Ààrẹ Macky Sall lọ sí Russia àti Ukraine láti lọ parí ìjà: Kíni àbẹ̀wò rẹ̀ lè ṣé?

Aworan Aarẹ Macky Sall

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Macky Sall ti ni oun yoo ṣoju Ajọ Iṣọkan ilẹ Afrika, AU,lati rinrinajo lọ si orilẹede Russia ati Ukraine fun ijiroro alaafia.

Aarẹ orilẹede Senegal naa fi ero rẹ han lasiko ipadepọ pẹlu adari orilẹede Germany, Olaf Scholz ni Ọjọ Kejilelogun, Oṣu Karun un.

O ni ohun ti Afrika fẹ beere lọwọ Aarẹ Putin ni ko fun orilẹede Ukraine ni anfaani lati ko ounjẹ wooro ati ajilẹ wa si ilẹ Afrika.

Ati pe eyi yoo je ki awọn naa si gbegi kuro lori ọrọ aje ilẹ Russia, ki wọn ba le gbe ajilẹ wa si ilẹ Afrika.

Kini Ajọ African Union fẹ laarin Russia ati Ukraine?

Aarẹ ilẹ Senegal, Macky Sall to tun jẹ Alaga Ajọ Iṣọkan Ilẹ Afrika, AU ti fi iha ti ilẹ Afrika kọ si ogun to n waye laarin orilẹede Russia ati Ukraine.

O ni akọkọ ni pe kii ṣe ogun abẹle ilẹ Afrika nitori ilẹ miran lo ti n ṣẹlẹ ki n ṣe lọdọ awọn.

‘’Alaafia la fẹ laarin Russia ati Ukraine, ti a si n ṣiṣẹ lati jiroro pẹlu orilẹede mejeeji ki alaafia le jọba.’’

Kini ipa ti Afrika le ni lati fopin si ija naa?

Gẹgẹ bi ọrọ aarẹ Macky Sall, Ajọ African Union ti bẹrẹ ijiroro ati ayẹwo lori bi wọn ṣe le fi opin si ija naa ati ipa rẹ lori wọn.

O ni awọn ni igbẹkẹle ninu awọn alajumọṣiṣẹpọ wọn lati wa ọna abayọ si ija naa.

Amọ onimọ nipa eto oṣelu, Ibrahima Bakhoum ni ko si ohun kankan ti ilẹ Afrika le ṣe lati fopin si ogun naa.

Bẹẹ lo si ni bi Afrika ko ṣe dasi ija laarin orilẹede mejeeji yi yoo ran ilẹ ọhun lọwọ lati fẹnu ko sọna kanna.

Kini ilẹ Ukraine fẹ lọwọ ilẹ Afrika?

Ohun ti Aarẹ ilẹ Ukraine n bere lọwọ gbogbo agbaye ni lati parapọ dina mọ ọrọ aje ilẹ Russia, ki wọn ba le jawọ igbogunti wọn.

Bakan naa, orilẹede mejidinlọgbọn ni Ilẹ Afrika lo dibo lati bu ẹnu atẹ lu bi Russia ṣe ṣigun bo ilẹ Ukraine.

Amọ mẹtadinlogun ninu wọn ni ko dibo naa, eleyii ti Senegal wa ninu wọn.

Awọn to ku ni Sudan, South Africa, Namibia, Angola, Uganda, South Sudan, Zimbabwe, Burundi, Equatorial Guinea, Central African Republic, Madagascar, Algeria, Mali, Tanzania, Mozambique ati Congo.

Orilẹede Eritrea nikan lo dibo tako orilẹede Ukraine.

Kini Russia fẹ lọwọ Afrika?

Ohun ti Russia fẹ ni lati mu idagbasoke ba ipa rẹ ni ilẹ Afrika.

Ọna ti o si n gba ṣe eyi ni ibadọrẹ pẹlu awọn orilẹede bii ́́ Mali, Central African Republic ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lẹyin ti Russia ṣekọlu si Ukraine ni Russia n bere ki awọn orilẹede nilẹ Afrika fi ọwọ sowọpọ pẹlu ohun, abi ki wọn ma fi si ibi kankan paapaa ni awọn igbesẹ ti Ajọ Iṣọkan agbaye n gbe.

Kini Macky Sall yoo ṣe lasiko ibẹwo rẹ?

Iwadii fihan pe Aarẹ Ilẹ Senegal yoo ṣe ipade pọ pẹlu Aarẹ orilẹede Russia, Vladmir Putin ati Aarẹ ilẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky.

Iroyin labẹle ni Ọjọ Kẹta, Oṣu Kẹfa ni Macky Sall yoo ṣabẹwo si Russia, amọ oun fun ara rẹ ko ti sọ di mimọ fun agbaye.