Èèyàn mẹ́ta lọwọ́ ti tẹ̀ lórí ìbúgbàmù tó wáyé ní Ibadan - Ìjọba Oyo

Aworan

Oríṣun àwòrán, JAMES IGBASAN/BBC

Ijọba ipinlẹ Oyo ti kede sita pe ọwọ ti tẹ afurasi mẹta to lọwọ ninu isẹlẹ ibugbamu to waye ni Bodija nibi ti ọpọ eeyan ti padanu ẹmi wọn.

Oludamọran si Gomina lori ọrọ eto abo, Fatia Owoseni lo kede ọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Ibadan.

Owoseni ni eeyan mẹta ni iwadi ti fihan pe wọn lọwọ ninu ibugbamu naa, ti wọn yoo si foju ba ileẹjọ lori iwadi ti awọn agbofinro se.

O tẹsiwaju pe agbegbe Aderinola ni ibugbamu naa ti waye ki i se agbegbe Dejo Oyelese.

Bakan naa lo safihan orukọ nnkan to bugbamu naa, eyi to pe ni ‘Water Gel Type Based Explosive’ to si jẹ pe ina mọnamọna lo ma sokunfa ibugbamu naa.

O ni ẹrọ aworan CCTV to jẹ ti ọkan lara Ile ti ibugbamu naa kọlu lo tu asiri bi isẹlẹ naa se waye.

“A ni anfani to se iwadi ibugbamu yii ni kiakia, ti awọn agbofinro si lọ kaakiri lati se iwadi to tọ ni agbegbe naa.

“Ẹka EOC ti gba ọpọ ẹri lori ohun to sẹlẹ, ti iye dukia to ba lasiko ibugbamu naa.

“Ni dede ago mẹfa, Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹta oṣu keji, to jẹ ọjọ kejidinlogun ti isẹlẹ naa waye, iye eeyan ti ibugbamu naa kọlu lo 335, ti wọn si ti forukọ, silẹ ni ẹka pajawiri pẹlu ileeṣẹ mẹrindinlogun, ile ijọsin, Mọsalasi ati Ile iwosan UCH si ti wa forukọ silẹ fun awọn ohun ti wọn padanu.”

Ki lo sẹlẹ saaju?

Iṣẹlẹ ibugbamu kan ti waye ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kinni ni agbegbe Adeyi Bodija ilu Ibadan.

Gẹgẹ bi awọn kan to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣe sọ iro ibugbamu naa rinlẹ de awon agbegbe kaakiri ilu Ibadan ni nnkan bii agogo mẹjọ alẹ to waye.

Ṣe ni igboro daru ti ipaya si ba ọpọlọpọ awọn olugbe ibadan ni kete ti iro ibugbamu naa waye eyi to mi ọpọlọpọ agbegbe ilu nla naa lalẹ ọjọ Iṣẹgun

Lara awọn agbegbe ti irọkẹkẹ ibugbamu naa de ni Bodija, Agbowo, Ẹlẹyẹle, Orogun, ati General Gas .

Bakan naa lawon eeyan to wa lagbegbe bii Iwo road, Gate, Bẹrẹ Mokola ati bẹẹbẹ lọ pẹlu ni awọn pẹlu gbọ jinijini irọkẹkẹ ibugbamu ọhun.

Awọn fidio ati aworan to n jẹyọ lori ayelujara n se afihan awọn oku ti wọn gbe kuro lagbegbe naa .