Ààrẹ Tinubu gbóríyìn fún Super Eagles, Ó níẹ̀bùn wà nílẹ̀ fún wọn

Aarẹ Orilẹede NAijiria, Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/twitter

Aarẹ orileede Naijiria, Bọla Ahmẹd Tinubu ti gbe oriyin fun ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lori bi wọn ṣe yawe oluwori kuro ni ipele to kangun si aṣekagba bọ si ipele aṣekagba gangan.

Lalẹ ana ni ikọ Super Eagles doju akẹgbẹ wọn ti Bafana-Bafana lati orileede South Africa bolẹ ninu idije ife ẹyẹ ilẹ Adulawọ to n lọ lọwọ lorileede Ivory Coast.

Ọọmi ni ifẹsẹwọnsẹ ọhun yọri si, ko to di pe wọn bọ si ipele pẹnariti.

Aworan ọrọ ti Tinubu kọ si awọn ikọ Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Screenshot/tinubu

Super Eagles bori Bafana-Bafana pẹlu ami ayo mẹrin si meji lati fi bọ si ipele aṣekagba.

Tinubu lasiko to n ki awọn Super Eagles lori ikanni ayelujara rẹ, o ni kaakiri ilẹ Afrika ni awọn agbabọọlu naa ti gbe ogo Naijiria ga.

Bẹẹ lo sọ pe ohun iwuri ni wọn jẹ fun awọn ọmọ Naijiria pẹlu ọkan itara ati akikanju ti wọn fi n gba bọọlu.

Ẹ gbiyanju lati gba ife ẹyẹ yii wale -Kashim Shettima, igbakeji aarẹ Naijiria

Igbakeji Aarẹ, Kasim Shettima atawọn ikọ Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Prince Dapo Abiodun - MFR, CON

Bakan naa, igbakeji aarẹ, Kashim Shettima toun naa kọwọrin lọ wo ifẹsẹwọnsẹ ọhun pẹlu Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun; Gomina Douye Diri ti ipinlẹ Bayelsa sọ pe oun gbe oṣuba kare fun wọn.

Awọn to tun tẹle igbakeji aarẹ ni minisita f'ọrọ eto ọdọ ni Naijiria, Jamila Bio Ibrahim; minisita f'ọrọ ere idaraya, Sẹnetọ John Owan Enoh-JOE ati awọn miran ninu ijọba.

Kashim Shettima ninu ọrọ rẹ gba Super Eagles lamọran lati gbiyanju gbe ife ẹyẹ naa wa sile, nitori pe gbogbo ọmọ Naijiria lo wa lẹyin wọn.

Alaga ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara gbe oṣuba kare fun ikọ Super Eagles.

O loun dupẹ lọwọ wọn pe wọn ko jẹ ki ireti araalu to le ni igba miliọnu ti wọn n gbadura lati ile ja si ofo

'Àwọn ọmọ Naijiria n reti aṣeyọri Super Eagles'

Aworan oju opo Twitter Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Dapo Abiodun

Gomina Dapọ Abiọdun toun naa wa ni papa iṣere Stade Bouaké pẹlu oluworan to le diẹ ni ẹgbẹrun mọkanlelọgbọn (31,227).

Nigba ti n sọrọ, o gbogbo ọmọ orileede Naijiria ni wọn reti ki ikọ Super Eagles bori akẹgbẹ wọn lati South Africa, iyẹn awọn Bafana-Bafana ninu idije AFCON2024 to n lọ lọwọ yii.

Bakan naa lo sọ pe oun tun n reti aṣeyọri wọn bi wọn ṣe n gbaradi lati koju ikọ Eerin lati orileede Ivory Coast ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba.

Gomina Douye Diri ti Bayelsa sọ pe oun gbadun gbogbo asiko ifẹsẹwọnsẹ to waye pẹlu ikọ Bafana-Bafana ni papa iṣere Stade Bouaké ni Côte D'Ivoire.

Diri ni inu oun dun pe Naijiria ti wa ni ipele agbakẹyin.

Igbakeji Aarẹ, Kasim Shettima atawọn ikọ Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Dapo Abiodun

Minisita f'ọrọ ere idaraya lorileede Naijiria, Sẹnetọ John Owan Enoh-JOE toun naa wa ni papa iṣere ọhun sọ pe ikọ Super Eagles fun awọn akikanju ọmọ Naijiria ni ọkan lati dunnu.

O lawọn ọmọ Naijiria ti ṣi fila soke fun wọn nitori ti wọn fi han pe ọkan aṣeyọri ni awọn araalu ni.

Bẹẹ lo rọ wọn pe ki wọn tubọ lo ọkan akikanju wọn lati fi gbe ife ẹyẹ ilẹ Adulawọ wa si Naijiria.

Gomina Ademọla Adeleke ti ipinle Ọṣun ni tiẹ fi ijo ati ayọ ki Super Eagles fun aṣeyọri nla naa, to si ni o fi ọkan oun balẹ pe oriire naa yoo ja si ibi naa araalu n lero.

Nigba to n sọrọ loju opo 'X' rẹ, o ni oun ni asiko to dara lati wo Super Eagles nibi ti wọn ti fi agba han akẹgbẹ wọn lati South Africa.