Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Herbert Wigwe, ọ̀gá àgbà Access Bank tó kú pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ nínú ìjàmbá bàálù

Herbert Wigwe

Oríṣun àwòrán, Herbert Wigwe/Twitter

Awọn alaṣẹ ile ifowopamọ Access Bank ti kede iku ọga agba wọn, to tun jẹ ọkan lara awọn oludasilẹ banki naa, ọgbẹni Herbert Wigwe.

Ninu ikede ti akọwe fun ileeṣẹ Access Holding, Sunday Ekwochi, fi sita ni ouwọ ọjọ aiku, lo ti kede pe Ọgbẹni Wigwe, iyawo rẹ, Doreen, ati ọkan ninu awọn ọmọ wọn, Chizi, lo kagbako iku ninu ijamba naa to waye ni orilẹ-ede America.

Wọn ṣapejuwe oloogbe Wigwe gẹgẹ bi irinṣẹ nla to gbe banki naa de ipo to wa lonii lati igba to ti darapọ mọ wọn lọdun 2002.

Yatọ si eyi, alaga Access Holdings, Ọgbẹni Abubakar Jimoh, naa ṣapejuwe rẹ ninu ikede ọhun, gẹgẹ bi ọrẹ to sẹ e gbẹmi le, to si ni adanu nla gba a ni iku rẹ jẹ fun gbogbo agboole Access Holdings.

Herbert Wigwe ati iyawo rẹ, Doreen

Oríṣun àwòrán, Herbert Wigwe/Twitter

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Herbert Wigwe

Lati alẹ ọjọ Abamẹta, ni orukọ ọga agba Access Bank, Herbert Wigwe, ti n tan kalẹ, paapaa lori ayelujara

Amọ pupọ ni ko mọ ohunkohun nipa ọkunrin naa, ju pe o jẹ ọga agba ọkan lara awọn banki to tobi julọ ni Naijriia.

Wigwe to ti fi igba kan jẹ igbakeji ọga agba banki naa, pada di ọga lọdun 2014 lẹyin ti oludokowo pọ rẹ, Aigboje Aig-Imoukhuede fi ipo naa silẹ lọdun 2014.

Ọdun 1966 ni wọn bi Herbert Onyewumbu Wigwe, niluu Port Harcourt, nipinlẹ rivers.

O gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu iṣiro owo lati University of Naijiria, to w ani Nsukka nipinlẹ Enugu lọdun 1987.

O gba iwe ẹri keji ninu imọ nipa eto ile ifowopamọ ati iṣuna lọdun 1991, ni University College of North Wales, nipasẹ ẹkọ ọfẹ ti ijọba ilẹ Britain.

Lẹyin naa lo kawe nipa akoso ọrọ aje ni Fasiti ilu London.

Wigwe bẹrẹ iṣẹ oluṣiri owo nileeṣẹ Coopers & Lybrand, ko to o darapọ mọ ile ifowopamọ Guaranty Trust Bank nibi to ti ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Lọdun 2002, Ọgbẹni Wigwe ati ẹni ti wọn jọ n dokowo pọ, Aigbpje Aig-Imoukhuede, ra Access Bank.

Laarin ọdun 2002 si 2017, banki naa kuro ni ipo karundinlaadọrin ni Naijiria, si ipo kẹrin laarin awọn banki to tobi julọ.

Orukọ iyawo Wigwe ni Chizoba, wọn si bi ọmọ mẹrin funra wọn.

Ileeṣẹ aarẹ Naijiria daro iku Herbert Wigwe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ Aarẹ Naijiria ti kẹdun iku ọga agba patapata fun ile ifowopamọ Access, Herbert Wigwe to jade laye ninu ijamba ọkọ baalu ẹlikọpita

Irọlẹ ọjọ Ẹti to kọja ni iroyin sọ pe Wigwe ati iyawo rẹ, Chizoba, pẹlu ọmọ rẹ, to fi mọ awọn mẹta miran ku ninu ijamba naa niluu Califonia, l'orilẹ-ede America.

Oludamọran pataki lori ọrọ iroyin fun Aarẹ Tinubu, Bayọ Ọnanuga nigba to n kẹdun Wigwe ati awọn marun-un naa, sọ pe adanu nla ni iku oloogbe naa jẹ fun Naijiria ati l'agbo ile ifowopamọ nilẹ Afrika.

Ọnanuga ninu ọrọ to kọ soju opo ‘X’ rẹ, ni gbogbo ipinnu Wigwe lati sọ banki Access di aṣiwaju nilẹ Afrika lo ti pada ja si iku ojiji yii, to si jẹ adanu nla.

Pupọ awọn iwe iroyin ilẹ Amẹrika ni wọn gbe iroyin iku Wigwe ati awọn marun-un ti wọn wa ninu ọkọ baluu ẹlikpita naa, bo tilẹ jẹ pe ko si eyi to sọ pato ibi ti wọn ti n bọ, ati ibi ti wọn n lọ.

Agbegbe kan to wa ni ẹnu ibode Nevada ati Califonia ni ijamba naa ti waye, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Ọnanuga tun fidi rẹ mulẹ pe agbẹjọro kan, Abimbọla Ogunbajọ naa wa ninu awọn to ku sinu ijamba yii.

Bakan naa, minisita fun isuna ni Naijiria tẹlẹ, Ngozi Okonjo-Iweala, ẹni to tun jẹ aarẹ ajọ kara-kata l'agbaye, World Trade Organization, naa kẹdun iku Wigwe.

Okonjo-Iweala loju opo ‘X’ rẹ ni iku Ọgbẹni Wigwe jẹ kayeefi ati adanu manigbagbe.

Awọn alaṣẹ ilẹ Amẹrika ko tii sọ pato nipa awọn ti wọn tun wa ninu baluu naa.

Ṣugbọn ṣa, awọn alakoso eto irinajo oju ofurufu l’Amẹrika, ninu ọrọ ti wọn jẹ ko di mimọ pe “itosi ibikan ti wọn pe ni Nipton, Califonia ni ijamba ọhun ti waye ni nnkan bi agogo mẹwaa alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan, oṣu Keji, ati pe awọn mẹfa ni wọn wa ninu ẹ.”

Awọn alakoso naa ti wa sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn.