Ọmọ ológo Stanley Nwabali: Wo ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa àpáta nlá aṣọ́lé Nàìjíríà tó fakọyọ

Aworan Stanley Nwabali aṣọle Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty

Inu didun nii moriya.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ṣi n dunnu pẹlu aṣeyọri ikọ agbagbọọlu ọkunrin orileede naa Super Eagles bi wọn ṣe fidi akẹgbẹ wọn lati orileede South Africa Bafana Bafana janlẹ nibi idije Afcon to n lọ lọwọ.

Aṣeyọri yi tunmọ si pe Naijiria ni yoo koju orileede Cote d' voire to jẹ olugbalejo idije naa nibi aṣekagba lọjọ Aiku.

Orin ayọ ati ijo idunnu lọpọ n jo ti wọn si n kan saara sawọn agbabọọlu Naijiria.

Amọ ninu awọn agbabọọlu naa, o ni eeyan kan tawọnb ọmọ Naijiria n ran ọrọ rẹ lẹnu gẹgẹ bi apata nla to duro wamu loju ile Naijiria.

Ẹni taa n wi yi ni Stanley Nwabali aṣọle Naijiria to fakọyo nibi ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba idije Afcon.

Ta wa ni arakunrin yii ati pe igba wo lo ti n ba ọrọ ere bọọlu bọ?

Alaye ree nipa aṣọle Naijiria Stanley Nwabali

Ibẹrẹ ṣoro diẹ ki Nwabali to gbera sọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Stanley Bobbi 'Bobo' Nwabali, jẹ agbabọọlu ọmọ orileede Naijiria to si tun ṣoju ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Chippa United ni liigi orileede South Africa.

Ipinlẹ Rivers ni wọn bi si to si dagba si ilu Port Harcourt.

Okwuzi lorukọ ilu ti awọn obi rẹ ti wa.

A ri ka nibi kan pe agbawaju ni Stanley Nwabali kọkọ fi bẹrẹ nidi ere bọọlu ko to di pe o yipo pada si aṣọle.

Ọdun 2019 la le sọ pe o bẹrẹ ere bọọlu gẹgẹ bi ogbontarigi pẹlu ikọ Go Round FC ni saa bọọlu ọdun 2017/18.

Ọmọ ọdun mejilelogun lo jẹ nigba naa.

O kuro nibẹ lọ si Enyimba ni saa bọọlu 2018/19 to si wa nibẹ titi di ọdun 2020 to lọ darapọ mọ Wikki Tourist.

O kuro ni Wikki lọ si Lobi Stars fun saa meji ,Katsian United lo kan lẹyin igba naa to lo saa 2021/22 nibẹ. ko to wa kangun si South Africa pẹlu Chippa United to wa bayii.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ laarin Naijiria ati Mexico ni ilu Los Angles lorileede America ni Stanley ti kọkọ ṣoju Naijiria.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ yi to waye lọjọ kẹta oṣu Keje ọdun 2021, goolu mẹrin si odo ni Mexico fi gbewuro soju Naijiria.

Nwabali ni aṣọle ọjọ naa ti wọn jẹ goolu wọnyi lọwọ rẹ.

Afcon 2023 ni o gbe ogo Nwabali yọ si ọmọ Naijiria

Lara ipenija ti ikọ agbabọọlu Naijiria Super Eagles n koju ṣaaju ki wọn to lọ si idije Afcon to n lọ lọwọ yi ni ẹni ti yoo di ipo aṣọle ikọ naa.

Ṣaaju asiko yi, awọn aṣọle bi Francis Uzoho ati Maduka Okoye lo wa loju ọpọn.

Koda nigba taa n wi yi, ọmọ Naijiria ti n bẹnu atẹ lu aṣọle Francis Uzoho pe inu awọn ko dun si pẹlu bo ṣe n sọ ile.

Idije Afcon bẹrẹ ti Akọnimọọgba Naijiria Jose Peseiro si yan Stanley Nwabali ko sọ ile Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ pẹlu Equitorial Guinea.

Lati igba to ti bọ soju ile fun Naijira lawọn ọmọ Naijiria ti nifẹ si pẹlu itu ati akitiyan to ṣafihan rẹ loju papa.

Ọpọ igba ni Nwabali gba Naijiria kalẹ lọwọ awọn alatako wọn ti eyi si ṣokunfa itẹsiwaju Naijiria nibi idije yi.

Koda nigba to farapa ninu ifẹsẹwọnsẹ Naijiria pẹlu Cameroon ọpọ ọm Naijiria lo ba kẹdun ti wọn si fi adura ranṣẹ pe ki ara rẹ tete ya.

O ṣara wayi pada to si tun bọ soju ile fun Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Angola.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ yi o gba Naijira kalẹ pẹlu bo ṣe duro wamu ti ko jẹ ki goolu wọle soju awọn Naijiria.

Bẹrẹ lati ifẹsẹwọnsẹ akọkọ to fi de ti eyi ti wọn ti koju South Africa yii, Nwabali duro wamu koda o tun mu meji ninu pẹnariti ti awọn South Africa dari si ọdọ rẹ.

Aworan Nwabali ati akẹgbẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki lawọn ọmọ Naijiria n ṣo nipa Nwabali

Loju opo ayelujara awọn ọmọ Naijiria n kan saara si Nwabali ti wọn si ti bẹrẹ si nipe lorisi orukọ lati fi fi gboṣuba fun un.

Oju opo rẹ ni Instagram ti ko ni ju eeyan ẹgbẹrun lọna mọkanlelogun to n baa dọrẹ ti gbera lọ si eeyan ni ẹgbẹrun lọna igba.

Loju opo Twitter a ri fọnran fidio kan nibi ti awọn ọmọ Naijiria ti tu yaaya lọ si ile baba Nwabali ni ilu PortHarcourt

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Awọn kan tun sọ pe bi o ba lọ sidi POS lọ gba owo bi wọn ba beere iru akanti rẹ, ko yara kọ orukọ Nwabali sibẹ

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Lori owo dọla to n lọ soke lasiko yi, wọn tun sọ pe Nwabali lo le da duro.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3