Afcon 2023: Balógun ikọ̀ Super Eagles Williams Troost Ekong fojú sun ife ẹ̀yẹ Adúláwọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Balogun ikọ Super Eagles ti orilẹede Naijiria, William Troost Ekong ni gbigba ife ẹyẹ adulawọ yoo jẹ ohun iwuri pupọ fun oun ati awọn eeyan orilẹede Naijiria.
Super Eagles fiyajẹ South Africa lẹyin ti wọn gba pẹnariti lati wọ ipele aṣekagba niluu Abidjan, nibi ti wọn yoo ti ma koju orilẹede to gba alejo idije naa, Ivory Coast.
Ọdun 2013 ni Naijiria wọ ipele aṣekagba gbẹyin, ti wọn si gba ife fun igba kẹta.
"Gbogbo wa ni a ni iru asiko yii lọkan," Troost Ekong sọ fun BBC Sport Africa.
"Mo ti ni iriri yii fun ọpọ igba. Mo ti ni lọkan bi ifẹsẹwọnsẹ yoo se waye ati bi yoo ṣe ri ti a ba gba ife ẹyẹ yii.
Saaju idije yii, Ikọ Super Eagles ko si lara awọn ti wọn ya sọtọ pe yoo gba idije yii, lẹyin ti wọn kọ lati se daadaa ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ti wọn gba ninu igbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2026, ti wọn si wa ni ipo kẹfa ni tabili awọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu to daju ti FIFA gbe kalẹ.
Ẹwẹ, Ikọ Super Eagles lo n leke tente bayii pe yoo gba ife ẹyẹ adulawọ naa lẹyin ti awọn orilẹede bii Morocco, Senegal ati orilẹede to gba ife ẹyẹ yii julọ, Egypt ti ja kuro ninu idije naa.
Akọnimọọgba fun Naijiria, Jose Peseiro sọ pe oun ni igbagbọ pupọ ninu ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, bo ṣe jẹ pe awọn ni wọn mi awọn julọ lasiko ti igbaradi n waye.
"Nigba ti mo tọwọ bọ iwe, mo sọ pe mo fẹ gba AFCON," Peseiro sọ fun BBC Sport Africa.
"Nigba naa, mi o le sọ boya awọn eeyan gba mi gbọ tabi rara amọ emi gbagbọ lati ibẹẹrẹ.
"A ko ti gba ohunkohun titi di asiko yii- A fẹ gba ife ẹyẹ AFCON.
Bassey kan sara si bi Naijiria ṣe fakọyọ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ to lagbara

Oríṣun àwòrán, Reuters
Gbogbo erongba Naijiria ni pe wọn ti bori South Africa lẹyin Troost Ekong gba pẹnariti wolẹ.
Bakan naa, Victor Osimhen ro pe oun ti sọ di meji ni o ku isẹju marun un ki ifẹsẹwọnsẹ pari sugbọn ọna mii ni ọrọ bayọ, ti adari ere bọọlu si fun Bafana Bafana ni pẹnariti, lẹyin to wo fọnran VAR , ti Teboho Mokoena si gba wọle.
"VAR to da ni nitori o mu pẹnariti tako wa." Peseiro salaye.
"Sugbọn fun wa, fun ọkan wa, ko dara nitori a ti n lewaju pẹlu goolu meji, ti wọn si da pada si ami ayo kọọkan.
Diẹ lo ku ki Khuliso Mudau gba goolu wọle fun South Africa ni ipele keji saaju ki wọn to lọ gba pẹnariti.
"Ifẹsẹwọnsẹ to le ni ṣugbọn mo gbagbọ pe a se daadaa." Calvin Bassey sọ fun BBC Sport Africa.
"O fi han pe a ṣe iṣẹ gidi. A nilo lati ni igbagbọ ninu arawa.
"Ikọ South Africa gbiyanju gan, ti wọn si ni awọn eeyan to mọ bọọlu gba. Lati bori wọn pẹlu Pẹnariti le gan.
"Mo kan sara si gbogbo awọn akẹgbẹ mi ti wọn ṣe ọkan akin lati gba pẹnariti naa. Ko rọrun lati gba pẹnariti pẹlu ifọkanbalẹ
Amule Stanley Nwabali ni akikanju lasiko pẹnariti fun ikọ Super Eagles, si mu Pẹnariti lati ọwọ Mokoena ati Evidence Makgopa, ki Kelechi Ihenacho to gba pẹnariti ikẹyin lati se aṣeyọri.
"Riri arami bi mo ṣe gba agbabọọlu to da ju loni ati bi a ṣe wọ ipele aṣekagba jẹ ala to wa si imusẹ," Nwabali , ẹni to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu kan ni orilẹede South Africa.
"Awọn akọnimọgba mi ni mo kan sara, nitori lasiko pẹnariti, wọn ṣe iranlọwọ fun mi pupọ.
Awọn araalu South Africa ko ti awọn agbabọọlu lẹyin

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lẹyin ti wọn lulẹ lasiko Pẹnariti, South Africa naka si awọn anfani ti wọn sọnu si iye to waye lọdun 1996.
Bafana Bafana gbe ipo keji lẹyin meji, ti wọn si gbe ipo kẹta ni ọdun 2000 sugbọn ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Naijiria yoo akọkọ ni ipele to kẹyin si aṣekagba ti wọn yoo gba lati ọdun mẹinlelogun sẹyin.
"Lati ibẹẹrẹ idije yii ni a ti n gbiyanju," Aubrey Modiba, agbawọẹyin sọ fun BBC Sport Africa.
"A gbiyanju lati mi awọn, ti lọ afikun akoko, bo ti lẹ jẹ pe a ni anfani lati bori.
"Bo ti lẹ jẹ pe inu wa bajẹ, pẹnariti da bi tẹtẹ ni. Ko jẹ si ọdọ wa lonii, ko si ohun ta le ṣe.
"A lero pe a yoo kọ gbọn ninu idije yii, ti a yoo se ma kopa ninu idije yii. Iriri wa ati gbogbo ohun ti a ṣe ni bi bayii dara pupọ fun ere bọọlu ni South Africa
Modiba n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Mamelodi Sundowns, ẹgbẹ agbabọọlu to gba ife ẹyẹ Inaugural African Football League, ẹgbẹ agbabọọlu to pese awọn agbabọọli to soju South Africa ju.
Ẹni ọdun Mejidinlọgbọn naa lero pe bi Bafana Bafana se fakọyọ ninu idije yii paapa bi wọn ṣe bori Morocco yoo tun se iwuri fun awọn agbabọọlu.
"Awọn eeyan ti ko si ni South Africa ni igbagbọ ninu wa nitori wọn n wo ifẹsẹwọnsẹ wa sugbọn ni ile, wọn ko fi bẹ tiwa lẹyin- eyi jẹ nnkan to ti mọ wa lara.
"Idi niyẹn ti a fi n ja lati se aṣeyọri nitori awọn to wa ni ile ko ni igbagbọ ninu wa
Modiba plays for Pretoria-based Mamelodi Sundowns, the winners of the inaugural African Football League and a club which has provided the core of the South Africa squad.
South Africa yoo koju DR Congo ni ipele fun ipo kẹta lọjọ Satide niluu Abidjan(20:00 GMT).












