Wo ohun tó lè ṣẹlẹ nítorí ìdìbò tí wọ́n sún síwájú ní Senegal

Oríṣun àwòrán, Reuters
Orileede Senegal ti ọpọ a maa foju wo gẹgẹ bi awokọṣe fun iṣejọba awarawa nilẹ adulawọ lẹsẹ tiẹ naa ti n mi bayii pẹlu bi awọn oluwọde ati ọlọpaa ṣe koju arawọn niwaju ile aṣofin ilẹ naa.
Ninu ile aṣofin, awọn aṣofin ṣẹṣẹ fọwọ si abadofin kan ti aarẹ Macky Sall gbe kalẹ lati fi sunjọ saa rẹ siwaju to si tun sunjọ idibo to yẹ ko waye laarin ọsẹ mẹta si asiko yi.
Khalifa Sall to jẹ eekan ẹgbẹ alatako ati olori ilu Dakar sọ pe idiwọ yi jẹ ''iditẹgbajọba nipa lilo ofin'' to si kesi araalu lati tako igbesẹ yi.
Agbarijọpọ ẹgbẹ alatako rẹ ti lawọn yoo gba ile ẹjọ lọ lori ọrọ yii.
Thierno Alassane Sall juwe rẹ gẹgẹ bi iwa ''iditẹgabjọba to lagbara'' to si s fun awọn alatilẹyin tiẹ naa pe ki wọn pejọ ṣe iwọde niwaju ile aṣofin.
Aba ti aarẹ mu wa yi yoo nilo ibuwọlu ida mẹta ninu ida marun ọmọ ile lati fọwọ si.
Ẹgbẹ to wa lori oye Benno Bokk Yakkar coalition ti agbarijọpọ ẹgbẹ ti aarẹ naa pẹlu wọn ṣebi ẹni ni ọmọ ẹgbẹ to pọ julọ nile aṣofin.
Ariyanjiyan waye ni ile aṣofin lori ọrọ yi taa si gbọ pe wọn fi agbofinro gbe awọn aṣofin alatako kan jade ninu ile lẹyin ti wọn gbiyanju lati tako itẹsiwaju ibuwọlu aba yii.
Ni ipari, aṣofin marunlelọgọrun,105, asofin lo dibbo faramọ aba yi.
Wọn kọkọ daba oṣu mẹfa ṣugbọn wọn pada fẹnuko si pe ki Macky Sall tẹsiwaju lori saa rẹ pẹlu oṣu mẹwaa sii.
Ọgbẹni Sall ṣi n tẹnumọ pe oun ko fẹ dupo aarẹ mọ.
Amọ awọn alatako rẹ sọ pe o fẹ diwọ mọ agbara si ni tabi ko si lọwọ ninu yiyan ẹni ti yoo gba ipo lẹyin rẹ.
Kete ti wọn kede isunsiwaju idibo yi ni awọn oluwọde bọ si igboro ni Dakar ti wọn si ni ki wọn yi ofin yi pada.
Nilẹ Africa, Senegal jẹ orileede amuyangan ti ijọba awarawa ko ti ni idiwọ ni paapa lagbegbe iwọ oorun ilẹ naa.
Ko fi igba kankan ṣe idiwọ fun eto idibo aarẹ to si ti ṣeto igbejọba mẹta ti ko mu wahala dani mẹta ọtọ́tọ.
Lọdun 2017, awọn ọmọ ogun Senegal lewaju ikọ alaafia ọmọ ogun ilẹ Africa lati da laafia pada si Gambia nigba ti aarẹ Yahya Jammeh kọ lati gba pe oun fidirẹmi ninu idibo to waye.
Aarẹ Sall Senegal jẹ ọkan gbogi ninu awọn to n ko ipa ribiribi lati ri pe awọn olori agbegbe iwọ oorun Africa ṣeto idibo ti ko lẹja bakan ninu ti wọn si da ijọba pada fun ijọba alagbada.
Amọ pẹlu nkan to n ṣẹlẹ yi, o dabi ẹni pe epo ti fẹ ta si aṣọ aala Senegal.
Awọn onwoye si sọ pe idanwo nla leleyi jẹ lati ri bi Senegal yoo ṣe yanju aawọ yi.
Lati nkan bi ọdun meji ni awọn alatako ti n figbe bẹnu pe ijọba n fi ẹsun ti wọn ko mọwọ mẹsẹ kan awọn oludije wọn ki wọn ma baa le kopa ninu idibo.
Koda wọn fofin de oloṣelu ẹgbẹ alatako kan pe ko ni lanfaani ati kopa ninu idibo.
Amọ ṣa, awọn alaṣẹ sọ pe awọn ko lo etoilana ofin lati ṣe idiwọ fẹnikẹni.
Wọn si sọ pe nkan ti aarẹ Sall n ṣe ni pe o fẹ ki gbogbo nkan walẹ daada ki eto idibo baa le waye ni irọwọrọsẹ.
Ko jọ pe itgbesẹ rẹ yi n so eso rere kankan.
Lọjọ Aje, awọn alaṣẹ gbegidina lilo internet ki awọn eeyan ma ba fi ọrọ ''aburu tabi eyi to le koju ijọba ranṣẹ''
Ni soki, wọn ko fẹ ki awọn alatako kora jọ fun iwọde tako ijọba.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn olugbe kan to ba BBC sọrọ ṣalaye pe awọn ti n wa ọna ẹburu lati fi lo internet ti ijọba gbegi dina yii ṣugbọn ọpọ ni ko yi ribi lo internet .
Awọn alatako tun ti bẹnu atẹ lu bi wn ṣe ti ileeṣẹ amohunmaworan kan Walf Tv pa lori ẹsun pe o n gbe iroyin to n pepe si ikọlu ijọba.
Awọn alatako aarẹ meji ti wọn fi igba kan jẹ wọlewọde rẹ ni wọn mu nibi iwọde yi.
Lara wọn ni olootu ijọba tẹlẹ Aminata Toure.
Awọn alatako lawọn n foya pe idunkoko yi le mu ki wahala bẹ silẹ ni orileede yi ti yoo si tan de awọn orileede mii ni agbegbe iwọ oorun Africa.
Iṣejọba awarawa ni Senegal jẹ nkan tawọn eeyan ko fi taratara ni igbagbọ ninu rẹ mọ labẹ ijọba aarẹ Macky Sall.












