Ǹjẹ́ ìpàdé àwọn Mínísítà ilẹ́ òkèrè lájọ Ecowas lè rí wàhálà Niger yanjú?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn Minisita ilẹ okere orileede to jẹ ọmọ ẹgbẹ Ecowas yoo ṣe ipade lỌjọbọ ni ilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria.
Ipade yi ni akọkọ iru rẹ ti yoo waye lẹyin ti awọn orileede Niger, Mali ati Burkina Faso kede pe awọn ti yapa kuro ninu ẹgbẹ naa.
Bẹẹ naa ni yoo waye lẹyin ikede aarẹ Senegal Macky Sall to sunjọ idibo aarẹ to yẹ ko waye siwaju.
Ipade awọn minisita yi a maa waye ṣaaju eleyi tawọn aarẹ yoo ti pade lati wa ojutu si awọn ọrọ to wa nilẹ.
Loju opo rẹ, Ecowas sọ pe ipade pataki ni eleyi jẹ nibi tawọn igbimọ apẹtusaawọ ati igbimọ aabo awọn minisita wọnyii yoo jiroro.
Ijiroro wọn yoo si da lori awọn ipoenija aabo ati eyi to lọwọ oṣelu ninu to n koju agbegbe iw oorun ilẹ Africa.
Lati ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kini ni Mali Burkina Faso ati Niger ti kede erongba wọn pe awọn ko ba Ecowas ṣe mọ.
Lọjọru,awọn orileede mẹta yi tawọn ologun ti gbajọba nibẹ tun tẹnu mọ ipinnu wọn lati yapa kuro ninu ẹgbẹ Ecowas ṣaaju ipade wọn.
Mali, Burkina Faso ati Niger lawọn ko ṣe mọ pẹlu Ecowas nitori awọn ijiya ti ẹgbẹ naa gbe le wọn lori nipa ọrọ aje lẹyin tawọn ologun gba ijọba nilẹ wọn.
Onimọ nipa ọrọ oṣelu Ọjọgbọn Jibrin Ibrahim sọ pe o yẹ ki awọn olori ẹgbẹ Ecowas ṣe pẹlẹ ki wọn si ma kaju kuro lara awọn orileede to fẹ yapa yi.
O ni ipenija nla ni yoo jẹ ti ọmọ ẹgbẹ Ecowas mẹrin ba yapa kuro lẹẹkan ṣoṣo
ti Senegal naa si n koju ipenija tiẹ nipa wahala to n ba eto oṣelu lẹyin ti aarẹ Macky Sall sun ọjọ idibo siwaju
Ki ni ireti awọn eeyan orileede Niger bayii?
Bo ti lẹ jẹ wi pe ero ṣe ọtọọtọ niupa nkan to n ṣẹlẹ ni orileede Niger-awọn kan faramọ ologun,awọn mi ko faramọ-gbogboawọn eeyan ilẹ naa lo jijọ n mọ inira ijiya ọrọ aje ti Ecowas gbe kalẹ lara.
Kassoum Mukhtar to jẹ Minisita tẹlẹ ri labẹ ijọba aarẹ Bazoum ti wọn yẹ aga nidi rẹ sọ pe o yẹ ki Ecowas ṣe pẹlẹ lori ọrọ yi ti wọn ko ba fẹ wahala ti yoo sọ ẹgbẹ naa sinu idaamu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Ijiya ọrọ aje oloṣu meje yi jẹ inira fun awọn araalu Niger tori naa ki wọn dawọ rẹ duro. Ti wọn ba wo ohun to n ṣẹlẹ daada wọn a ri wi pe tohun ti ijiya ti wọn gbe kalẹ ifẹ awọn araalu si awọn ologun ko dinku, o n peleke sii ni.
O ni ''Eyi fi han pe gbogbo igbesẹ ti Ecowas n gbe awọn araalu ko faramọ''
Kassoum Mukhtar tẹsiwaju pe o yẹ ki Ecowas maa ṣiṣẹ tọ idagbasoke awujọ ni
Ọpọ awọn ọmọ Niger n reti abajade daada lati ipade yi ti Ecowas fẹ jiroro nipa ilẹ wọn to yapa kuro ninu ẹgbẹ naa.
Ọmọ orileede Niger kan to ba wa sọrọ sọ pe ''a le ro pe orire ni ipade yi yoo mu wa fun wa tori pe awa eeyan Niger ti farada inira pupọ ati pe awọn alaini lo mọ inira yi lara julọ''
Mali, Niger ati Burkina Faso lawọn ko lodi si wiwa ninu ẹgbẹ naa lopin igba ti ko ba ti si nkankan to ṣe idiwọ fun wọn ninu ẹgbẹ Ecowas.
Ohun to wa nilẹ bayii ni pe Ecowas gbọdọ tẹti si awọn ibeere awọn olori ologun yi ti wọn ba fẹ ki wọn pada sinu ẹgbẹ naa.














