Iléẹjọ́ ní kí wọ́n yẹgi fún obìnrin kan tó ṣekúpa aṣojúlóge ní Enugu

Oríṣun àwòrán, IJEOMA NWEKE/FACEBOOK
Ile ẹjọ giga nipinlẹ Enugu ti ni ki wọn lọ yẹ igi fun obinrin kan, Chiamaka Ifezue fun ẹsun pe o ṣekupa obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ - Ijeoma Nweke lọdun 2020.
Ijeoma Nweke lo jẹ aṣojuloge ti Chiamak Ifezue pe ko wa ba oun sisẹ sugbọn to pora, ti ileeṣẹ ọlọpaa si sawari oku rẹ ni ẹgbẹ ọna lẹyin ọjọ diẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa lo nọmba ẹrọ ibaraẹnisọrọ Ijeoma lati fi se iwadii, ti ọwọ si tẹ eeyan meji, Ifezue ati aburo rẹ Chukwuemeka, ti wọn si fẹsun ipaniyan kan awọn mejeeji .
Ni ile ẹjọ lọjọru, ọjọ keje oṣu keji, Adajọ Kenneth Okpe n se kokari ẹjọ naa ni afurasi naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan pe o fi tipatipa fun oloogbe ni majele jẹ, eyi to sokunfa iku rẹ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wọn fẹsu iṣekupani kan Ifezue labẹ iwe ofin ti ọdaran ti ipinlẹ Enugu, to si jẹ pe o jẹbi idajọ iku.
Lasiko to n gbe idajọ naa kalẹ, Adajọ ni Ifezue tutu loju sugbọn o ni ọkan lile.
“Ko ni ita lara lati igba ti igbẹjọ yii ti bẹrẹ. Mo fi akoko yii ni ki wọn lọ yẹgi fun iwọ Ifezue Chiamaka titi ẹmi yoo fi bọ lara rẹ. Ki Ọlọrun saanu fun ré,” Adajọ Okpe gbe idajọ kalẹ.
Sugbọn Adajọ Okpe tu aburo, Chukwuemeka silẹ lẹyin to gba si ẹnu agbẹjọro pe awọn to fẹsun kan kọ lati mu ẹri wa pe o wa nibi ti isẹlẹ naa ti waye.
Lati ọdun 2020 ni isẹlẹ iky Ija=eoma Nweke ti waye.
Ki lo sẹlẹ saaju?
Lọjọ kọkanla, oṣu kọkanla ọdun 2011, Ijeoma Nweke to jẹ aṣojuloge gba ipe lati ọdọ onibara rẹ fun pe ko wa sisẹ ni ile.
O lọ fun isẹ naa sugbọn ko pada wa si ile.
Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ, ti wọn si iwadii awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ to pe Ijeoma fun pe ko wa sisẹ ni ile.
Ibẹ ni wọn gba mu Ifezue Chiamak ati aburo Chukwuemeka, i wọn si gbe wọn lọ si ileẹjọ.
Ijeoma jẹ akẹkọọ jade fasiti ipinlẹ Imo, nibi to ka ẹkọ gboye Psychology ko to di pe o kọ isẹ aṣeojuloge.
Nigba ti iroyin iku rẹ jade lori ayelujara, ọpọ awọn Naijiria lo yari, ti wọn si n pe fun idajọ ododo.















