Ó ṣeéṣe kí ìjọba tó bá fi owó ará ìlú rán àwọn èèyàn ní Hajj ó gbèpè dípò àdúrà - Alfa Akewugbagold

Oríṣun àwòrán, Sheikh Taofeeq Akewugbagold/FACEBOOK
Òpó tó kẹ́yìn nínú òpó márùn-ún tó gbé ẹ̀sìn Islam ró ni lílọ sí Saudi Arabia láti lọ ṣe iṣẹ́ Hajj jẹ́.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Islam ṣe gbe kalẹ̀, ẹni tó bá lówó lọ́wọ́, tó sì ní agbára àti okun láti lọ ni iṣẹ́ Hajj pọn dandan fún àmọ́ ó gbọ́dọ̀ wà nínú ọkàn Mùsùlùmí pé òun fẹ́ ṣe Hajj láyé.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Mùsùlùmí ló máa ń tiraka láti ri pé àwọn ṣe iṣẹ́ Hajj kí wọ́n tó jáde láyé gẹ́gẹ́ bí ìlànà ẹ̀sìn Islam ṣe gbe kalẹ̀.
Ìgbàgbọ́ ni pé ẹni tó bá ṣe iṣẹ́ Hajj ní àǹfàní tó pọ̀ tó máa jẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó bá ti ṣẹ̀ ṣáájú àkókò yìí máa jẹ́ píparẹ́.
Owó gọbọi ni àwọn èèyàn máa ń ná ní ọdọọdún láti ṣe iṣẹ́ Hajj tí àwọn èèyàn sì máa ń kọminú lórí bí owó Hajj ṣe máa ń wọn ní ọdọọdún.
Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹta oṣù Kejì ọdún 2024 ni àjọ tó ń mójútó ètò Hajj ní Nàìjíríà, NAHCON kéde pé owó tí àwọn ènìyàn máa nílò láti ṣe Hajj ọdún yìí wà láàárín ₦4,679,000 sí ₦4,890,000.
Àtẹ̀jáde tí Agbẹnusọ NAHCON, Fatima Sanda Sára fi léde ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kejìlá oṣù Kejì ni gbèdéke tí wọ́n fún àwọn ènìyàn láti fi san owó Hajj yìí kí àjọ náà lè rí iṣẹ́ rẹ̀ ṣe pẹ̀lú ìjọba Saudi Arabia kí gbèdéke ọjọ́ tí wọ́n fún àwọn náà tó pé.
Ṣáájú ni àwọn ènìyàn ti rò pé owó Hajj ọdún 2024 kò ní ju ₦4.5m lọ gẹ́gẹ́ bí alága NAHCON, Malam Jalal Ahmad Arabi ṣe ti sọ àmọ́ tí ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ bí owó dọ́là ṣe ti gbẹ́nu sókè sí owó náírà.
Malam Arabi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni àwọn gé kù tí owó Hajj náà fi já wálẹ̀ sí iye tó jẹ́ báyìí pé owó náà kò bá wọ mílíọ̀nù mẹ́fà náírà.
Èyí ló ti ń fa ọ̀pọ̀ awuyewuye láàárín àwọn ènìyàn pé ṣé àwọn èèyàn máa lè lọ Hajj ní ọdún yìí pẹ̀lú bí owó rẹ̀ ṣe gbé ẹnu sókè yìí.
Kò sí bó ṣe lè wù kí Hajj wọ́n tó, àwọn èèyàn máa lọ

Oríṣun àwòrán, @NIGERIAJJCOM
Nígbà tó ń bá BBC News Yoruba sọ̀rọ̀, gbajúmọ̀ Alfa oní wáàsí, Sheikh Taofeek Akewugbagold kan sáárá sí àjọ NAHCON fún ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé láti ri pé owó Hajj kò ju iye tí wọ́n fi sí náà lọ.
Akewugbagold ní ọ̀pọ̀ ló ti ń rò ó pé owó Hajj máa tó mílíọ̀nù mẹ́fà sí méje náírà pẹ̀lú bí owó náírà ṣe ń já wálẹ̀ ní ojoojúmọ́.
