Ìjọba buwọ́lu òfin tó wọ́gilé ìdájọ́ ikú

Oríṣun àwòrán, others
Ijọba orilẹede Zimbabwe ti buwọlu ofin to wọgile idajọ iku lorilẹede naa.
Awọn igbimọ alasẹ lorilẹede Zimbabwe gbe igbesẹ yii lẹyin ogun ọdun ti orilẹede naa kọkọ fọwọsi idajọ iku fun eeyan kan.
Minisita fun eto iroyin lorilẹede naa, Jenfan Muswere, ṣalaye pe awọnọmọ igbimọ iṣejọba lorilẹede naa gbe igbesẹ yii lẹyin ti ijọba buwọlu ofin naa.
Igbimọ awọn Minisita ni ki ijọba rọpo idajọ iku pẹlu ẹwọn egbere gẹgẹ bi ijiya to ga julọ lorilẹede Zimbabwe.

Oríṣun àwòrán, AFP
Saaju ni Aarẹ orilẹede Zimbabwe, Emmerson Mnangagwa bu ẹnu atẹlu lilo idajọ iku fun awọn ẹlẹsẹ.
Mnangagwa, lọdun 1965 ni wọn dajọ iku fun lẹyin ti wọn fẹsun kan lọwọ ninu ado oloro to bugbamu ninu ọkọ Reluwe lasiko to kopa ninu ogun.
Lẹyin ọ rẹyin, ni Ile ẹjọ yii idajọ naa pada lẹyin ti awọn agbẹjọro rẹ ni ko ti to iye ọdun to yẹ ko ri iru ijiya bẹ.
Gẹgẹ bii ofin se gbe kalẹ, idajọ iku wa fun awọn to wa ni ẹni ọdun mọkanlelogun si aadọrin ọdun.
Ọdun 2005 ni idajọ iku waye gbẹyin lorilẹede Zimbabwe.















