Wo bí àlékún ṣe bá iye owó àwọn nǹkan lẹ́nu ìgbà tí Ààrẹ Tinubu dé orí ipò

Aworan Tinubu ati ọja kan

Oríṣun àwòrán, Tinubu/facebook/others

Ni Naijiria lonii awọnk araalu n kojuipenija ọwọngogo nkan lọja.

Lati igba ti aarẹ Bola Ahmed Tinubu si ti de ori oye lati nnkan bi oṣu mẹjọ sẹyin ni ipenija yi ti n ba wọn finra.

O buru debi pe awọn eeyan kan ṣe iwọde lawọn ipinlẹ kọọ́kan lati fẹhonu han.

Minna ni ipinlẹ Niger wa lara wọn ti awọn araalu si ke gbajare lori bi ara ṣe n ni wọn.

Ọkan ninu wọn to ba BBC sọrọ sọ pe: ''A ko ri idaji nkan taa n jẹ tẹlẹ jẹ nisinyi tori pe wọn gbowo lori.Awọn ọkunrin n sa fi ẹbi wọn silẹ ti igbeyawo si n tuka tori ọrọ airi bukata ounjẹ gbọ''

Araalu dibo fun aarẹ Tinubu pẹlu igbagbọ pe yoo tan iṣoro inira ti wọn ri labẹ ijọba aarẹ tẹlẹ Muhammadu Buhari .

Ọpọ lo fọkan tan tori pe o ṣe akoso ipinlẹ Eko to si mu idagbasoke ba ipinlẹ naa.

Amọ lẹyin ọpọ oṣu to de ori aleefa tan, niṣe ninu araalu n bajẹ pe kaka ki nkan yatọ niṣe lo n buru si.

Ajọ National Bureau of Statistics to n risi akọsilẹ ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria nipa iye owo nkan sọ pe oṣu kini ọdun yi lawọn ri alekun iye owo ọja to buru julọ lorileede Naijiria lati nkan bi ọdun mẹtadinlọgbọn sẹyin.

Ajọ naa sọ pe alekun iye owo ọja to waye ni oṣu Kejila jẹ ida 28.92% to ṣafihan pe leralera ni nkan n wọn si loṣooṣu.

Nkan mii top tun n kan araalu lominu ni ainimọ nipa igba ti nkan yoo walẹ pada.

BBC ṣe afiwe iye owo awọn ọja kan nigba ti ijọba Tinubu gun ori aleefa si asiko taa wa yii:

Nkan ounjẹ

Ọja tomato kan

Oríṣun àwòrán, others

Irẹsi jẹ ọkan lara awọn nkan jijẹ tawọ araalu sọ pe iye owo rẹ lọ soke gidi gaan.

Eyi si n waye tohun ti gbogbo igbiyanju ijọba aarẹ tẹlẹ to ni awọn fagbara fun awọn agbẹ onirẹsi.

A kan si alaga awọn ọlọja ipinlẹ Kano Alhaji Muntakka Isa ati Alhaji Musa Nabanki to jẹ olori awọn ọlọja Kano State Amalgamated Association of Traders (AMATA) ati Bashir Sule Dantsoho alaga awọn ọlọja nkan ọsin ti gbogbo wọn si jẹri si wi pe iye owo nkan ti gọbọi lọja.

Suga Ike ọda

lye owo rẹ tẹlẹ: #2,300

Iye rẹ nisinyi: #5,200 - #5,300

Ẹran Kilo Kan

lye owo rẹ tẹlẹ: #2800- #3000

Iye rẹ nisinyi: #3800- #4200

Owo ọkọ

Opopna kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹka irinna jẹ ọkan lara awọn ti ọwọngogo yi kan.

Ko si sẹyin bi ijọba ti y ẹkunwo lori owo bẹntiroo.

