Àwọn àgbààgbà Àlùfáà, Ìmáàmù ní àsìkò tó kí ìjọba àpapọ̀ ṣiṣẹ́ lórí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ́

Oríṣun àwòrán, Ounje/Getti Images
L’Ọjọbọ ọsẹ yii ni agbarijọ ẹgbẹ awọn Kristẹẹni ati Musulumi lorileede Naijiria rawọ ẹbẹ sijọba apapọ lati wa ọna abayọ si iṣoro ọwọngogo ounjẹ to n koju araalu.
Bi igbe aye ṣe n fi ojoojumọ lọ soke lasiko yii, bẹẹ ni ọwọngogo n ba ounjẹ, to si n kọ ọmọ Naijiria lominu pupọ.
Ẹgbẹ awọn Musulumi ati Ulama lẹkun nipinlẹ Kaduna ati ẹgbẹ awọn Biṣṣobu lẹkun Aarin gbungbun Ariwa ati Guusu-Iwọ-Oorun orileede Naijiria sọ pe ebi ọgaja fọwọ mẹkẹ lo n pa araalu lasiko yii.
Ẹgbẹ awọn Imaamu ni Kadanu parọwa si Gomina Uba Sani lati paṣẹ fun awọn alaga ijọba ibilẹ mẹtalelogun nipinlẹ naa lati pese ounjẹ iranwọ fun awọn araalu lawọn agbegbe wọn.
Bakan naa, awọn Biṣọọbu Katoliiki ni ẹkun Ibadan, iyẹn Ibadan Ecclesiastical Province sọ pe igbe aye ko fẹẹ rọrun fun araalu pẹlu ọwọngogo ati ẹbi to wa nita.
Wọn ni ki ijọba tete gbe igbesẹ ti yoo fopin si iṣoro airi ounjẹ jẹ lasiko.
decried the precarious socio-economic situation prevalent in the country, saying that “the ship of state is foundering.”
Ẹkun naa ti awọn ilu bii Ibadan Archdiocese, Ilorin, Ondo, Oyo, Ekiti, ati Oṣogbo dioceses wa labẹ rẹ ni wọn sọ eyi lasiko ipagọ ti wọn ṣe niluu Ibadan laipẹ yii ni Jubilee Conference Centre, Ibadan.
Ẹ pin ounjẹ de igberiko

Oríṣun àwòrán, BBC/JELILAT OLAWALE
Awọn Imaamu ninu ọrọ wọn lasiko ipade awọn oniroyin ti wọn pe ni olu-iya ijọ Jama’atu Nasril Islam (JNI) to wa niluu Kaduna jẹ ko di mimọ pe yoo lewu pupọ bi ijọba ba gbagbe awọn mẹkunnu ti ebi n pa lasiko yii.
Awọn alakoso ijọ naa, Sheikh Aminu Umdah ati Sheikh Idris Muhammad Sabon-Gari sọ pe ẹkun ti araalu n sun ti jẹ ohun to yẹ ki ijọba tete wa ọna abyọ yọ ko too pẹ ju.
Ninu ọrọ wọn, “Awa ẹgbẹ awọn Imaamu ati Ulama nipinlẹ Kaduna ti dide lati sọrọ lori iṣoro ati ẹbi to n doju kọ araalu nitori awọn agbekalẹ ijọba lori yiyọ owo iranwọ ori epo.
“A n rọ ijọba ipinlẹ yii lati gbe eto dide, ki wọn si sọ fawọn alaga ijọba ibilẹ lati pese iranwọ fun araalu kaakiri igberiko ati agbegbe wọn.”
Wọn ni ajọṣepọ ati ifọwọsowọpọ ni gbogbo ẹka ijọba lo ṣe pataki lasiko yii lati rii pe ọna abayọ atigbadegba wa fun ipenija ti araalu n koju.
“Pinpin eroja ounjẹ ati owo iranwọ ti ijọba apapọ ṣagbatẹru rẹ fun awọn aṣoju araalu nile igbimọ aṣofin ati ijọba ipinlẹ ti jẹ ki awọn eeyan maa la adojukọ nla kọja
“Ẹkun ti awọn eeyan wa n sun yẹ ki ọna abayọ tete wa. A wa n rọ Gomina Sani ati ijọba apapọ lati ipinlẹ Kaduna, ki wọn tete gbe igbesẹ pajawiri nipa pinpin ounjẹ iranwọ fun araalu kaakiri ipinlẹ naa.”
Awọn Biṣọọbu sọrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alaga ẹgbẹ awọn Biṣọọbu, Refurẹndi agba Leke Gabriel Abegunrin ti wa di buba awọn ajinigbe ati apaniyanjaye, to si ni awọn ẹri rẹ ni ti awọn ọba alaye ti awọn amookuṣeka pa danu laipẹ yii.
O ni ẹdun ọkan lo jẹ lori bi wọn ṣe pa Elesun tiluu Esun Ekiti, Ọba David Babatunde Ogunṣakin, ati the Olumojo tiluu Imojo Ekiti, Ọba Samuel Oluṣọla nipinlẹ Ekiti, pẹlu bi wọn ṣe ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe ba ni lọkan jẹ pupọ.
Bakan naa ni Abegunrin tun ni ajalu buruku naa lo tun kan Ọba Peter Ṣẹgun, Olukoro tiluu Koro nipinlẹ Kwara ti wọn padanu, ti wọn si tun ji iyawo ati awọn meji miran gbe salọ.
“Ọkọ orileede yii ti wa n rin lori agba aisi eto aabo bayii, pẹlu ipenija eto ọrọ aje nitori pe ọwọngogo ṣe ba gbogbo nnkan nipasẹ owo naira, jibiti ori ayelujara, aibikita ijọba ati imugbooro iwa ajẹbanu.
“Lojoojumọ ni igbe aye aisi idẹrun ti wa di tọrọfọnkale fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn n gbe ninu iṣẹ ati oṣi, eyi to n mu ki ọpọ maa gbẹmi ara wọn.
Siwaju sii lo sọ pe ipenija yii ti wa sọ awọn araalu di ọdaju nitori iwa ailaanu awọn adari lẹka eto oṣelu.
Bakan naa lo sọ pe igbesẹ ọna abayọ ti ijọba yoo gbe lasiko yii ti pẹ ju fun awọn araalu ti wọn ti padanu ẹmi wọn sọwọ awọn agbebọn, ajinigbe ati oniruuru ajalu.
Bẹẹ lo rọ ijọba lati tete gbe igbesẹ ti yoo fopin si awọn iṣoro wọnyi, ki ọkọ Naijiria ma ba a ri sinu agbami okun.















