Wo àwọn àbùdá mẹ́jọ tí àwọn tó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún láyé máa ń ní

Àwòrán ẹni ọgọrun un ọdún

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Fernanda Paúl
    • Role, BBC World Service

Margarita Flores n dide ni kutukutu ni ojojumọ. Yoo jẹ ounjẹ aarọ, lọ fun rinsẹ ti yoo si tun ka iwe.

O sọ pe o nifẹ lati ṣe ju bayii lọ, bii lọ si ibi-idaraya. ṣugbọn gẹgẹ bi ẹni ọgọrun ọdun leni meje (107), awọn ẹsẹ rẹ ko ni agbara to nilo.

“Mo le jẹ ki wọn rin sii ko le mọ wọn lara,” o ṣe awada pẹlu akọroyin BBC Fernanda Paúl lati ile rẹ ni ilu Santiago ni Chile.

Àwòrán Margarita Flores

Oríṣun àwòrán, Flores family

Lasiko ifọrọwerọ mi pẹlu ẹni ọgọrun-un ọdun naa, o sọrọ ni irọrun, ti mo si gbọ ohun to n sọ daada. O ni awọn ọrẹ, ati ọmọbirin kan ti o wa pẹlu rẹ lojoojumọ.

O sọ pe: “Ní ọjọ orí mi, mo ṣi fẹ ṣe ọpọ nnkan.

Margarita jẹ apẹẹrẹ rere ti awọn amoye abuda sọ pe ọpọlọpọ awọn eniyan ti o ju ọgọrun un lọ to si tun wa ni ilera: igbesi aye, resilience ati ifẹ lati ṣe ajọṣepọ.

Àwòrán

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Margarita jẹ apakan ti aṣa to gboro.

Gẹgẹ bi ajọ agbaye (UN) se ti sọ, o wọpọ fun awọn eeyan lati fẹ abẹla to le ní Ọgọrun un fun ọjọbi wọn.

Ni ọdun 1990, awọn eeyan ẹgbẹrun mejiladọrun nikan ni wọn ni anfaani yẹn, sugbọn lọdun 2021 iye awọn eeyan yii lo ti di pupọ si 621,000.

Bo ti lẹ jẹ pe awọn iwadi jiini nipa igbesi yii ti awọn onimọ si ṣe itupalẹ iṣẹlẹ yii, ọpọlọpọ awọn amoye to n ṣe tọju n kopa nla ninu iwadii.

María Dolores Merino, onimọ ìjìnlẹ-ọkan ati ìmọ ẹkọ ní fasiti Complutense ti Madrid, Sípéènì, jẹ ọkan lara wọn. O ti ṣe iwadii awọn ọgọrun ọdun fun ọpọlọpọ ọdun.

Ninu ọkan ninu awọn ẹkọ rẹ to ṣẹṣẹ jade, iwadii rẹ ri pe awọn ẹgbẹ yii ni awọn ohun afijọ mọkandinlogun.

O ti pin wọn si awọn isọrimẹjọ, eyi ti a ṣe akojọ si isalẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

1. Okun/Agbára

Ọkan ninu awọn abuda ni okun tabi agbara, to jẹ mọ riri ara ẹni to o wa laaye, to kun fun ọpọlọpọ agbara

María Dolores Merino ṣalaye fun BBC pe: “Ó yani lẹnu gan-an: awọn eeyan to le ni ọgọrun -un ọdun ta a fọrọ wa lẹnu wo ní ìfẹ ọkan lati tẹsiwaju gbigbe ile aye.

“Tí ẹ ba ń ba wọn sọrọ, o ní sọ pe ẹni yẹn ti le ni ọgọrun-ún [100] ọdún. Ni gbogbo rẹ, a le sapejuwe wọn gẹgẹ bii ẹni to ri ara rẹ gẹgẹ bii ti ẹnikan to n kere lọjọ ori, ”o ṣafikun.

Àwòrán arúgbó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lara awọn ti o kopa ninu iwadii Merino ni awọn obinrin ati awọn ọkunrin ti wọn tẹsiwaju lati ṣiṣẹ titi ti wọn fi di ẹni ọdun mejidinlọgọrun.

Wọn tun gbiyanju lati kopa ninu awọn iṣe to n ṣe ara loore, gẹgẹ bi lilọ si oke ati isalẹ awọn pẹtẹẹsì lojoojumọ, títa ayo kaadi ere, tabi ṣiṣe Sudoku.

Stacy Andersen jẹ oludari-alakoso ti Ikẹkọ New England Centenarian, ile-iṣẹ kan ni ilu Amẹrika ti Boston to jẹ ẹka Iwadii lori awọn eeyan to le ni ọgọrun ọdun lọ. O gba pe igbesi aye to ni okun jẹ abuda ọlọpọlọ pataki kan.

