Wo bí o ṣe lè dẹ́kun ikú òjijì níbi tí o ti ń wo eré bọ́ọ̀lù

Aworan iko egbe agbaboolu Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Nigeria Super Eagles/Facebook

Idije ere bọọlu jẹ eyi to maa n ru ọkan awọn eniyan soke ti o si maa n mu itara wa ti eeyan ba n wo o.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn ololufẹ ṣe maa n fẹ ko jẹ pẹ ẹgbẹ tabi orilẹ ede ti ti wọn ba n ṣatilẹyin fun lo jawe olubori ninu idije naa.

Lasiko yii, idije ere bọọlu awọn orilẹ ede adulawọ tọdun 2023 iyẹn AFCON 2023 nibi ti orilẹ ede Naijiria ti pegede lati kopa nibi ṣekagba idije naa ti yoo waye lọjọ Aiku, ọjọ kọkanla oṣu Keji lẹyin ti wọn na South Africa nibi abala to kangun si aṣekagba.

Iroyin ni ko din ni eeyan marun-un ọtọọtọ ti wọn ti padanu wọn lasiko ti wọn n wo idije ifẹsẹwọnsẹ laaarin agbabọọlu Super Eagles ati Bafana-Bafana ti l’Ọjọru, to kọja yii.

Super Eagles lo pada fẹyin akẹgbẹ wọn Bafana-Bafana janlẹ amọ oniruurru iṣẹlẹ lo mu ki ọkan ọpọ awọn eeyan to n wo idije naa ru soke.

Iroyin to kọkọ jade ni ti iku Ọmọwe Cairo Ojuogboh, ọkan lara awọn alẹnulọrọ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to jade laye lasiko ti wọn wọgile goolu Victor Osimhen.

Ọmọwe Ojuogboh ti figba kan ri jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin kekere orilẹede to ṣoju ẹkun Ika nipinlẹ Delta ati alakoso agba ileeṣẹ to n ri sọrọ Niger Delta, Niger Delta Development Commission (NDDC).

Lẹyin rẹ ni iroyin miiran tun jade nipa igbakeji alakoso ẹka eto ipawo-wọle ni ile ẹkọ giga fasti ijọba ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Abdullahi Ayuba, ti wọn loun naa jade laye.

Ologbe naa la gbọ wi pe o sọ fawọn ti wọn jọ wo bọọlu pe ooru n mu oun lati inu wa, oun fẹ pada lọ si ile lati lọ sinmi lai mọ pe ifunpa rẹ ti ga.

Akọroyin wa fi idi ẹ mu lẹ pe bo ṣe dele lo ṣubu lulẹ ti wọn si gbe lọ ile iwosan aladani kan lagbegbe Sango ni ilu Ilọrin ti wọn si ni ki wọn maa gbe lọ si ile iwosan nla (UITH) Ilọrin ni ibi to ti jade laye.

Ko pẹ lẹyin eyi ni iroyin tun jade nipa agunbanirọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Samuel ti wọn loun naa ṣubu lulẹ nibi to ti n wo bọọlu ọhun nipinlẹ Anambra, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Siwaju sii ni a tun gbọ pe baba ọlọmọ meji kan, Mikail Oṣundiji naa tun jade laye lagbegbe Olomore to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Ibi ti wọn ni Mikail ti n wo bọọlu yii pẹlu awọn eeyan ni wọn lo ti ni ẹjẹ riru lasiko ti wọn wọgile goolu Osimhen, to si jẹ pe ki oloju too ṣẹ ẹ, o ti ku.

Eyi to tun ṣẹṣẹ jade sita bayii ni ti gbajugbaja oniṣowo ọmọ bibi ilu Anambra nni, Oloye Osondu Nwoye ti wọn loun naa jade laye nibi ti wọn ti n wo bọọlu yii.

Orileede Ivory Coast ni wọn sọ pe Oloye Osondu fi ṣe ibugbe, ohun to si ṣeku pa oun naa ko yatọ si eyi to pa awọn mẹrin yooku, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ni bayii, ikọ BBC YORUBA ti wa ba awọn ọjọgbọn lẹka eto ilera kaakiri sọrọ nipa ohun to le ṣokunfa iku ojiji lasiko ti awọn eeyan ba n wo ere bọọlu ti wọn fẹran.

Ẹ ma jẹ ka mu aṣekagba naa ni kolekole - Dokita Arabinrin Olubusayọ Ọlayinka

Aworan osibitu ijoba, Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Ogun State General Hospital/Wikimedia

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn agba nọọsi nipinlẹ Ogun ni Dokita Arabinrin Olubusayọ Ọlayinka to sọ ohun to le fa iku ojiji lasiko ti eeyan ba n wo ere bọọlu lọwọ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe;

"Pupọ awọn to jade laye yii lo jẹ pe wọn ni ipenija ilera kan tabi omiran lara wọn. Awọn miran le ti mọ ninu wọn, bẹẹ lawọn miran le ma mọ, ṣugbọn Ọlọrun lo ye.

Ẹlomiran le ni aisan ẹjẹ riru tabi itọ ṣuga, bẹẹ ni ẹlomiran le ni mejeeji papọ ninu wọn, nitori pe mejeeji lo n ṣiṣẹ papọ.

Bi eeyan ba ni itọ ṣuga, ti ko ba gbe igbesẹ to yẹ ko gbe nipa ṣiṣe ayẹwo ati itọju rẹ, o maa pada ni ẹjẹ riru bi ko ba ṣọra.

Ayọ ayọju tabi ki n sọ pe ireti ayọ ayọju naa le fa ki ẹjẹ eeyan sare fo soke, o si le ṣe akoba fun iru ẹni bẹẹ, bi awọn to padanu ẹmi wọn yii lasiko ti wọn n wo bọọlu Naijiria ati South Afrika.

Dokita Ọlayinka to tun jẹ alakoso to n mojuto ọrọ afẹfẹ agbelẹrọ, Oxygen Project Coordinator nipinlẹ Ogun tẹsiwaju pe gbogbo nnkan leeyan gbọdọ ṣe niwọntun-wọnsi, nitori pe kii ṣe gbogbo eeyan lo mọ pe awọn ni aisan ẹjẹ riru.

Eeyan gbọdọ maa ṣayẹwo ara rẹ loore-koore, o kere ju ẹẹmeji laarin oṣu kan.

Imọran ti mo fẹ gba awọn ọmọ Naijiria bi Super Eagles ba koju Ivory Coast lọjọ Aiku yii ni pe, ẹ ma jẹ ka pariwo pupọ ju, ko ba ma a fa akoba fun ilera ara wa, ko si iye igba ti eeyan fi n ku, paapaa ẹni to ba ni awọn aisan ti mo sọ yii.

Ẹ ma jẹ ka mu aṣekagba naa ni kolekole, ki wọn ṣe jẹjẹ. Ẹnikan lo maa bori, ẹnikan lo si maa padanu.

Mo wa ni papa iṣere lọjọ ti Samuel Okwaraji jade laye lọdun 1989, mo ṣẹṣẹ jade ile-ẹkọ girama lọdun naa lọhun ni, ọpọ awọn eeyan lo ku pẹlu ẹ nigba yẹn

Ẹ ma jẹ ki iru nnkan bẹẹ tun pada ṣẹlẹ."