Àwọn ohun tí ò lè ṣe rèé láti fi ṣọ́ ìdílé rẹ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

Aworan afihan awọn oṣiṣẹ aabo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣọwọ jiiyan gbe lorileede Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yi jẹ ohun to n kọ ọpọ lominu.

Jakejado Naijiria ni ọrọ aabo to mẹhẹ ti n fa ifoya ohun aifọkanblẹ.

Iye awọn to ti ko si ọwọ awọn ajinigbe yi ti kọja afẹnusọ lati nkan bi ọdun meloo kan sẹyin.

Wọn si ti ri ijinigbe yi gẹgẹ bi ọna ati ri owo kiakia.

Apa ariwa Naijiria ni iṣẹlẹ yi ti gbogo si amọ bayii o ti ran kaakiri to fi de awọn ipinlẹ iwọ oorun guusu Naijiria.

Eyi si ti mu ki ọpọ maa sọ ara wọn ni lilọ tabi bibọ ṣugbọn awọn alaburu to kuku n sọ ni yi a maa ribi ji awọn eeyan gbe tohun ti igbiyanju aabo.

Laipẹ yi ni awọn alaburu yi ji awọn akẹkọọ gbe ni ipinlẹ Ekiti ti wọn si tun ṣeku pa awọn oriade kan nipinlẹ naa.

Ekiti nikan kọ, a tun gbọ pe wọn pa Kabiyesi ilu Koro Ekiti ni Kwara ti wọn si ji Olori Kabiyesi ati eeyan kan gbe.

Ko si igba ti awọn ajinigbe yi ba ṣoro ti wọn kii beere obitibiti owo idoola lọwọ awọn mọlẹbi ẹni ti wọn gbe.

Aarẹ orileede Naijiria Bola Ahmed Tinubu na dasi awọn iṣẹlẹ ijinigbe to gbode to si ni ki awọn oṣiṣẹ aabo tẹpa mọṣẹ lati ri pe wọn pese aabo to peye fun araalu.

Ibi ti aarẹ ti n sọ eleyi ni a tun ti gbọ iroyin pe awọn ajinigbe ji iyawo kan ati awọn eeyan mẹrindinlọgọta to n sin lọ sile ọkọ nipinlẹ Katsina.

Awọn alaburu yi ṣefidio sita ti wọn si ni kawọn mọlẹbi san ọgọrun miliọnu Naira bi bẹẹ kọ awọn yo fi iyawo naa lọkọ mii.

Ọrọ naa ko yi ti niyanju titi di akoko taa n ṣe akojọpọ iroyin yi.

Ibeere to gba ẹnu ọpọ ọmọ Naijiria bayii wa ni pe ki la le ṣe lati daabo bo ara wa ju ti tẹlẹ lọ?

Idahun rẹ la mu t yin wa ninu apilẹkọ yi.

Awọn amọran taa mu tọ yin wa la ri lọdọ ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn onimọ nipa eto aabo.

Awọn amọran aabo to le ṣe ọ lanfaani

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn amọran taa mu tọ yin wa yi wa lati ọdọ awọn ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria.

Bi a ba le ṣe amulo wọn, yoo ṣe anfaani lati tubọ sọ awa ti idile wa lọwọ awọn ajinigbe.

A pin wọn si awọn nkan ti ako gbọdọ ṣe ti wọn mu wa fun wa gẹgẹ bi ọna idaabo ati eleyi taa le ṣe.

Awọn eleyi ti wọn ni ka yago fun ree:

Akọkọ. Ma ṣe lo ami idanimọ si ara ọkọ rẹ eleyi ti yoo satọna ibi to ti n ṣiṣẹ ni paapa to ba jẹ pe wọn tio n san owo daada

Aba Keji . Bo ba jade lọ si ode inawo, ma jẹ ki olorin ki o debi pe wa ma wa na owo falafala loju agbo.Bi o ba lowo lati fun alagbe, fi sinu apo iwe. Ko si ẹni ti yoo mọ iye owo to fi sibẹ.

Aba Kẹta. : Bo ba lọ sidi ẹrọ ATM lati gba owo. Yago fun gbigba owo pupọ.Ranti pe awọn kan le tati ibẹ ro pe owo pọ lọwọ rẹ ti wn yoo si tọ pinpin rẹ pada de ile.

Ẹlẹẹkẹẹrin: Boo ba ti gba alaati owo lori foonu rẹ,ni paapa to ba jẹ owo to pọ, ri wi pe o pa atẹjiṣẹ yi rẹ. O kuku mọ iye owo to wa ninu akanti rẹ. Bi awọn alaburu ba gba ọ mu, nkan ti wọn maa n kọkọ sare wo ree. Ti wọn ba ti ri wi pe o gba owo to pọ, ọrọ bu ṣe nuu ni.

Ẹlẹẹkaarun: Ma ṣe maa sare idaraya ni iwọ nikan ni paapa ti ojumọ ko ba tii mọ tabi ti ilẹ ba ti ṣu. Ọpọ eeyan ni wọn ti foju si lara ti wọn si jigbe salọ sinu ọkọ ni iru akoko yii.

Amọran Kẹfa: Ma ṣe fikaadi idanimọ ibiṣẹ rẹ kọrun kaakiri to ba ti kuro ni ibiṣẹ.Ko si ami ẹyẹ kankan ti wọn yoo fun ọ to ba jẹ ki gbogbo eeyan mọ ibi to ti n ṣiṣẹ.

Amọran Keje: Nibi ipade ẹgbẹ tabi ti aladugbo, yago fun pe ko maa kede owo nla gẹgẹ bi owo to da laarin ẹgbẹ.Pẹlẹ pẹlẹ dọwọ rẹ.

Awọn nkan to le ṣe lati fi daabo bo ara rẹ

  • Ri wi pe o ti ilẹkun ile rẹ ni gbogbo igba .Koda bo ba ṣe pe o kan jade lọ si itosi ile rẹ ni.
  • Sọ ibi to baa n lọ fun awọn alabagbe rẹ, ọkọ tabi iyawo rẹ.Eleyi jẹ ọna kan ti awọn eeyan yoo fi le tete mọ ibi to de kẹyin ti wọn o fi gburo rẹ mọ.
  • Ṣọ nkan to ba n ṣe alabapin nipa ara rẹ loju opo ayelujara.Aye 'fake life'' ni gbigbe kii ṣe lasiko taa wa yi. Awọn ajinigbe ko ni gbọ pe aworan ile nla ati ọkọ bọgina to fi soju opo rẹ kii ṣe tiẹ.
  • Ma ṣe da ọmọ rẹ ran niṣẹ lọ sibi to ba jina. Kda bo ba ṣe itosi, ri wipe eeyan kan tẹle lọ sibẹ.Wọn o ni tibi ọmọ wa mu wa o!
  • Ma ṣe alabapin aworan awọn ọmọ rẹ ninu aṣọ ileẹkọ wọn ti awọn alaburu yoo fi mọ ile ẹkọ ti wọn n lọ. Ri wi pe o daabo bo awọn ọmọ rẹ.