“Ọpọ awọn eeyan sọ pe awọn n gbadun igbesi aye ati pe, fun mi,o jẹ ohun iyalẹnu,” o sọ fun BBC.

Àwòrán arúgbó to gbe ọmọ kekere kan dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

2. Ìfàsí ọkàn láti bá ẹlòmíì ṣòrọ̀

Gẹgẹ bi ìwadii tí María Dolores Merino ṣe ṣafihan, awọn eeyan tí wọ́n ti le ní ọgọrun un ọdun saba ma a nifẹ ba awọn eeyan sọrọ.

“Wọn ni ìbaṣepọ ọlọyaya pẹlu idile wọn tabi awọn ọrẹ wọn. Wọn ṣe iranlọwọ fun awọn miiran nigbati wọn ba le se ati pe wọn nifẹẹ pupọ. eyi ti o ṣe pataki pupọ, ”

Stacy Andersen sọ pe iṣẹ rẹ ti mu ṣe akiyesi pe awọn eeyan yii jẹ eeyan “to ni nifẹ lati pade awọn eeyan tuntun.”

“Ṣugbọn o ṣeni laanu pe ọkan ninu awọn alebu pipe ọgọrun un ọdun o le padanu ọpọlọpọ awọn ọrẹ ati ẹbi rẹ. Nitori naa agbara lati pade eeyan tuntun ati ṣii si awọn asopọ tuntun jẹ pataki gaan, ”o ṣafikun.

Àwòrán Margarita Flores

Oríṣun àwòrán, Flores family

Margarita Flores sọ pe nini awọn ọrẹ "ṣe pataki pupọ".

O ṣalaye pe: “Nítori pe lọna yẹn, mi o ni da wa.

Àwòrán bí àwọn arúgbó ṣe ń bara wọn sọrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

3. Ìfarajìn

Iwa miiran ti awọn eeyan to ti pe ọgọrun ọdun pin ni ìfarajin, gẹgẹ bii iwadii ṣe sọ.

“Ni gbogbo rẹ, saaju wọn ti jẹ eeyan to mọ ojuse, oye ati eeya to n ṣiṣẹ takuntakun. Wọn ní ìfarajin lati mu ero wọn wa si imusẹ,” ni María Dolores Merino sọ.

Ile ẹkọ Stacy Andersen (New England Centenarian) ti n ṣe ikẹkọ ihuwasi ti awọn ọmọde fun ọgọrun un ọdun.

O sọ pe eyi jẹ nitori “ni gbogbo rẹ, wọn tẹle ipasẹ awọn obi wọn.

“A se akiyesi pe ani ní ogun ọdun sẹyin, wiwa laaye ní ìsopọ pẹlú nini koko gíga laye. Wọn ni awọn ibi-afẹde ti wọn fẹ lati ṣaṣeyọri. Wọn rii pe ọjọ kọọkan ni idi kan ti rẹ, ”o sọ.

“Ọkan ninu awọn ẹgbẹ ti o ti ṣe iwadii ni pẹkipẹki nípa ọpọlọ wa ni Japan. Ati pe wọn ni gbolohun ọrọ yii ti wọn pe ni 'Ikigai', eyiti o ni idi kan lati dide ni gbogbo owurọ - eyi fara oẹ nini koko pataki ni igbesi aye.

“Mo ro pe iyẹn gaan ṣe ipa nla ni wiwa ni ẹni ọgọrun un ọdun,” Andersen ṣafikun.

Àwòrán bí àwọn arúgbó ṣe n se ere idaraya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

4. Akitiyan

Akitiyan jẹ ọkan pataki ninu awọn abuda fun ti awọn eeyan to jẹ ẹni ọgọrun un ọdun tabi ju bẹlọ, ni ibamu pelu iwadi awọn ẹgbẹ kan.

Nini Akitiyan - ni a le sapejuwe gẹgẹ ni anfani lati bori awọn ipọnju, ati paapaa lati ni okun nipasẹ iriri yẹn - ni ibatan si igbesi aye gigun.

"O jẹ orisun ti o lagbara pupọ, nitori pe o fun ọ laaye lati koju awọn ipọnju ati siwaju, laisi ipalara ti ẹmi nipasẹ rẹ," Merino sọ.

“Nipa nini iru igbesi aye gigun bẹ, awọn eniyan laise aniani ti ni iriri to nira pupọ,bii awọn iṣẹlẹ to ti waye sẹyin - gẹgẹ bi ogun tabi awọn ajakale-arun - si pipadanu awọn ololufẹ.”

Stacy Andersen gba.

Ó sọ pe: “O daju pe wọn banu jẹ lori awọn nnkan to ti waye tẹlẹ, ṣugbọn wọn fi wọ́n sílẹ̀ sẹyin, wọ́n sì ń tẹ síwájú.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

5. Ìdarí

Gẹgẹ bii awọn oniwadi, awọn eeyan to ti pe ọgọrun un ọdun maa ṣe afihan ifarahan lati ṣe awọn ipinnu tiwọn, ti iṣakoso igbesi aye wọn si wa lọwọ wọn.

