Kí ló le mú akẹ́kọ̀ọ́ ìpele 400l ní fásitì Kwara gba ẹ̀mí ara rẹ̀?

Obinrin kan to wọ hijab

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, bẹẹ ni awọn eeyan n gbera ṣanlẹ nibi ti wọn ti sinku akẹkọọbinrin fasiti ipinlẹ Kwara to wa niluu Malete, ijọba ibilẹ Moro, Rashidat Shittu, ẹni ti wọn lo gbe majele jẹ lati fi gba ẹmi ara rẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn adojukọ ti Rashidat n doju kọ lẹnu ẹkọ rẹ lo fa a to fi pinnu lati gba ẹmi ara rẹ lojiji.

Rashidat ti wọn lo wa ni ipele kẹrin (400level) pa ara rẹ lasiko ti oun pẹlu awọn akẹkọọ yooku n gbaradi fun eto idanwo ti wọn fẹẹ ṣe.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni lẹyin ti Rashidat gbe majele jẹ, ti majele ọhun si ti n da a laamu, lo ṣẹṣẹ sọ fun awọn ọrẹ rẹ.

Ariwo inu rirun ni wọn lo n pa titi to fi ku.

Bi Rashidat ṣe sọ idi ti inu fi n run un, ni wọn sọ pe awọn ọrẹ rẹ sare gbe e lọ si ile itọju to wa ninu ọgba ile-ẹkọ wọn.

Nibẹ ni wọn ti sọ pe ki wọn tete maa gbe e lọ si ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo, Ilorin Teaching Hospital, ṣugbọn ti wọn sọ pe ẹpa ko boro mọ.

Ile iwosan naa ni wọn ti sọ fun awọn ọrẹ rẹ pe Rashidat ti ku, ko si si atunṣe kankan to le jii pada saye mọ.

Ṣaaju asiko yii ni wọn sọ pe Rashidat ti sọ fun lara awọn ọrẹ rẹ wi pe oun ko mọ bi oun yoo sẹ bọ ninu iṣoro ti oun n dojukọ lẹnu eto ẹkọ oun, ṣugbọn ti wọn ni amọran oriṣiriṣi ni wọn fun un.

Ile isinku awọn musulumi ti Janazah to wa lagbegbe Osere niluu Ilọrin la gbọ pe wọn sinku rẹ si nilana musulumi.

Agbenusọ fasiti iipinlẹ Kwara, Ọmọwe Saeedat Aliyu nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun sọ fun BBC pe oun ko tii gbọ nipa ẹ, ati pe ẹnikẹni ko tii fi to oun leti.

Aliyu ni oun yoo gbiyanju lati ṣe iwadii kikun nipa ohun to ṣẹlẹ gangan.