Alfa Labeeb Lagbaji, Modrasat Mohammed wọ́gilé ẹjọ́ tí wọ́n pe Tani-Ọlọhun

Alfa Labeeb Lagbaji ati ẹgbẹ Modrasat Mohammed ti wọgile ẹjọ ti wọn pe ilu mọka onisẹse e ni, Abdulazeez Adegbọla ti a mọ si Tani-Ọlọhun.
Eyi waye ni ile ẹjọ Majisireeti kan to fi ilu Ilorin to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara ṣe ibujoko.
Iwaju Magistrate Mohammed Adam ni ẹjọ naa ti waye lonii ọjọ kẹfa osu keji ọdun 2024 yii.
Ẹsun ọtọọtọ ni awọn mejeji fi kan an ni ile ẹjọ kan naa.
Akọkọ ni ti Alfa Labeeb Lagbaji lori ẹsun ibanilorukọjẹ, ekeji si ni ti ẹgbẹ Modrasat Muhammad fun ẹsun jijo Kurani nina.
Awọn ẹjọ meji yi waye tẹle ara wọn, ile ẹjọ si wọgile wọn nipasẹ isẹ ti awọn agbẹjọro wọn wa jẹ ni ile ẹjọ.
Awọn agbẹjọro naa lo sọ fun ile ẹjọ pe, awọn olupẹjọ ti awọn n duro fun ti setan lati wọgile awọn ẹjọ ti wọn pe olujẹjọ.
Wọn salaye pe awọn onibara awọn ṣe ipinnu yi latari ipade alaafia to waye laarin wọn ati olujẹjọ.
Adajọ Mohammed Adam ko se meni ko se meji, o wọgile ẹjọ naa o si ni ki Tani-Olohun maa lọ layọ ati alaafia.
Ẹjọ ti wa ku meji lọrun Tani-Olohun bayi lati dominira patapata.