Merino ṣalaye pe: “Wọn ti ṣeto aye wọn ní ilana ti wọn fẹ.

"Wọn tun ti mọ bi a ṣe le wa awọn anfani, wọn si pinnu ara wọn eyi ti wọn yoo lepa."

Àwòrán

Oríṣun àwòrán, Getty Images

6. Ìwúrí ọkàn

Iwadi ti laipe yii lati ọwọ María Dolores Merino tọka si pe awọn eniyan ti o ju ọgọrun un ọdun lọ ọkan to jafajafa, abuda bii iwariiri, ifẹ si ẹkọ ati ikẹkọ ara-ẹni.

Awọn tí a fọrọ wa ọrọ lẹnu wo fun ìkẹkọọ naa fi ifẹ han si ohun to n sẹlẹ lagbaye or n kẹkọọ nípa nnkan ti yoo wulo fun wọn.

Merino sọ pé: “Ni ọpọ ìgba wọn jẹ onkawe nla, tí wọn si ni awọn akojọpọ ìwe to fani mọra.

Margarita Flores jẹ ọkan ninu wọn. Lọwọlọwọ, o n ka iwe nípa itan aye ti Pope Francis.

"Ṣugbọn mo ka ọpọlọpọ awọn ohun miiran lati ji peepe - lati awọn iwe-akọọlẹ aṣa aṣọ ríran si awọn iwe-ifẹ," o fi igberaga ṣe alaye.

Àwòrán

Oríṣun àwòrán, Getty Images

7. Níní èrò rere

Stacy Andersen sọ pe “Awọn eeyan to ti le ni ọgọrun un ọdun ni lati ni ero rere.

"O ṣọwọn lati gbọ pe ẹni ọgọrun un ọdun kan sọ pe: 'O wu mi pe ki maa wa laaye.' Ṣugbọn ti o ba beere lọwọ ẹni ogoji ọdun, ṣe o fẹ to ẹni ọgọrun un ọdun laay, pupọ wọn yoo sọ pe 'Rara'.

Gẹgẹ bí iwadii Merino ṣe sọ, awọn agbalagba to ti le ni ọgọrun un ọdun ni inu wọn ko ki dun nitori ero pe wọn ko ni pẹ jade laaye

Margarita Flores sọ pe o wa ni igba gbogbo ni ẹmi ohun yara.

“Gbogbo eeyan sọ fun mi pe mo wa ni alaafia … nitori naa, Mo wa pa ni igba gbogbo,” o sọ.

Àwòrán

Oríṣun àwòrán, Getty Images

8. Ọgbọ́n orí

Ni ipari, Ọgbọn orí jẹ ihuwasi ti ọpọlọpọ awọn eeyan to jẹ ọgọrun un ọdun ni.

Gẹgẹ bi Merino ṣe sọ, awọn eeyan wọnyi ni agbara oye lati ronu, ronu, yanju awọn iṣoro pẹlu aṣeyọri, ati lati kọ ẹkọ ni kiakia.

“Ọpọlọpọ awọn ihuwasi ti awọn eeyan to ti le ni ọgọrun un ọdun ma hu lo lọ si oye.

“Fun apẹẹrẹ, wọn ni awọn abajade eto-ẹkọ yanranti ati awọn abajade alamọdaju, wọn ti kọ ara wọn, wọn ni ipinnu, wọn le koju idojukọ paapaa ti wọn ko ba kọ wọn nipa rẹ ti wọn yoo se aṣeyọri, wọn nifẹ lati kọ ẹkọ, ibaraẹnisọrọ wọn yara, wọn jafafa ati pe wọn ni iranti to dara, ”O salaye.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

-- "Margarita, kini ohun to lo lati de ẹni ọdun 107?" Mo beere lọwọ rẹ lori foonu.

- "Emi ko mọ. Ni igba gbogbo mo wa ni alaafia. Mo n fi igbagbogbo se is, boya wiwun tabi ṣe awọn ohun miiran.

Nipa ṣiṣe awọn nnkan wonyi, n ko ri aye lati ronu.

Margarita ni eeyan to dagba julọ ni agbegbe rẹ, Santiago,"La Reina".

Ati pe botilẹjẹpe o mọ pe o ti ń “rẹ” oun, awọn alaṣẹ ni agbegbe rẹ ti ṣe ileri fun u pe wọn yoo ṣeto ayẹyẹ nla kan ti o ba pe ọdun 110.

“A yoo ṣe ayẹyẹ kan. Nitori naa ko si akoko lati sinmi,” o sọ, pẹlu ọyaya

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,