Gẹgẹ bi Mallam Lawwali Dan Ada to jẹ ọkan lara awọn olori ẹgbẹ awakọ ni Jabi ni ilu Abuja ṣe sọ, saaju ki wọn to yọ ẹkunwo ọtọ ni iye owo ọkọ amọ bayii nkan ti yatọ.

Abuja si Sokoto lekun lati #8,000- #16,000.

Abuja si Kano lekun lati #5,000 - #10,000

Abuja si Kaduna lekun lati #3,000 - # 5,500

Abuja si Katsina lekun lati #6,000 - #10,000.

Gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye wiwọ awọn ọkọ ijọba yi dẹrun diẹ ṣugbọn wọn ko to awọn ọkọ aladani to n gbero .

Awọn iye owo ọkọ lawọn ibo mii lati Abuja ree:

Abuja si Maiduguri lekun lati #6,500 - #10,000 lawọn ọkọ ijọba

Abuja si Taraba lekun lati #13,000 - #22,000 ninu ọkọ ijọba.

Abuja si Adamawa lekun lati #12,000 - #19,500 ninu ọkọ ijọba.

Bẹntiroo

Aworan awọn eeyan kan to n rọ epo bẹntiro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọjọ Kọkandinlọgbọn ti wọn burawọle fun Aarẹ Tinubu lo tikede pe ko si ni ẹdinwo mọ ninu owo bẹntiroo.

Saaju ikede yi Naira mẹtadinlọgọrun un ni wọn n ta ajala bẹntiroo kan ni Abuja.

Ni Kano ati awọn ipinlẹ mi loke ọya, igba le mẹwaa Naira ni wọn n ta.

Ni Eko, mejidinlọgọjọ Naira ni lita kan.

Bẹẹ lo sunmọ lawọn ipinlẹ ilẹ Yoruba mii.

Kete ti aarẹ Tinubu kede yiyọ ẹkunwo bẹntiroo, Bashir Dan Mallam to jẹ alaga awọn to n ta epo ati gaasi ni apa araiwa Naijiria sọ pe owo lita kan di 450-520 jakejado Naijiria.

Lati oṣu Keje ọdun to kọja titi di isinyi lawọn ipinlẹ ariwa ati ila oorun Guusu Naijiria jala bẹntiroo kan a maa lọ fun nkan bi N710.

Ni ipinlẹkan si omiran iye owo bẹntiroo ko kere ju 620-670 lowo to kere julọ ati 700-710 lawọn ibi to ti lọ soke.

Simẹnti

Aworan ṣọbu simẹnti kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nilẹ oni to mọ yi, Mohammed Jamiu Awwal to ba BBC sọrọ ni ilu Ilorin sọ pe iye owo simẹnti apo kan ti lọ soke di 8000-8500. Saaju asiko yi owo simẹnti ko ju nkan bi 4,200 si 4500.

Koda ọkan ninu awọn ileeṣẹ to n pese simẹnti loun yoo mu adinku ba iye owo simẹnti walẹ si 3,500.

Amọ titi di asiko yi kaka ki owo simẹnti wa silẹ bi wọn ṣe ṣadehun, niṣe lo n ga si ju ti tẹlẹ lọ.

Kini ijọba n sọ lori ọwọngogo ọja yii?

Loore koore ni ijọba n tẹnumọ pe awọn ko sinmi lati ri pe iye owo ja walẹ ni Naijiria .

Laipẹ yi ni Gomina Banki apapọ Naijiria Olayemi Cardoso s niwaju ile aṣojuṣofin pe banki apapọ n gbe igbesẹ lati ri wi pe wọn jẹ ki nkan bọ sipo pada.

Amọ ko daju pe eleyi le ṣẹlẹ lopin igba to ṣe pe iye nkan ti Naijiria n ko wọle lati ilẹ okere [pọju eleyi ti wọn n pese labẹle lọ.

Lọkan araalu igbagbọ diẹ lo ku bayii tori pe gbogbo ileri ijọba lati mu ki nkan dẹ ko di imuṣẹ.