Ó ní owó dọ́là ló ń sọ iye tí owó Hajj máa jẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè tó jẹ́.
Àmọ́ ó kọminú lórí iye tí àwọn iléeṣẹ́ aládàni tó ń kó àwọn ènìyàn lọ sí Hajj yóò san, pé kí NAHCON wá ọgbọ́n láti mú àdínkù ba owó náà.
"Ó ba èèyàn nínú jẹ́ pé owó Hajj wọ́n tó báyìí àmọ́ tí èèyàn bá ti rí bí owó dọ́là ṣe ń lọ sókè, yóò mọ́ pé ó máa wọ́n tó báyìí."
"Kò sí bí ó ṣe lè wù kí ó wọ́n tó, ohun tó dá mi lójú ni pé àwọn èèyàn máa lọ sí Hajj náà ni nítorí ọ̀kan pàtàkì nínú òpó Islam ni."
"Mecca kìí ṣe ohun tí Mùsùlùmí kò gbọdọ̀ má lọ tí ó bá ti lówó lọ́wọ́."
Ǹjẹ́ ó tọ́ láti rán àwọn èèyàn ní Hajj pẹ̀lú bí nǹkan ṣe rí lásìkò yìí?
Alhaji Akewugbagold tún tẹ̀síwájú pé ìnira tí àwọn ènìyàn ń kojú lásìkò yìí lórí oúnjẹ lágbára púpọ̀ nítorí náà ìjọba gbọdọ̀ ṣọ́ra ṣe lórí rírán àwọn èèyàn ní Hajj.
Ó ní ohun tó yẹ kí ìjọba ṣe ni ìkúnpá fún àwọn tó bá ní owó lọ́wọ́ láti rán ara wọn lọ sí Hajj dípò kíkó owó gọbọi láti fi ran àwọn ènìyàn ní Mecca.
"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ìjọba máa ń fún ní Hajj ọ̀fẹ́ kìí mọ iyì rẹ̀, wọ́n sábà máa ń ṣìwà wù tí wọ́n bá dé Saudi ni.
Bákan náà ló tún wòye pé ọ̀pọ̀ tí ìjọba máa ń rán ní Hajj ni kò ní ìmọ̀ kíkún nípa ẹ̀sìn Islam.
Ó ní àìtẹ̀lé ìlànà tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ lórí Hajj ló máa ń fà á tí ọ̀pọ̀ fi máa ń ṣìwà wù lórí Hajj.
Ó fi kun pé ẹni tó bá máa ṣiṣẹ́ Hajj gbọdọ̀ tí kojú òṣùwọ̀n nínú òpó mẹ́rin tó ṣáájú nínú òpó ẹṣin Islam.
"Ọ̀pọ̀ ni kò ṣe òpó mẹ́rin àkọ́kọ́ tó gbé Islam ró tí wọ́n fi ń fò sí ìkarùn-ún nítorí afẹfẹyẹ̀yẹ̀."
"Mi ò ní kí ìjọba má ràn án èèyàn ní Hajj, àmọ́ kí wọ́n má ràn án àwọn ènìyàn tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí."
"Àsìkò tí ètò ọrọ̀ ajé ìlú bá dúró ire ni ìjọba lẹ́tọ̀ọ́ láti rán àwọn èèyàn ní Hajj kìí ṣe irú ìgbà tí ebi ń pa gbogbo ìlú yìí, kí ìjọba mójútó ọrọ̀ ajé kí wọ́n fi Hajj sílẹ̀ fún ẹni tó bá fẹ́ lọ lápò ara rẹ̀.
Alfa Akewugbagold ní ẹni tó bá fẹ́ rán èèyàn ní Hajj lásìkò yìí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wo ipa ẹni náà báyìí, kí ó ṣe ìrànlọ́wọ́ tó lè fi bọ́ ara rẹ̀ àti ẹbí rẹ̀ ná kí wọ́n tó ran lọ sí Mecca.
Ó tẹ̀síwájú pé gbígbọ́ bùkátà jíjẹ àti mímu ṣe pàtàkì lásìkò yìí ju rírán èèyàn lọ sí Mecca lọ.















