Èèkàn ẹgbẹ́ APC jáde láyé níbi tó ti ń wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Nàìjíríà àti South Africa ní Afcon, Tinubu kẹ́dùn

Oríṣun àwòrán, Ọ̀mọ̀wé Ojougboh/Google
Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu kẹdun iku Ọmọwe Cairo Ojuogboh, ọkan lara awọn alẹnulọrọ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Cngress, APC to jade laye.
Lasiko t Ojuogboh n wo ifẹsẹwọnsẹ to waye laarin ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti orileede Naijiria ati Bafana-Bafana ti orileede South Africa la gbọ wi pe ọlọjọ de ba a.
Ọmọwe Ojuogboh ti figba kan ri jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin kekere orileede to ṣoju ẹkun Ika nipinlẹ Delta ki o to jade laye lalẹ Ọjọru.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni bi wọn ṣe fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu South Africa ni anfaani lati gba pẹnariti ni Ojougboh ṣubu lulẹ, to si gbabẹ dakẹ.
Wọn ni ẹru to ba agba oloṣelu naa, lo fa a to fi ṣubu lulẹ ni iṣẹju mejidinlaadọrun ninu ifẹsẹwọnsẹ ipele to kangun si aṣekagba ni idije AFCON to n lọwọ.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Aarẹ, Ajuri Ngelale, Tinubu ba idile oloogbe naa ati ijọba ipinlẹ Delta kẹdun.
Tinubu sọ pe ẹdun ọkan ni alakoso agba ileeṣẹ to n ri sọrọ Niger Delta, Niger Delta Development Commission (NDDC) jẹ foun, nitori pe ojiji lo ba oun.
Nigba to n gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere, Tinubu rọ awọn mọlẹ lati mu ara wọn le, pẹlu igbagbọ pe Ọlọrun yoo tu wọn ninu.
Oloogbe naa ni Akinuwa tiluu Agbor to wa nijọba ibilẹ Ika, ipinlẹ Delta.














