Ìjàmbá ọkọ̀ tún gbẹ̀mí èèyàn kan ní ìlú Ìlorin

Ọkọ àti ọkada to ni ijamba

Ni ọsan ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ ijamba ọkọ tirela kan tun ran ọkunrin kan lọ si ọrun alakeji ni ilu Ilorin.

Titi di asiko ti a n ko iroyin jọ, a o tii mọ orukọ tabi nnkankan nipa ọkunrin naa.

Ni ikorita Pipeline road, agbegbe Offa garage ni ilu Ilorin, Olu ilu ipinlẹ Kwara ni iṣẹlẹ laabi naa ni ọsan ọjọ Aiku, ọjọ Kejìlá oṣu Keji ọdún 2024.

Gẹgẹ bi nnkan ti ẹni ti iṣẹlẹ ijamba ọkọ naa ṣoju rẹ sọ fun ikọ iroyin BBC News Yoruba nigba ti a ṣabẹwo si agbegbe naa, ọgbẹni Wasiu Olalekan sọ pe ọkọ nla Dana naa lo kọlu ọlọkada kan.

Ọkọ àti ọkada to ni ijamba
Ọkọ àti ọkada to ni ijamba

O ni ọlọkada naa to gbe ero meji ni ọkọ nla naa lọ ya ba ti ẹni kan si padanu ẹmi rẹ loju ẹsẹ ti awọn meji si farapa.

Awọn oṣiṣẹ ẹsọ oju popo ipinlẹ Kwara, KWARTMA to n ṣọ agbegbe naa to fidi iṣẹlẹ naa nulẹ, Ayinde ṣalaye pe ọkọ nla naa padanu ijanu rẹ lasiko to wa lori ere, eyi si lo fa a ti ko fi le dara duro fun ọkada naa.

O ni eyi lo mu ki ọkọ nla ọhun lo kọlu ọkada ọhun ti eeyan kan si padanu ẹmi rẹ ninu ijamba naa.

Bakan naa lo ṣalaye pe wọn ti gbe oku ẹni to padanu ẹmi rẹ lọ si budo igbokupamọsi, ti awọn to farapa si ti n gba itọju ni ile iwosan aladani kan.

Ìjàmbá ọkọ̀ típà ṣekúpa ọlọ́kadà kan, àwọn méjì mìíràn farapa ní Ilorin

Ọkada ati ọkọ to wa ninu ijamba

Ni owurọ ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹwaa oṣu keji ọdun 2024 ni ijamba ọkọ gbẹmi ọkunrin kan ni ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara.

Ọkọ nla tipa kan to ko iyẹpẹ lo lọ kọlu ọlọkada, ti ọlọkada naa to si gbẹ mi ẹ loju ẹẹsẹ

Iṣẹlẹ naa to waye ni nnkan bii ago mẹfa abọ owurọ ni Amoyo idojukọ ile epo Anu Oluwapọ, ijọba ibilẹ Ifelodun, ipinlẹ Kwara.

Nigba ti ikọ iroyin BBC News Yoruba sabẹwo sibi ti iṣẹlẹ naa ti sẹlẹ larọ kutu oni ni a ba oku ọlọkada naa nilẹ pẹlu ọmọ rẹ to farapa, nigba ti wọn ti gbe ẹnikeji to kan lẹsẹ lọ ile iwosan.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ, arabirin Omolola Awodibu ṣalaye pe ọkọ tipa naa lofi ọna ti ẹ silẹ to si lọ kọlu ọlọkada naa.

O ni ọlọkada ọhun ni awọn mọ si baba Shadrach, to si gbe ọmọ rẹ meji sẹyin ọkọ ti wọn si n jade lọ.

Iyawo oloogbe naa ti wọn lọ pe nile lati wa wo ọkọ rẹ sọ pe oko ni ọkọ oun n lọ pẹlu awọn ọmọ rẹ lasiko ti ijamba naa fi waye.

Iyawo oloogbe naa lasiko to n gbarata ni oun atawọn ẹbi oun to ko sinu ijamba ọkọ naa ṣẹṣẹ gbadura owurọ tan ki wọn to kuro nile ni.

Awọn ara adugbo Amoyo wa rọ ijọba ipinlẹ Kwara lati wa nnkan ṣe si ọrọ awọn oni tipa to maa n sa ere asapajude lopopona marosẹ Amoyo si Idọfian ki adinku le ba isẹlẹ ijamba ojupopo lagbegbe naa.