Nigeria vs South Africa: Ìjà àgbà méjì láàrín Super Eagles àti Bafana Bafana ní Afcon 2023

- Author, Isaiah Akinremi ati Emmanuel Akindibuwa
- Role, BBC Sport Africa
- Reporting from, Lagos
Nigeria, orilẹede to ti gba ife ẹyẹ Afcon ni igba igba mẹta yoo tun gbe ina wo oju pẹlu South Africa ninu ipele to kangun si aṣekagba idije ife ẹyẹ Afcon 2023 ni Ọjọru.
Ni igba mẹta ọtọọtọ ti awọn orilẹede mejeeji yii ti figagbaga ṣaaju asiko yii ni idije Afcon, Naijiria lo n gbegba oroke. Ni ti ero awọn onwoye, orilẹeede Naijiria lọpọ n fi oju si gẹgẹ bi ẹni ti yoo bori lẹyin ti awọn orilẹede ti a le tọka si gẹgẹbii egungun nla gbogbo lagbo ere bọọlu ni Afrika to wa si ibi idije naa ti di ero iworan lẹyin ti wọn ti ja kuro ninu idije ọhun.
Amọṣa,ikọ Bafana bafana South Africa to gba ife ẹyẹ naa ni ọdun 1996 ti yọ ọwọ Morocco ni idije naa. Morocco si ni orilẹede Afirika ti ipo rẹ ga julọ ni atẹ igbelewọn ajọ FIFA fun awọn orilẹede gbogbo to n gba bọọlu lagbaye.
South Afrika yoo fẹ gbẹsan irora atẹyinwa lara Naijiria, paapaa nigba ti Naijiria na wọn pẹlu goolu meji si odo lọdun 2000 ti wọn kọkọ de ipele to kangun si aṣekagba.
Kan lara awọn eekan agbabọọlu Super Eagles ni igba kan ri, Tijjani Babangida ṣalaye fun BBC Sports Africa pe “ifigagbaga nla lo n waye laarin orilẹede Naijiria ati South Africa, eyi ti yoo mu ki ifẹsẹwọnsẹ laarin wọn gbona janjan.”
Ọdun 2019 ni awọn mejeeji yii pade gbẹyin ni idije Afcon ti Naijiria si bori pẹlu goolu meji si ẹyọ kan.
Balogun ikọ agbabọọlu South Africa tẹlẹDean Furman fi to BBC World Football ninu eto ifọrọwerọ kan to waye nipa Afcon peIgba kan wa ti o ku diẹ ki awọn na Naijiria ki wọn to gba goolu kan wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa fẹ de opin.”
“A fidirẹmi niwaju wọn lọdun 2013 ni ipele quarter final; ṣugbọn bayi a ti kọja ipele yii.”
Naijiria ni okuta idena lọna Bafana

Oríṣun àwòrán, BBC Sport
Ipo kejilelogoji ni Naijiria wa lori atẹ igbelewọn FIFA, igbesẹ mẹrinlelogun ni wọn fi ju South africa, amọ South Africa wọ awọn agba iṣaju kan nilẹ ni ipele komẹsẹ o yọ akọkọ eyi ti wọn ti lu Moroccopẹlu goolu meji si odo.
‘Ohun ti wọn gba pẹlu Morocco jẹ ifẹsẹwọnsẹ wọn ti mo ṣi gbadun julọ lati ọpọlọpọ sẹyin” ni ọrọ ti Mark Fish, ọkan pataki lara ikọ Bafanabafana to gba ife ẹyẹ naa ni ọdun 1996 ṣe lalaye fun BBC Sports Africa.
“A mọ pe Naijira ni okun ati agbara pupọ pẹlu awọn ẹlẹsẹ ayo to pọ, ṣugbọn South Africa naa gbọdọ doju kọ wọn pẹlu ipinnu kan naa ti wọn ti fi ṣẹgun gbogbo ifẹsẹwọẹ wọn iṣaaju.”
Ija agba meji laarin awọn aṣọle

Oríṣun àwòrán, BBC Sport
Ikọ mejeeji lo ni aṣọle to gbamuṣe ti eeyan le ka kun awọn to dara julọ ni idije naa. Ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ni ko ti si ẹni to tii gba goolu sinu awọn awọn mejeeji.
Amọṣa aṣọle South Africa, Rowen Williams jẹri ọmọ ọkọ ni ifẹsẹwọnsẹ wọn ti wọn gba ni Quarter finals pẹlu Cape Verde nibi to ti mu pẹnariti mẹrin.
Furman ni “Ronwen ti di ilu mọọka ni South Africa bayii. Ko dẹrun lati mu pẹnariti mẹrin.”
Stanley Nwabali, aṣọle Naijiria ni tirẹ ko ṣoju Naijiria ju igba meji lọ ṣaaju idije Afcon.















