ ile iwosan aladani kan lagbe gbe Sango ni ilu Ilọrin ti wọn si ni ki wọn ma gbe lọ si ile iwosan nla (UITH) Ilọrin ni ibi to ti jade laye.

Lasiko ti akọroyin ile isẹ wa nfi ọrọ wa ọkan lara awọn osisẹ ile ẹkọ na lẹnu wo, Ọjọgbọn Dayọ Olorisade ṣalaye pe iku oloogbe naa bawọn lo Jiji.

O salaye siwaju pe oun gbọ pe iṣẹlẹ na sẹlẹ lalẹ ana, lẹyin to dari de ni ibi toti lọ wo bọọlu.

Wọn ti sin oku ologbe naa ni ilana ti Musulumi.

Atẹjade adari agba lẹka eto iroyin ni ile ẹkọ giga KWASU) Dr Saedat Aliyu fi diẹ mulẹ pe lotọ ni Ọgbẹni Ayuba jade laye.

Pẹlu alaye pe eto isinku ti waye larọ oni ni itẹ munsulumi lagbegbe Apata yakuba ni ilu Ilorin.

Adari agba na fi kun pe awọn o ti mọ ohun to ṣokunfa iku ologbe na.

Ọkan lara awọn eyan adugbo oloogbe na to ba akọroyin wa sọrọ Ọgbẹni Arikewusọla Abeeb sọ pe iṣẹlẹ na sẹlẹ lalẹ ana lasiko ton wo bọlu, o pẹlu afikun pe boya oloogbe na ti ni aisan kan lara ni tẹlẹ,

O wa gba ladura ki Ọlọhun fi si alujanna oni idẹra.